Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 8 (March sí August 2019)

Àwọn Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Apá 8 (March sí August 2019)

Nínú àwọn fọ́tò iṣẹ́ ìkọ́lé yìí, ẹ máa rí bí iṣẹ́ ṣe ń tẹ̀ síwájú ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tuntun ní Britain láàárín oṣù March sí August 2019.

  1. Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

  2. Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àtúnṣe Nǹkan

  3. Àwọn Ọ́fíìsì

  4. Ilé Gbígbé A

  5. Ilé Gbígbé B

  6. Ilé Gbígbé C

  7. Ilé Gbígbé D

  8. Ilé Gbígbé E

  9. Ilé Gbígbé F

March 5, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Òṣìṣẹ́ kan ń ṣiṣẹ́ lára àwọn páìpù tó ń gbé omi tó gbóná.

March 29, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àtúnṣe Nǹkan

Nínú àwọn yàrá ìmúra, àwọn òṣìṣẹ́ ń kọ́ balùwẹ̀.

April 10, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Òṣìṣẹ́ kan ń tẹ́ àwọn wáyà sórí òrùlé, àwọn wáyà tó ń tẹ́ yìí ni kò ní jẹ́ kí ààrá ba àwọn nǹkan jẹ́. Òṣìṣẹ́ yẹn fi okùn kọ́ ara ẹ̀, ó sì so okùn náà mọ́ orí òrùlé yẹn kí ọkàn ẹ̀ lè balẹ̀ bó ṣe ń ṣiṣẹ́ náà pé kò sí ewu kankan.

April 16, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn òṣìṣẹ́ ń nu àwọn gíláàsì torí wọ́n máa lẹ àwọn ìsọfúnni kan síbẹ̀. Àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ lẹ̀ síbẹ̀ ló máa jẹ́ káwọn èèyàn tètè rí àwọn gíláàsì náà kí wọ́n má sì ṣèèṣì kọlù wọ́n.

April 23, 2019—Ilé Gbígbé A

Òṣìṣẹ́ kan ń fi kámẹ́rà wo inú ihò kó lè mọ̀ bóyá kò sí ibì kankan tó dí níbẹ̀.

April 23, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn káfíńtà ń to igi sára ògiri gbọ̀ngàn tí wọ́n á máa lò fún ilé ìjẹun àti àwọn ètò pàtàkì míì.

May 14, 2019—Ilé Gbígbé B

Àwọn òṣìṣẹ́ ń gbin ewé sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn nítòsí ògiri.

May 14, 2019—Ilé Gbígbé A

Àwọn òṣìṣẹ́ ń de gíláàsì mọ́ ẹnu àbáwọlé níbì téèyàn lè dúró sí gbatẹ́gùn. Gíláàsì yìí máa jẹ́ bí ààbò fún ẹni tó bá dúró síbẹ̀, ó máa jẹ́ kí ìtànṣán oòrùn wọlé ki atẹ́gùn sì lè ya wọlé dáadáa.

May 21, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Ní ọwọ́ ìta pálọ̀ ìgbàlejò, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ mànàmáná ń de iná mọ́bẹ̀.

June 11, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Òṣìṣẹ́ kan ń fi irinṣẹ́ gé páìpù táá máa gbé atẹ́gùn.

June 17, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn tó ń tọ́jú ilẹ̀ ń gbin igi, wọ́n tún palẹ̀ mọ́ ibi táwọn èèyàn á máa gbà. Lápá òsì ẹ máa rí ilé ìjẹun tí wọ́n á tún máa lò fún àwọn ètò pàtàkì míì. Ilé Gbígbé-A ló wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn yẹn.

June 24, 2019—Ilé Gbígbé-A

Ẹni yìí ń ṣe páìpù tó máa tú omi síta tí iná bá ń jó.

July 9, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Wọ́n ń ṣètò ilẹ̀ kí wọ́n lè fúrúgbìn àwọn òdòdó síbẹ̀. Lọ́wọ́ ẹ̀yìn, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀rọ tó máa ń fagbára tú omi síta fọ wíńdò àwọn ọ́fíìsì.

July 9, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Àwọn òṣìṣẹ́ ń fi èròjà kan tó máa ń jẹ́ kí ilẹ̀ rẹwà wọ́ ilẹ̀. Wọ́n á lo irinṣẹ́ kan tí kò ní jẹ́ kí ibì kan ga ju ibòmíì lọ, lẹ́yìn náà wọ́n á fi irinṣẹ́ míì yọ atẹ́gùn tó bá há sáàárín ilẹ̀ náà.

July 24, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn òṣìṣẹ́ ń lẹ ilẹ̀ inú ilé ìjẹun tó tún jẹ́ gbọ̀ngàn tí àá máa lò fún àwọn ètò míì. Lára ògiri tó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn, níbi tí pèpéle máa wà, wọ́n ti gbé tẹlifíṣọ̀n sára ògiri tí wọ́n ṣe lọ́nà tí ohùn ò fi ní máa ta pa dà.

July 26, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Nítòsí yàrá tí wọ́n á ti máa ṣe àwọn fídíò, káfíńtà kan ń ṣe gíláàsì àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n á máa lò níbẹ̀.

August 1, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Àwọn káfíńtà ń ṣe ohun tí wọ́n á máa fi pín ọ́fíìsì sí kéékèèké, ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa jẹ́ kó rọrùn tí wọ́n bá fẹ́ tún àwọn ọ́fíìsì tò lọ́jọ́ iwájú.

August 1, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Agbaṣẹ́ṣe kan ń to àwọn irin tí wọ́n á máa lò níbi tí wọ́n á ti máa ṣe àwọn fídíò. Ara irin yìí ni wọ́n máa so àwọn irinṣẹ́ kan kọ́ sí, irú bíi iná àti kámẹ́rà.

August 15, 2019—Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá À Ń Kọ́ Lọ́wọ́

A ya àwòrán yìí lọ́wọ́ òkè ní apá àríwá ilẹ̀ náà. Lápá òsì, iṣẹ́ ti parí lára Ilé Gbígbé B, C, D, E, àti F. Láàárín, ẹ máa rí Ilé Gbígbé-A, òun náà ò ní pẹ́ parí, iṣẹ́ ti parí lára Àwọn Ọ́fíìsì náà. Lápá ọ̀tún, ilé Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò àti Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àtúnṣe Nǹkan, iṣẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí níbẹ̀. Àmọ́ o, iṣẹ́ àtúnṣe ojú ilẹ̀ ṣì ń lọ lọ́wọ́ ní gbogbo ọgbà náà.

August 26, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn òṣìṣẹ́ ń to òkúta sí ilẹ̀ nítòsí pálọ̀ ìgbàlejò. Àtíbàbà tẹ́ ẹ̀ ń rí lẹ́yìn yẹn ló ń ṣíji bo àwọn òṣìṣẹ́ tó ń fọ ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe.