Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ló Fà Á Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Yí Àwọn Ohun Kan tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Pa Dà?

Kí Ló Fà Á Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Yí Àwọn Ohun Kan tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Pa Dà?

 Bíbélì la máa ń gbé gbogbo ohun tá a gbà gbọ́ kà, torí náà, bí Ìwé Mímọ́ ṣe túbọ̀ ń yé wa sí i là ń ṣàtúnṣe sí àwọn ohun tá a gbà gbọ́. a

 Àwọn àtúnṣe tá a ṣe yìí bá ìlànà tó wà nínú Òwe 4:​18 mu, ó sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” Bí ojúmọ́ ṣe máa ń máa ń mọ́ díẹ̀díẹ̀ ká lè túbọ̀ máa rí àwọn ohun tó wà láyìíká kedere, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe máa ń fi òye òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yéni díẹ̀díẹ̀, tó bá tó àsìkò lójú rẹ̀. (1 Pétérù 1:​10-​12) Bí Bíbélì ṣe sọ, ó ti mú kí òye òtítọ́ yìí túbọ̀ yéni ní “àkókò òpin.”​—Dáníẹ́lì 12:4.

 Kò yẹ kí àwọn àtúnṣe tá a ṣe sí òye tá a ti ní yìí yà wá lẹ́nu tàbí kó ìrònú bá wa. Àwọn tó ń sin Ọlọ́run láyé àtijọ́ náà ti fìgbà kan ní èrò tí kò tọ̀nà, wọ́n ti retí pé kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ nígbà tí kò tíì tó àkókò, ìyẹn sì gba pé kí wọ́n tún èrò wọn ṣe.

  •   Ogójì (40) ọdún ṣáájú àkókò tí Ọlọ́run ṣètò pé òun máa yan Mósè láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú ni Mósè fúnra rẹ̀ ti fẹ́ gbà wọ́n sílẹ̀.​—Ìṣe 7:​23-​25, 30, 35.

  •   Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú Mèsáyà àti àjíǹde rẹ̀ kò yé àwọn àpọ́sítélì.​—Aísáyà 53:​8-​12; Mátíù 16:21-​23.

  •   Ọ̀tọ̀ ni àkókò táwọn Kristẹni kan láyé àtijọ́ ń fọkàn sí pé “ọjọ́ Jèhófà” máa dé.​—2 Tẹsalóníkà 2:​1, 2.

 Nígbà tó yá, Ọlọ́run la àwọn nǹkan yìí yé wọn dáadáa, àdúrà wa sì ni pé á máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwa náà.​—Jákọ́bù 1:5.

a Tí òye tá a ní nípa àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì bá yí pa dà, a kì í fi pa mọ́. Kódà, a máa ń kọ ọ́ sílẹ̀, a sì máa ń gbé e jáde. Bí àpẹẹrẹ, tẹ ìlujá “Beliefs Clarified” yìí kó o lè rí àwọn àtúnṣe tá a ti tẹ̀ jáde nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa lédè Gẹ̀ẹ́sì.