Dáníẹ́lì 12:1-13

  • “Àkókò òpin” àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà (1-13)

    • Máíkẹ́lì máa dìde (1)

    • Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa tàn yinrin (3)

    • Ìmọ̀ tòótọ́ máa pọ̀ yanturu (4)

    • Dáníẹ́lì máa dìde fún ìpín rẹ̀ (13)

12  “Ní àkókò yẹn, Máíkẹ́lì*+ máa dìde, ọmọ aládé ńlá+ tó dúró nítorí àwọn èèyàn rẹ.* Àkókò wàhálà máa wáyé, èyí tí irú rẹ̀ kò wáyé rí látìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí di àkókò yẹn. Ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn rẹ máa yè bọ́,+ gbogbo àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé.+  Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ máa jí, àwọn kan sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn míì sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra ayérayé.  “Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa tàn yinrin bí òfúrufú, àwọn tí wọ́n sì ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo máa tàn bí ìràwọ̀, títí láé àti láéláé.  “Ní tìrẹ, Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì gbé èdìdì lé ìwé náà títí di àkókò òpin.+ Ọ̀pọ̀ máa lọ káàkiri,* ìmọ̀ tòótọ́ sì máa pọ̀ yanturu.”+  Èmi Dáníẹ́lì wá wò, mo sì rí àwọn méjì míì tó dúró síbẹ̀, ọ̀kan ní etí omi níbí àti ìkejì ní etí omi lọ́hùn-ún.+  Ọ̀kan wá sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,*+ tó wà lórí omi tó ń ṣàn pé: “Ìgbà wo ni àwọn ohun àgbàyanu yìí máa dópin?”  Nígbà náà, mo gbọ́ tí ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, tó wà lórí omi tó ń ṣàn sọ̀rọ̀, bó ṣe gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀ sókè ọ̀run, tó sì fi Ẹni tó wà láàyè títí láé búra pé:+ “Ó máa jẹ́ fún àkókò tí a yàn, àwọn àkókò tí a yàn àti ààbọ̀ àkókò.* Gbàrà tí fífọ́ agbára àwọn èèyàn mímọ́ túútúú bá ti dópin,+ gbogbo nǹkan yìí máa dópin.”  Ní tèmi, mo gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi;+ mo wá sọ pé: “Olúwa mi, kí làwọn nǹkan yìí máa yọrí sí?”  Ó sì sọ pé: “Máa lọ, Dáníẹ́lì, torí pé ọ̀rọ̀ náà máa jẹ́ àṣírí, a sì máa gbé èdìdì lé e títí di àkókò òpin.+ 10  Ọ̀pọ̀ máa wẹ ara wọn mọ́, wọ́n máa sọ ara wọn di funfun, a sì máa yọ́ wọn mọ́.+ Àwọn ẹni burúkú máa hùwà burúkú, kò sì ní yé ìkankan nínú àwọn ẹni burúkú; ṣùgbọ́n àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa lóye.+ 11  “Látìgbà tí a bá ti mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo*+ kúrò, tí a sì ti gbé ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀,+ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti àádọ́rùn-ún (1,290) ọjọ́ máa wà. 12  “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fojú sọ́nà,* tó sì dé ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínlógójì (1,335) ọjọ́! 13  “Àmọ́ ní tìrẹ, máa lọ sí òpin. O máa sinmi, àmọ́ wàá dìde fún ìpín rẹ* ní òpin àwọn ọjọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”
Ní Héb., “àwọn ọmọ àwọn èèyàn rẹ.”
Tàbí “yẹ̀ ẹ́ [ìyẹn, ìwé náà] wò fínnífínní.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ìyẹn, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀.
Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”
Tàbí “tó ń retí lójú méjèèjì.”
Tàbí “ní ibi tí a pín ọ sí.”