Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdílé Kan Ni Wá

Ìdílé Kan Ni Wá

Wà á jáde:

  1. 1. Ọkọ̀ òfúúrufú balẹ̀

    Lẹ́yìn ìrìn àjò tó jìn

    A filé sílẹ̀,

    A ń rí ọwọ́ Jèhófà

    Lẹ́nu iṣẹ́ yìí

    Lóòótọ́, iṣẹ́ náà kò rọrùn rárá,

    Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn.

    Ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ara wa pọ̀ gan-an,

    Torí náà à ń sọ pé:

    (ÈGBÈ)

    Ọmọ Jèhófà ni wá

    À ń fayọ̀ sìn ní ìṣọ̀kan.

    Bí ìlú wa tilẹ̀ jìnnà,

    Ìdílé

    Kan ni gbogbo wa.

  2. 2. Ẹ ti ń dúró dè wá kí ẹ

    Lè fi ìfẹ́ kí wa káàbọ̀.

    Ohùn orin ń dún, ìpàdé bẹ̀rẹ̀,

    Ṣe ninú wa ń dùn ṣìnkìn.

    A mọ̀ pé Jèhófà Baba wa ni

    Ó mú kí èyí ṣeé ṣe.

    Torí náà, a fọpẹ́ a fìyìn fún Jèhófà

    Jọ̀ọ́ tẹ́wọ́ gbọpẹ́ wa.

    (ÈGBÈ)

    Ọmọ Jèhófà ni wá

    À ń fayọ̀ sìn ní ìṣọ̀kan.

    Bí ìlú wa tilẹ̀ jìnnà,

    Ìdílé

    Kan ni gbogbo wa.

  3. 3. Ọkọ̀ òfuurufú gbéra

    A lọ síbi tá a kò dé rí.

    À wàásù fún àwọn tó wà níbẹ̀

    Wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ sí wa.

    Àwọn ará fìfẹ́ tọ́jú wa gan-an

    Wọ́n jẹ́ kí ara tù wá.

    Ibi yòówù ká wà, bó ti wù kó jìn tó,

    Ìfẹ́ wa jinlẹ̀ gan-an!

    (ÀSOPỌ̀)

    Ó yẹ ká mọ̀

    Páwọn ọmọ ìyá wa wà káàkiri,

    Ní Mali sí Mẹ́síkò,

    Ní Japan sí Jàmáíkà.

    (ÈGBÈ)

    Ọmọ Jèhófà ni wá

    À ń fayọ̀ sìn ní ìṣọ̀kan.

    Bí ìlú wa tilẹ̀ jìnnà,

    Ìdílé

    Kan ni gbogbo wa.

    Ní gbogbo orílẹ̀-èdè,

    A mọ̀ pé ìdílé ni wa.

    Ìfẹ́ wa hàn sí aráyé

    Torí Jèhófà ló so wá pọ̀!

    Kóńgò, Màláwì àti Amẹ́ríkà

    Nàìjíríà, Kánádà, Káńbodíà

    Dòmíníkà, Estonia àti Kúbà

    Ìdílé kan ni gbogbo wa.