ORIN 69
Máa Wàásù Ìjọba Náà
-
1. Ẹ tẹ̀ síwájú, ẹ máa wàásù.
Ẹ kéde orúkọ Jáà.
Ẹ wá àwọn onírẹ̀lẹ̀ lọ
Torí ‘fẹ́ tẹ́ ẹ ní sí wọn.
Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́
Láti bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́.
Torí náà, ká máa fayọ̀ wàásù;
Ká kéde òótọ́ fáráyé.
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú, fìgboyà wàásù
‘Jọba náà fáráyé.
Tẹ̀ síwájú, kó o jẹ́ adúróṣinṣin
sí Jèhófà.
-
2. Àwọn ẹni àmì òróró
Àti àgùntàn mìíràn;
Gbogbo wa lọ́kùnrin, lóbìnrin
Ni ká máa tẹ̀ síwájú.
Ó yẹ kí gbogbo ayé gbọ́ pé
Ìjọba Ọlọ́run dé tán.
Bá a ṣe ń wàásù, ẹ̀rù kìí bà wá.
Jèhófà ló wà lẹ́yìn wa.
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú, fìgboyà wàásù
‘Jọba náà fáráyé.
Tẹ̀ síwájú, kó o jẹ́ adúróṣinṣin
sí Jèhófà.
(Tún wo Sm. 23:4; Ìṣe 4:29, 31; 1 Pét. 2:21.)