Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Burú Kó O Yí Ẹ̀sìn Rẹ Pa Dà?

Ṣó Burú Kó O Yí Ẹ̀sìn Rẹ Pa Dà?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Burú Kó O Yí Ẹ̀sìn Rẹ Pa Dà?

Nígbà tí Avtar bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí bí àwọn èèyàn ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Sikh nínú gan-an. Ó sọ pé: “Lórílẹ̀-èdè tí mo ti wá, téèyàn bá yí ẹ̀sìn ẹ̀ pa dà, ṣe ló máa dẹni ìtanù láwùjọ. Àwọn orúkọ tá à ń jẹ́ pàápàá jẹ mọ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀. Tó o bá yí ẹ̀sìn ẹ pa dà ṣe ló dà bíi pé o ò ka ìdílé tó o ti wá sí, o ò sì fẹ́ kí wọ́n pè ẹ́ mọ́ wọn.”

AVTAR wá di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣé ohun tó burú ló ṣe bó ṣe yí ẹ̀sìn ẹ̀ pa dà yẹn? Ó ṣeé ṣe kíwọ náà gbà pẹ̀lú ìdílé Avtar pé kò yẹ kéèyàn yí ẹ̀sìn ẹ̀ pa dà. O lè rò pé ẹ̀sìn ìdílé ẹ ò ṣeé yà kúrò lára ìtàn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ yín, torí náà kò yẹ kó o fi í sílẹ̀.

Ó ṣe pàtàkì lóòótọ́ láti bọ̀wọ̀ fún ìdílé ẹni. Bíbélì sọ pé: “Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ.” (Òwe 23:22) Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká ṣèwádìí òótọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa àti ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. (Aísáyà 55:6) Ṣé irú ìwádìí bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe? Bó bá ṣeé ṣe, báwo ni ìwádìí náà ṣe ṣe pàtàkì sí ẹ tó?

Bá A Ṣe Lè Ṣàwárí Òtítọ́ Tó Wà Nínú Ìwé Mímọ́

Ẹ̀kọ́ táwọn ìsìn tó wà láyé fi ń kọ́ni ò bára dọ́gba. Ó dájú nígbà náà pé gbogbo ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn ò lè jóòótọ́. Èyí jẹ́ ká lóye pé, bí Bíbélì ṣe sọ lọ̀rọ̀ rí, ní ti pé ọ̀pọ̀ “ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ ní 1 Tímótì 2:4, pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ‘gbogbo onírúurú ènìyàn wá ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ Báwo lèèyàn ṣe lè ní irú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀?

Èèyàn lè ní irú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣàyẹ̀wò Bíbélì. Díẹ̀ rèé lára ìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì, sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni.” (2 Tímótì 3:16) Bó o ṣe ń wá òtítọ́ kiri, ó yẹ kó o ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀rí to fi hàn pé òótọ́ ló wà nínú Bíbélì. Fúnra ẹ ṣèwádìí kó o lè rí i pé Bíbélì kún fún ọgbọ́n tí ò láfiwé, ìtàn tó jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti nímùúṣẹ.

Dípò kí Bíbélì kọ́ àwọn tó ń kà á pé gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, ńṣe ló ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá gbọ́, àmọ́ kí wọ́n “dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Bí àpẹẹrẹ, gbogbo ẹ̀kọ́ tó bá wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ànímọ́ rẹ̀, títí kan ànímọ́ ẹ̀ tó gbawájú jù lọ, ìyẹn ìfẹ́.—1 Jòhánù 4:8.

Bíbélì mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run fẹ́ ká ‘rí òun ní ti gidi.’ (Ìṣe 17:26, 27) Níwọ̀n bí Ẹlẹ́dàá wá ti fẹ́ ká wá òótọ́ rí, kò lè jẹ́ àṣìṣe tá a bá wá ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rí tá a rí yẹn, bó bá tiẹ̀ yọrí sí pé ká yí ẹ̀sìn tá à ń ṣe pa dà. Àmọ́ àwọn ìṣòro tó lè tìdí ẹ̀ yọ ńkọ́?

Bí Ìfẹ́ fún Ìdílé Ò Ṣe Ní Borí Ìfẹ́ fún Ọlọ́run

Báwọn èèyàn bá ti yí ẹ̀sìn wọn pa dà, wọ́n lè pinnu pé àwọn ò ní bá wọn lọ́wọ́ nínú àwọn ààtò ẹ̀sìn kan àti ayẹyẹ wọn mọ́. Bó ṣe sábà máa ń rí, èyí lè fa èdèkòyédè láàárín ẹbí. Jésù sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀. Ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Mo wá láti fa ìpínyà, láti pín ọkùnrin níyà sí baba rẹ̀, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, àti ọ̀dọ́ aya sí ìyá ọkọ rẹ̀.” (Mátíù 10:35) Ṣé ohun tí Jésù wá ń sọ ni pé torí àtimáa dá ìyapa sílẹ̀ ni wọ́n ṣe kọ Bíbélì? Rárá o. Ńṣe ni Jésù fòye mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn mọ̀lẹ́bí bá gbógun ti ẹni tó yí ẹ̀sìn ẹ̀ pa dà.

Ṣé èèwọ̀ ni kí ẹbí bínú sí wá? Bíbélì kọ́ni pé káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, káwọn aya sì wà ní ìtẹríba sáwọn ọkọ wọn. (Éfésù 5:22; 6:1) Àmọ́ ṣa ó, ó fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní ìtọ́ni pé kí wọ́n “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Torí náà, láwọn ìgbà míì ó lè pọn dandan pé kó o ṣe ìpinnu táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ò ní fọwọ́ sí kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ẹ̀kọ́ òótọ́ àti èké, síbẹ̀ Ọlọ́run fún olúkúlùkù láǹfààní láti pinnu ohun tó máa ṣe. (Diutarónómì 30:19, 20) Kò yẹ kí wọ́n fipá mú ẹnikẹ́ni láti ṣe ẹ̀sìn tí ò nífẹ̀ẹ́ sí tàbí kí wọ́n sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún un láti fara mọ́ ìdílé ẹ̀ tàbí kó fọwọ́ mú ẹ̀sìn tó yàn láti ṣe. Ṣé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń da àárín tọkọ taya rú ni? Rárá o. Kódà, Bíbélì rọ ọkọ àtaya tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra pé kí wọ́n máa bá a lọ ní gbígbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan.—1 Kọ́ríńtì 7:12, 13.

Bó O Ṣe Lè Ṣẹ́pá Ìbẹ̀rù

Ohun táwọn tẹ́ ẹ jọ wà ládùúgbò máa sọ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa bà ẹ́ lẹ́rù. Mariamma sọ pé: “Ohun tó ń ba ìdílé mi lẹ́rù ni pé mi ò ní lè rí ọkọ tó dáa fẹ́, táá máa gbọ́ bùkátà mi. Torí náà, wọn ta ko ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́.” Ṣe ni Mariamma gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run tó sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lọ. (Sáàmù 37:3, 4) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Dípò tí wàá fi máa bẹ̀rù ohun tó máà ṣẹlẹ̀, kúkú pọkàn pọ̀ sórí àǹfààní tó o máa rí níbẹ̀. Ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ń mú káyé àti ìwà èèyàn dáa sí i ni. Ó máa ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n á ṣe fẹ́ràn ìdílé wọn dénú. Ó lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti borí àwọn àṣà tí ò dáa bíi kéèyàn máa ṣẹ̀ẹ̀kẹ́ èébú tàbí kó jẹ́ aríjàgbá, ó tiẹ̀ lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ lílo oògùn olóró àti mímu ọtí lámujù. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Àwọn ìwà tó yẹ ọmọlúwàbí bíi jíjẹ́ adúróṣinṣin, jíjẹ́ olóòótọ́ àti òṣìṣẹ́ kára ni Bíbélì gbé lárugẹ. (Òwe 31:10-31; Éfésù 4:24, 28) O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o sì rí àwọn àǹfààní tó wà nínú fífi ohun tó kọ́ni sílò nígbèésí ayé rẹ?

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbé ohun tí ẹ̀sìn ẹ fi ń kọ́ni yẹ̀ wò?—Òwe 23:23; 1 Tímótì 2:3, 4.

◼ Báwo lo ṣe lè dá ẹ̀kọ́ tòótọ́ mọ̀?—2 Tímótì 3:16; 1 Jòhánù 4:1.

◼ Ṣó yẹ kí àtakò àwọn ìdílé ẹ mú kó o ṣíwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?—Ìṣe 5:29.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

Ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ń mú káyé àti ìwà èèyàn dáa sí i

[Àwòrán tó wà ní ójú ìwé 15]

Mariamma àti ọkọ rẹ̀ rèé