Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 39

Ní Orúkọ Rere Lọ́dọ̀ Ọlọ́run

Ní Orúkọ Rere Lọ́dọ̀ Ọlọ́run

(Oníwàásù 7:1)

  1. 1. Gbogbo ayé wa ló yẹ kí á fi ṣe

    Orúkọ rere, ká sì pòfin Jáà mọ́.

    Tí Jèhófà bá rí bí a ṣe ń sapá tó

    Láti ṣèfẹ́ rẹ̀, ó máa láyọ̀.

  2. 2. Ayé yìí lè fẹ́ ká wá orúkọ ńlá;

    Ká wá òkìkí àt’ojúure èèyàn.

    Tá a bá dọ̀rẹ́ ayé, asán ni gbogbo rẹ̀.

    A ò ní rí ojúure Jèhófà.

  3. 3. A fẹ́ k’Ọ́lọ́run rántí wa sí rere;

    Ká ní orúkọ rere títí ayé.

    A ó gbèjà òtítọ́, a gbọ́kàn wa lé Ọ.

    A ó pa orúkọ rere wa mọ́.