Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ORIN 32

Dúró Ti Jèhófà!

Yan Àtẹ́tísí
Dúró Ti Jèhófà!

(Ẹ́kísódù 32:26)

 1. 1. Nígbà kan, a kò mohun táa fẹ́ ṣe.

  Ìsìn èké sì ń darí ayé wa.

  Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run

  Mú káyọ̀ kún ọkàn wa.

  (ÈGBÈ)

  Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ.

  Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀.

  Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà,

  Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá.

 2. 2. A dúró ti Ọlọ́run níṣọ̀kan.

  À ń wàásù Ìjọba rẹ̀ fáráyé.

  Àkókò tó kí kálukú wọn yàn

  Láti wá sin Ọlọ́run.

  ((ÈGBÈ)

  Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ.

  Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀.

  Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà,

  Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá.

 3. 3. A kò bẹ̀rù ohun t’Èṣù lè ṣe

  Torí Jèhófà ni agbára wa.

  Báwọn ọ̀tá tilẹ̀ pọ̀ jù wá lọ,

  Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé.

  (ÈGBÈ)

  Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ.

  Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀.

  Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà,

  Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá.