Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 4:1-21

  • Ó yẹ kí ìríjú jẹ́ olóòótọ́ (1-5)

  • Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ Kristẹni (6-13)

    • ‘Má ṣe kọjá ohun tó wà lákọsílẹ̀’ (6)

    • Àwọn Kristẹni jẹ́ ìran àpéwò (9)

  • Pọ́ọ̀lù ń bójú tó àwọn tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí (14-21)

4  Ó yẹ kí àwọn èèyàn kà wá sí ìránṣẹ́* Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí mímọ́ Ọlọ́run.+  Nínú ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ àwọn ìríjú ni pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.  Lójú tèmi, kò jẹ́ nǹkan kan pé kí ẹ̀yin tàbí àwùjọ ìgbẹ́jọ́* téèyàn gbé kalẹ̀ wádìí mi wò. Kódà, èmi gan-an kò wádìí ara mi wò.  Nítorí mi ò rí nǹkan tó burú nínú ohun tí mo ṣe. Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé mo jẹ́ olódodo; ẹni tó ń wádìí mi wò ni Jèhófà.*+  Nítorí náà, ẹ má ṣèdájọ́+ ohunkóhun ṣáájú àkókò tó yẹ, títí Olúwa yóò fi dé. Yóò mú àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ inú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀, á sì jẹ́ kí a mọ èrò ọkàn àwọn èèyàn, lẹ́yìn náà, kálukú á gba ìyìn rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+  Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo ti fi èmi àti Àpólò+ ṣàpẹẹrẹ* àwọn nǹkan yìí fún ire yín, kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ wa, ẹ máa kọ́ ìlànà tó sọ pé: “Má ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀,” kí ẹ má bàa gbéra ga,+ tí ẹ ó sì máa sọ pé ẹnì kan dára ju èkejì lọ.  Nítorí ta ló mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí lo ní tí kì í ṣe pé o gbà á?+ Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo gbà á lóòótọ́, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu bíi pé kì í ṣe pé o gbà á?  Ṣé ó ti tẹ́ yín lọ́rùn báyìí? Ṣé ẹ ti lọ́rọ̀ báyìí? Ṣé ẹ ti ń ṣàkóso bí ọba+ láìsí àwa? Ì bá wù mí kí ẹ ti máa ṣàkóso bí ọba, kí àwa náà lè ṣàkóso pẹ̀lú yín bí ọba.+  Nítorí lójú tèmi, ó dà bíi pé Ọlọ́run ti fi àwa àpọ́sítélì sí ìgbẹ̀yìn láti fi wá hàn bí àwọn tí a ti dájọ́ ikú fún,+ nítorí a ti di ìran àpéwò fún ayé+ àti fún àwọn áńgẹ́lì àti fún àwọn èèyàn. 10  Àwa jẹ́ òmùgọ̀+ nítorí Kristi, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ olóye nínú Kristi; àwa jẹ́ aláìlera, àmọ́ ẹ̀yin jẹ́ alágbára; ẹ̀yin ní iyì, àmọ́ àwa kò ní iyì. 11  Títí di wákàtí yìí, ebi ń pa wá,+ òùngbẹ ń gbẹ wá,+ a ò rí aṣọ tó dáa wọ̀,* wọ́n ń nà wá,*+ a ò sì rí ilé gbé, 12  à ń ṣe làálàá, a sì ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́.+ Nígbà tí wọ́n ń bú wa, à ń súre;+ nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, à ń fara dà á pẹ̀lú sùúrù;+ 13  nígbà tí wọ́n bà wá lórúkọ jẹ́, a fi ohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn;*+ a ti dà bíi pàǹtírí* ayé, èérí ohun gbogbo, títí di báyìí. 14  Kì í ṣe kí n lè dójú tì yín ni mo ṣe ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín, àmọ́ kí n lè gbà yín níyànjú bí àwọn ọmọ mi tó jẹ́ àyànfẹ́. 15  Nítorí bí ẹ bá tiẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) atọ́nisọ́nà* nínú Kristi, ẹ kò ní baba púpọ̀; torí nínú Kristi Jésù, mo di baba yín nípasẹ̀ ìhìn rere.+ 16  Nítorí náà, mo rọ̀ yín, ẹ máa fara wé mi.+ 17  Ìdí nìyẹn tí mo fi rán Tímótì sí yín, torí ó jẹ́ ọmọ mi ọ̀wọ́n àti olóòótọ́ nínú Olúwa. Á rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mò ń gbà ṣe nǹkan* ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù,+ bí mo ṣe ń kọ́ni níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ. 18  Àwọn kan ń gbéra ga, bíi pé mi ò ní wá sọ́dọ̀ yín. 19  Àmọ́ màá wá sọ́dọ̀ yín láìpẹ́, tí Jèhófà* bá fẹ́, kí n lè mọ agbára tí àwọn tó ń gbéra ga ní, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. 20  Nítorí Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu, ti agbára ni. 21  Èwo lẹ fẹ́? Ṣé kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú ọ̀pá+ àbí kí n wá pẹ̀lú ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìwà tútù?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọmọ abẹ́.”
Tàbí “kóòtù.”
Tàbí “ṣàpèjúwe.”
Tàbí “gbá wa káàkiri.”
Ní Grk.,“a wà ní ìhòòhò.”
Ní Grk., “a wá ojú rere.”
Tàbí “ìdọ̀tí.”
Tàbí “olùkọ́.”
Ní Grk., “àwọn ọ̀nà mi.”