Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ

Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ

Wà á Jáde:

  1. 1. Mò ń wora mi láyé tuntun,

    Níbi tí kò ní síbẹ̀rù mọ́.

    Ó dé tán.

    Ó dá mi

    Lójú gan-an.

  2. 2. Jèhófà ló ṣe ìlérí yìí.

    Ó dá mi lójú pé òótọ́ ni.

    Ọkàn mi sì

    Balẹ̀ pé

    Ó máa ṣẹ.

    (ÈGBÈ)

    Ìtura—

    Máa dé bá gbogbo àwọn èèyàn.

    Àlàáfíà—

    Yóò wá jọba bí Jèhófà ṣe fẹ́.

  3. 3. Àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú,

    Wọ́n máa jíǹde, a ó sì pa dà rí wọn.

    Ó dé tán.

    Ó dá mi

    Lójú gan-an.

  4. 4. Kò ní sírora àtẹkún mọ́.

    Ara gbogbo èèyàn máa jí pépé.

    Ọkàn mi

    Balẹ̀ pé

    Yóò rí bẹ́ẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ìtura—

    Máa dé bá gbogbo àwọn èèyàn.

    Àlàáfíà—

    Yóò wá jọba bí Jèhófà ṣe fẹ́.

  5. 5. Mo nígbàgbọ́ nínú Jèhófà;

    Gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá sọ yóò ṣẹ.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ọkàn mi

    Balẹ̀ pé

    Ọjọ́ kan ń bọ̀

    Tí ayé tuntun máa dé.

    Ṣáà máa—

  6. 6. Wora rẹ láyé tuntun,

    Níbi tí kò ní síbẹ̀rù mọ́.

    Ó dé tán.

    Ó dá mi

    Lójú gan-an.