Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Britain, Apá 9 (September 2019 sí February 2020)

Fọ́tò Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní Britain, Apá 9 (September 2019 sí February 2020)

 Nínú àwọn fọ́tò yìí, wàá rí bí wọ́n ṣe parí iṣẹ́ lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Britain àti bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láàárín September 2019 sí February 2020.

  1. Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

  2. Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àtúnṣe Nǹkan

  3. Àwọn Ọ́fíìsì

  4. Ilé Gbígbé A

  5. Ilé Gbígbé B

  6. Ilé Gbígbé C

  7. Ilé Gbígbé D

  8. Ilé Gbígbé E

  9. Ilé Gbígbé F

September 10, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn tó ń mú kí ilẹ̀ rẹwà ń pa ilẹ̀ mọ́ kí wọ́n lè gbin nǹkan sórí ẹ̀. Ilé gbígbé A àti B sì wà lọ́ọ̀ọ́kán.

September 19, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Odò kékeré kan wà lẹ́yìn àwọn ọ́fíìsì yìí. Odò yìí àtàwọn míì tó wà níbi iṣẹ́ ìkọ́lé ní Chelmsford wà lára àwọn odò tí àwọn omi míì máa ń ṣàn gbà. Ìyẹn ti jẹ́ kí omi ibẹ̀ túbọ̀ dára, kí omíyalé dín kù, ó sì ti jẹ́ kí àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko gbádùn àyíká tó mọ́ tó sì rẹwà.

September 19, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Tọkọtaya kan jọ ń ṣiṣẹ́ láti kan àwọn ògiri tó pààlà ọ́fíìsì tuntun náà pa pọ̀.

October 14, 2019—Ilé Gbígbé A

Ẹnì kan tó n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀ka tó ń yàwòrán ilé ń lo iná pupa tí wọ́n fi ń wọn nǹkan bó ṣe ń lẹ àmì mọ́ ilẹ̀kùn ibi tí wọ́n ti ń se irun.

October 28, 2019—Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá À Ń Kọ́ Lọ́wọ́

Káfíńtà kan ń lo púlọ́ọ̀mù bó ṣe ń gbé àmì sójú ọ̀nà. Torí pé éékà márùnlélọ́gọ́rin (85) ni ilẹ̀ náà, àwọn àmì yìí máa jẹ́ atọ́nà fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn àlejò tó bá wá.

November 4, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn panápaná ìjọba ń wò ó bóyá ẹrọ tó ń fọ́n omi ń ṣiṣẹ́ dáadáa.

November 14, 2019—Àwọn Ọ́fíísì

Ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé ń darí ìjọsìn òwúrọ̀ kan nígbà tí wọ́n ń wo bí Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn kọ̀ǹpútà ṣe ń ṣiṣẹ́. Wọ́n ṣe àtagbà ètò náà sí ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú London.

November 19, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná ń de iná tí wọ́n fi ń darí ọkọ̀ sójú ọ̀nà tó lọ sí ọ̀kan lára àwọn ibi tí wọn ò ṣe fún gbogbo èèyàn.

November 19, 2019—Ibi tí wọ́n kó irinṣẹ́ sí

Àwọn òṣìṣẹ́ ń bó wáyà kí wọ́n lè tún un lò.

November 25, 2019—Ibi tí wọ́n kó irinṣẹ́ sí

Ẹnì kan tó ń fini mọ̀nà ń ṣàlàyé bí ilẹ̀ náà ṣe rí fáwọn tó wá ṣèbẹ̀wò. Ohun tó ju ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ̀rún (95,000) èèyàn ló wá ṣèbèwò síbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ lọ́wọ́.

December 5, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Britain ń bá àwọn tó ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà sọ̀rọ̀ ní ìpàdé oṣooṣù tó kẹ́yìn tí wọ́n ṣe kí àwọn ẹ̀ka tó wà ní Bẹ́tẹ́lì tó bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó ilé náà. Ohun tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá (11,000) èèyàn ló yọ̀ǹda àkókò àti okun wọn láti ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà.

December 10, 2019—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àwọn Fídíò

Àwọn Tó Ń Ṣe Fídíò àti ẹ̀ka tó ń tàtagbà fídíò ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì tuntun náà. Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà wọ ike aláwọ̀ búlúù kan sórí bàtà wọn kí bàtà wọn má bàa ba ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jẹ́.

December 30, 2019—Àwọn Ọ́fíìsì

Wọ́n ń da iyẹ̀pẹ̀ tó gbẹ́ sáàárín àwọn òkúta tí wọ́n tò sójú ọ̀nà tó lọ sí àwọn ọ́fíìsì.

January 16, 2020—Ibi Tí Àá Ti Máa Ṣe Àtúnṣe Nǹkan

Mẹ́káníìkì kan ń tún bọ́ọ̀sì kékeré kan ṣe. Ní báyìí tó jẹ́ pé ojú kan ni gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì náà wà, àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ò nílò ọ̀pọ̀ àwọn bọ́ọ̀sì kékeré táá máa gbé wọn lọ síbiṣẹ́ lójoojúmọ́. Torí náà, wọ́n lè ta àwọn bọ́ọ̀sì tí wọn ò lò mọ́. Ọkọ kékeré táwọn tó ń tún àyíka ṣe ń lò wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn.

January 29, 2020—Ilé Gbígbé D

Wọ́n ń já ẹrù àwọn tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀. Àwọn mẹtàdínlọ́gbọ̀n (27) ló bá àwọn ará Bẹ́tẹ́lì kó ẹrù wọn ní January àti February. Níbẹ̀rẹ̀ oṣù March, gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti ń gbé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun náà, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbẹ̀.

February 6, 2020—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìdáná ń se oúnjẹ tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa jẹ.

February 7, 2020—Ibi Táwọn Òṣìṣẹ́ Ń Gbé

Wọ́n ta àwọn ilé kéékèèké tí wọ́n lò nígbà iṣẹ́ ìkọ́lé náà, wọ́n sì ń kọ́ wọn lọ. Àwọn ilé yìí làwọn tó ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà gbé, kò sì jìnnà rárá sí ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Ètò yìí mú kí lílọ bíbọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ dín kù. Nípa bẹ́ẹ̀, afẹ́fẹ́ carbon àtàwọn afẹ́fẹ́ míì tó lè pa àwọn èèyàn lára dín kù. Àjọ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àyíká ìyẹn BREEAM gbóṣùbà káre fáwọn ará fún ètò tí wọ́n ṣe yìí. Àwọn ilé gbígbé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ náà wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn lọ́hùn-ún.

February 14, 2020—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtúmọ̀ èdè ń ṣètò yàrá ìgbohùnsílẹ̀. Yàrá ìgbohùnsílẹ̀ yìí jẹ́ àfikún sí àwọn ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ kéékèèké tó wà ní ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan táwọn atúmọ̀ èdè ń lò. Yàrá yìí sì wà lárọwọ́tó fáwọn tó ń túmọ̀ èdè Irish, èdè Scottish Gaelic àtàwọn èdè míì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Britain.

February 24, 2020—Àwọn Ọ́fíìsì

Arákùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ń bá aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó agbègbè southeast England sọ̀rọ̀ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àtìgbàdégbà làwọn aṣojú yìí máa ń kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n á ṣe kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti bí wọ́n á ṣe bójú tó wọn. Lọ́wọ́ ẹ̀yìn, àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka yìí ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n á ṣe mú káwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ àtàwọn tí wọ́n tún ṣe máa móoru, kí atẹ́gùn sì máa wọlé dáadáa.

February 25, 2020—Àwọn Ọ́fíìsì

Àwọn ará tó ń tilé wá ṣiṣẹ́ dé sí yàrá ìgbàlejò. Lẹ́yìn náà, wọ́n kí wọn káàbọ̀, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí wọ́n á ti ṣiṣẹ́. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sí Chelmsford, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún àwọn ará ló ń wá láti ilé wọn kí wọ́n lè wá ṣèrànwọ́ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Lọ́wọ́ ẹ̀yìn lọ́hùn-ún, àwọn amojú ẹ̀rọ ń ṣàyèwò àwọn tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n á lò nígbà àfihàn tí wọ́n ṣètò fáwọn àlejò.