Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 33

Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà

Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà

(Sáàmù 55)

  1. 1. “Gbọ́ àdúrà mi,” Jèhófà.

    Má fojú pa mọ́ fún mi.

    Wo bínú mi ṣe bà jẹ́ tó;

    Jọ̀ọ́, fi mí lọ́kàn balẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ

    Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.

    Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ

    Torí pé olóòótọ́ ni.

  2. 2. Tí mo bá lè fò bí ẹyẹ,

    Màá fò ré kọjá ewu.

    Kémi lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀tá

    Tí ó ń lépa ẹ̀mí mi.

    (ÈGBÈ)

    Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ

    Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.

    Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ

    Torí pé olóòótọ́ ni.

  3. 3. Ọlọ́run máa ń tù wá nínú,

    Ó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀.

    Yóò máa bá wa gbé ẹrù wa

    Torí ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

    (ÈGBÈ)

    Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ

    Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.

    Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ

    Torí pé olóòótọ́ ni.