Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Apá 7 (September 2018 sí February 2019)

Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Apá 7 (September 2018 sí February 2019)

Nínú fọ́tò iṣẹ́ ìkọ́lé yìí, wàá rí ibi ti iṣẹ́ dé lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láàárín September 2018 sí February 2019.

  1. Ilé Iṣẹ́ Apá Àríwá

  2. Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù

  3. Àwọn Ọ́fíìsì

  4. Ilé Gbígbé A

  5. Ilé Gbígbé B

  6. Ilé Gbígbé C

  7. Ilé Gbígbé D

  8. Ilé Gbígbé E

  9. Ilé Gbígbé F

September 25, 2018—Ilé Gbígbé A

Àwọn Kọ́lékọ́lé àti Àwọn Tó Ń Fi Ẹ̀rọ Ṣiṣẹ́ lo ẹ̀rọ méjì tí wọ́n fi ń gbẹ́ ilẹ̀ láti gbẹ́ ihò ńlá kan tí wọ́n máa ri páìpù tá a gbé omi wọnú ilé mọ́. Àwọn Ọ́fíìsì ló wà lápá ẹ̀yìn nínú àwòrán náà..

September 26, 2018—Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù

Àwọn agbaṣẹ́ṣe fi ohun èlò tí wọ́n fi ń bo ògiri bo iwájú ilé. Wọ́n ṣe ara ohun èlò náà àti àwọ̀ tí wọ́n fi kùn ún lọ́nà tí ilé náà á fi bá ìrísí ojú ilẹ̀ agbègbè náà mu.

September 27, 2018—Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù

Lẹ́yìn tí wọ́n ti da kọnkéré sórí ilẹ̀, àwọn agbaṣẹ́ṣe fi ẹ̀rọ kì í mọ́lẹ̀ kó lè dán, kó máa kọ mànà, kó sì lálòpẹ́.

October 4, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwòrán apá àríwá ìlà oòrùn ọ́fíìsí tí wọ́n yà látòkèèrè. Ní iwájú àwòrán náà, Àwọn Kọ́lékọ́lé palẹ̀ agbègbè náà mọ́, wọ́n sì sọ ilẹ̀ náà di èyí tó tẹ́jú kí wọ́n lè fi ṣe ibi ìgbọ́kọ̀sí gbogbo-gbòò fún àwọn tó bá wá sí ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń gbàlejò. Wọ́n ti gbé férémù irin sára ọ́fíìsì ìgbàlejò tó wà láàárín àwọn ọ́fíìsì méjèèjì, lápá òsì. Àwọn ọ́fíisì apá àríwá àti apá gúúsù ló wà lápá ẹ̀yìn.

October 10, 2018—Ibi Tí Wọ́n Máa Kọ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Sí

Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ilé Gbígbé A, wọnlẹ̀wọnlẹ̀ kan ń ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ àwọn tó ń gbin igi àti òdòdó ó sì ń ṣe àkọsílẹ̀. Torí pé bí iṣẹ́ ìkọ́lé bá ti bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti máa ń gbin igi àti òdòdó, wọ́n á ti dàgbà dáadáa tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà á bá fi parí.

October 31, 2018—Ilé Gbígbé F

Àwọn kunlékunlé ń fi ọ̀dà tó ní oje kun ilẹ̀ ibi ìgbọ́kọ̀sí. Ọ̀kan lára wọn wọ bàtà tó ní irin ṣoṣoro, èyí tí kò ní jẹ́ kí ipa ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn lórí ibi tí wọ́n bá ti kùn. Ilẹ̀ tí wọ́n bá fi ọ̀dà tó ní oje kùn kì í tètè pàwọ̀ dà, ọ́ìlì mọ́tò kì í bà á jẹ́. Bó sì ṣe yẹ kí ibi ìgbọ́kọ̀sí rí nìyẹn.

November 6, 2018—Ilé Iṣẹ́ Apá Gúúsù

Àwọn oníṣẹ́ omi ẹ̀rọ díwọ̀n ṣéènì onírin tí wọ́n máa lò, wọ́n sì gé e. Ara ṣéènì onírin yìí ni wọ́n á gbé ẹ̀rọ tó ń lo ìmọ́lẹ̀ látara oòrùn kọ́ sí, kí wọ́n lè lò ó láti mú ibi kan tó fẹ̀ gan-an táwọn èèyàn a ti máa ṣiṣẹ́ móoru.

November 6, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn òṣìṣẹ́ kọ́kọ́ kun inú Àwọn Ọ́fíìsì ní ọ̀dà ọwọ́ kan. Ọ̀pá ẹ̀rọ tó ń pèse ooru, afẹ́fẹ́ àti òtútù wà ní òkè àjà ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan, wọ́n fi ọ̀rá dúdú wé wọn kí wọ́n má bàa dógùn-ún.

November 8, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn òṣìṣẹ́ gbé férémù irin sókè ibi tí ọ́fíìsì ìgbàlejò wà.

December 7, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn agbaṣẹ́ṣe lo ẹrọ agbẹ́rùròkè tó ní ohun tó ń fi afẹ́fẹ́ fa nǹkan mọ́ra láti fi gbé gíláàsì sí ìta yàrá ìjẹun àti gbọ̀ngàn ńlá.

December 10, 2018—Àwọn Ọ́fíìsì

Díẹ̀ lára Àwọn Òṣìṣẹ́ Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni Nípa Iná Mànàmáná ń fi sọ́kẹ́ẹ̀tì sẹ́nu àwọn wáyà tí ìsọfúnni ń gbà kọjá. Irú àwọn wáyà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n rì mọ́ abẹ́ ilẹ́ láwọn ìpele mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Àwọn Ọ́fíìsì ti fẹnu kora gùn tó àádọ́ta kìlómíta (máìlì mọ́kànlélọ́gbọ̀n). Bí wọ́n ṣe ní ibi tí àwọn ọ́fíìsì náà ti fẹnu kora yìí á mú kó rọrùn láti ṣe àtunṣe tó bá yẹ nínú ọ́fíìsì láì làágùn púpọ̀, tí ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ sí ìdàrúdàpọ̀.

December 26, 2018—Ilé Gbígbé A

Àwọn Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Pàjáwìrì ń ṣe ìfidánrawò bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo ẹni tó bá já bọ́ látorí àtẹ̀gùn tí bẹ́líìtì ààbò gbé dúró, tó sì ń fi dirodiro.

January 8, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Ọ̀kan lara Àwọn Kọ́lékọ́lé ń wọn ibi táwọn ẹlẹ́sẹ̀ á máa gba kọjá kí wọ́n tó to kọnkéré pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ síbẹ̀. Lójú ọ̀nà yẹn, ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ́lẹ̀ ń gbẹ́ kòtò, kí wọ́n lè gbin àwọn igi hornbeam sí ẹ̀gbẹ́ ojú ọ̀nà náà.

January 9, 2019—Àwọn Ilé Iṣẹ́

Fọ́tò tí wọ́n yà láti òkèèrè. Wọ́n ń to àwọn ohun èlò tó ń fi agbára oòrùn pèsè iná mànàmànà sára òrùlé ilé iṣẹ́ àti ti Àwọn Ọ́fíìsì, kí wọ́n lè máa fi agbára oòrùn múná wá.

January 17, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Ọ̀kan lára Àwọn Òṣìṣẹ́ Tó Ń Ṣe Àṣekágbá Iṣẹ́ ń tẹ́ òkúta ẹfun tí wọ́n fi ń bo ilẹ̀ sórí ilẹ̀ ibi àbáwọlé tó wà ní àjà kẹta. Ohun fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó ní àwọ̀ ọsàn wà ní ìsàlẹ̀ òkúta ẹfun náà tí kì í jẹ́ kó fi ara kan ilẹ̀ pátápátá, torí náà kò lè fọ́ bí ilẹ̀ náà bá yẹ̀.

January 21, 2019—Ibi tí wọ́n kó irinṣẹ́ sí

Àwọn òṣìṣẹ́ tébi ń pa gba oúnjẹ ọ̀sán wọn, wọ́n sì ń jẹ ẹ́ ní yàrá ìjẹun tó wà fún ìgbà díẹ̀. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni yàrá ìjẹun yìí máa ń pèsè oúnjẹ fáwọn òṣìṣẹ́ tó tó ẹgbẹ̀rún kan lójoojúmọ́.

January 30, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Wọ́n ń fi àwọn katakata kó ẹrù kúrò ní ẹ̀yìn ọ́fíìsì. Ní apá ọ̀tún, wọ́n ti gbé gíláàsì tó ṣeé ṣí tó sì ṣeé tì sára àwọn òpó tó yí yára ìjẹun ka kí oòrùn tó rọra ń tàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ nígbà òjò máa bàa wọnú yàrá ìjẹun ati inú gbọ̀ngàn.

January 30, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn Òṣìṣẹ́ Tó Ń Ṣe Àṣekágbá Iṣẹ́ ń tẹ́ kápẹ́ẹ̀tì sorí ilẹ̀, Àwọn Tó Yọ̀ǹda Ara Wọn Láti Wá Ṣiṣẹ́ Ọjọ́ Kan sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Nípa irú ìṣètò yìí, gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófa jákèjádò ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ireland ni ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n fi àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn ránṣẹ́ láti wá ṣiṣẹ́ ọjọ́ kan. Ní ìparí oṣù February, àwọn tó ti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà lọ́nà yìí ti lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (5,500).

February 12, 2019—Ilẹ́ Iṣẹ́ Apá Gúúsù

Àwọn agbaṣẹ́ṣe mọ ògiri ìdábùú ńlá kan gba àárín ilé náà kọjá, ó sì pín ilé náà sí méjì dọ́gbadọ́gba. Òpó kúkúrú aláwọ̀ ọsàn tó wà lórí ilẹ̀ náà ni wọ́n fi sàmì sí ibi tí kò léwu ti ẹ̀rọ́ tí wọ́n fi ń gbé nǹkan ti lè máa ṣiṣẹ́.

February 20, 2019—Àwọn Ọ́fíìsi

Bí iṣẹ́ ṣe ń lọ lọ́wọ́ níbi tí ilẹ̀ ti fẹnu kora níbi ìyará ìgbàlejò, àwọn òṣìṣẹ́ ń mú kí agbègbè náà wà ní mímọ́ tónítóní.