Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 105

“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

(1 Jòhánù 4:7, 8)

  1. 1. Bàbá wa ọ̀run jẹ́ ìfẹ́,

    Ó ní káwa náà nífẹ̀ẹ́.

    Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa,

    Tá a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn,

    Ìgbé ayé wa á ládùn,

    Ó sì máa jẹ́ ká níyè.

    Jésù Kristi náà fìfẹ́ hàn;

    Ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

  2. 2. Ìfẹ́ tòótọ́ máa ń ta wá jí;

    Ó máa ń mú ká fìfẹ́ hàn.

    Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run

    Máa s’agbára wa dọ̀tun.

    Ìfẹ́ máa ń ṣoore, kìí jowú;

    Ìfẹ́ máa ń ní ‘faradà.

    Ẹ jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa;

    Ká gbádùn ìfẹ́ tòótọ́.

  3. 3. Má di ẹnikẹ́ni sínú;

    Má fàyè gba ìbínú.

    Jèhófà ni kó o yíjú sí,

    Àwọn òfin rẹ̀ dára.

    Ẹ jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,

    Yóò mú kífẹ̀ẹ́ wa jinlẹ̀.

    Ká fara wé Ọlọ́run wa;

    Ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn.