Lọ́jọ́ kan, èmi àti àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan kóra jọ nínú igbó tó wà ní abúlé kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Gbogbo wa jókòó, a sì ń sọ bí Jèhófà ti ṣe bù kún wa nígbèésí ayé. Bí mo ṣé ń wojú ìyàwó mi ọ̀wọ́n tí ẹ̀rín músẹ́ ń bọ́ lẹ́nu ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mò ń rántí gbogbo àwọn ìbùkún tá a ti gbádùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti gbádùn irú àwọn ìkórajọ yìí láwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra. Mi ò tiẹ̀ ronú pé Jèhófà lè fún mi nírú àǹfààní yìí. Torí pé nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, nǹkan míì ni mi ò bá fayé mi ṣe. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún yín.
Inú abúlé kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni wọ́n bí mi sí. Kí wọ́n tó bí mi làwọn òbí mi àtàwọn òbí mi àgbà ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kódà, ọmọ ọdún mẹ́fà ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, mo sì ṣèrìbọmi nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13). Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tá a bá gbọludé nílé ìwé. Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an mo sì fẹ́ fi gbogbo ayé mi sìn ín títí láé.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), àwọn olùkọ́ wa níléèwé kíyè sí i pé mo máa ń fakọ yọ nídìí eré ìdárayá. Ni àwọn aṣojú méjì láti ẹ̀ka tó ń gbá bọ́ọ̀lù kan tí wọ́n ń pè ní rugby bá wá rí mi, wọ́n sì sọ fún mi pé wọ́n máa fún mi ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ torí bí mo ṣe máa ń fakọ yọ nídìí eré ìdárayá. Ó wù mí kémi náà di ìlú mọ̀ọ́ká nídìí eré bọ́ọ̀lù rugby yìí, àmọ́ mo ti yara mi sí mímọ́ fún Jèhófà lákòókò yẹn. Ni mo bá fọ̀rọ̀ náà lọ bàbá mi, wọ́n sì ni kí n ronú nípa ìlérí tí mo ṣe fún Jèhófà kí n tó pinnu bóyá màá gbá èrè bọ́ọ̀lù yìí. Mo ṣe ohun tí bàbá mi sọ, mo sì rí i pé mi ò lè ki irin méjì bọná pa pọ̀. Mi ò lè máa gbá eré bọ́ọ̀lù yìí kí n sì tún ní mo fẹ́ fi gbogbo ọjọ́ ayé mi sin Jèhófà. Torí náà mi ò gba ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ náà. Kò ju oṣù mélòó kan lọ ni àjọ tó ń rí sí eré ìdárayá nílùú Canberra láwọn máa fún mi ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ kí n lè máa kópa nínú eré ìje ẹlẹ́mìí ẹṣin, wọ́n ni tí mo bá gbà, mo lè ṣojú orílẹ̀-èdè Ọsirélíà níbi ìdíje Commonwealth tàbí ìdíje Olympic. Àmọ́ torí pé mo fẹ́ ṣe ohun tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run mi, mo sọ fún wọn pé mi ò fẹ́.
Kò pẹ́ rárá tí mo jáde iléèwé ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà torí ó ṣe díẹ̀ tó ti wà lọ́kàn mi. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ò rọrùn fún ìdílé wa, bí mo ṣe fiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ nìyẹn. Mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbi tí mo ti ń bá wọ́n wa àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò nínú oko. Nǹkan bí ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni mí nígbà yẹn, mo sì ń dágbé. Nígbà tó yá, mi ò fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn mi mọ́, mo rẹ̀wẹ̀sì, ìjọsìn mi wá di afaraṣe-má-fọkàn-ṣe. Àwọn ọ̀rẹ́ tí mò ń bá rìn tún wá dá kún ìṣòro mi torí pé wọ́n máa ń mutí lámujù, wọ́n tún máa ń ṣèṣekúṣe, ó sì ń wù mí kémi náà máa ṣe bíi tiwọn. Lákòókò yẹn mo jìnnà sí Jèhófà, mo sì ń ṣe ohun tó wù mi.
Mo mọ̀ pó yẹ kí n ṣàtúnṣe, torí náà mo kó lọ sí ìlú míì kí n lè jìnnà sáwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ yẹn. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan táá mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, mo sì pinnu láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pa dà. Kò pẹ́ sígbà yẹn mi mo pàdé Leann McSharry, ìyẹn ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó sì máa ń tijú, bá a ṣe dọ̀rẹ́ nìyẹn. A jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wù wá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, irú bí iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Nígbà tó dọdún 1993, a ṣègbéyàwó, a sì fayé wa lé Jèhófà lọ́wọ́.
Ọwọ́ Wa Tẹ Ohun Tó Wù Wá
Ọdún tá a ṣègbeyàwó yẹn lèmi náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Torí pé a ò fẹ́ gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ, a ò sì fẹ́ jẹ gbèsè, a ra ọkọ̀ kan tá a lè máa gbé inú ẹ̀. Ọdún mẹ́fà la fi ń lọ sáwọn ibi tí ètò Ọlọ́run bá ní ká lọ, a sì ń ṣe onírúurú iṣẹ́ ká lè gbọ́ bùkátà ara wa. A wàásù láwọn ìjọ tó wà ní abúlé láwọn aṣálẹ̀ Queensland. Ibi tí ilẹ̀ bá ṣú wa sí, la máa sùn mọ́jú, lọ́pọ̀ ìgbà ó lè jẹ́ ibi tó dá. A tún máa ń ṣe àwọn ìpàdé wa nínú igbó tàbí ní gbọ̀ngàn ìlú. Láìka bí nǹkan ṣe rí yìí sí, inú wa máa ń dùn, síbẹ̀ a ṣì máa ń ronú pé, ‘Ṣé àwọn nǹkan míì tún wà tá a lè ṣe fún Jèhófà?’ Kò pẹ́ tá a fi rí ìdáhùn ìbéèrè náà.
Ètò Ọlọ́run kọ lẹ́tà sí wa, wọ́n sì ní ká lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè míì, ọ̀rọ̀ yẹn kà wá láyà, ó sì ṣe wá bíi pé a ò ní lè ṣe é torí pé a ò lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. A gbádùn ká máa lọ sóde ìwàásù. Àmọ́ torí pé a ò fi bẹ́ẹ̀ láwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa ń ṣe wá bíi pé a kì í ṣe olùkọ́ tó já fáfá.
A sọ bó ṣe ń ṣe wá fún Arákùnrin Max Lloyd tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wà ní Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. a Ṣe ló bá wa sọ̀rọ̀ bíi bàbá sọ́mọ, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tó bá tiẹ̀ ń ṣe wá bíi pé a ò kúnjú ìwọ̀n, tá a bá ṣáà ti yọ̀ǹda ara wa, Jèhófà máa mú ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá fún wa. Ohun tó sọ yẹn wọ̀ wá lọ́kàn gan-an, a sì múra láti lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Sri Lanka.
Iṣẹ́ Náà Ò Rọrùn
Lọ́dún 1999, a gúnlẹ̀ sí ìlú Colombo, tó jẹ́ olú ìlú Sri Lanka. Nǹkan yàtọ̀ gan-an níbí tá a bá fi wé ibi tá a ti ń bọ̀. Torí pé ní abúlé Ọsirélíà ọkàn wa balẹ̀. Àmọ́ níbí, wọ́n ń jagun, ọ̀pọ̀ èèyàn ló tòṣì, èrò pọ̀ rẹpẹtẹ, àwọn tó ń tọrọ bárà wà káàkiri, èdè wọn sì tún ṣòro lóye. Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, a rí àwọn ìṣúra ní Sri Lanka, ìyẹn àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin títí kan ọ̀pọ̀ àwọn míì tí wọ́n lọ́kàn tó dáa àmọ́ tí wọn ò tíì mọ Jèhófà.
Ìlú Kandy ni wọ́n rán wa lọ, ìlú yìí sì rẹwà gan-an torí pé oko tíì àti igbó kìjikìji yí i ká. Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ìlú yẹn torí pé tẹ́ńpìlì àwọn tó ń jọ́sìn Búdà pọ̀ gan-an níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nílùú yẹn ni ò mọ nǹkan kan nípa Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa. Torí pé àwọn tó ń sọ èdè Sinhala àti Tamil ló wà níjọ wa, èdè méjèèjì la máa fi ń ṣèpàdé. Èdè Sinhala ò rọrùn rárá, àmọ́ àwọn tá a jọ wà níjọ àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọyì bá a ṣe ń sapá láti kọ́ èdè náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣìṣe wa máa ń pa wọ́n lẹ́rìn-ín!
Àmọ́, kíkọ́ èdè yẹn kéré lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìṣòro míì tá a ní. Bí àpẹẹrẹ, a ti máa ń gbọ́ bí àwọn alátakò ṣe ń ṣe inúnibíni sáwọn ará wa, àmọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé wa, àwa náà fojú winá ẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn jàǹdùkú kan yí wa ká, wọ́n dáná sun àwọn ìwé wa, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu èmi àti arákùnrin kan. Lákòókò yẹn, a ṣáà ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀, kó sì rántí wa tí wọ́n bá tiẹ̀ pa wá. Láìrò tẹ́lẹ̀, àwọn jàǹdùkú yẹn fi wá sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ. Ṣe lara wa ń gbọ́n bá a ṣe ń kúrò nílùú yẹn, àmọ́ a dúpẹ́ pé Jèhófà dá ẹ̀mí wa sí.
Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn iṣẹ́ wa ní Sri Lanka. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ogun tó ń jà ti mú káwọn èèyàn kẹ́yìn síra wọn, inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí i tí Jèhófà ń mú káwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wá sínú ìdílé ẹ̀ tó wà níṣọ̀kan. A ò lè gbàgbé àwọn ìrírí tá a ní nílùú tó rẹwà yìí. Àmọ́, lẹ́yìn ọdún méjì péré, àwọn ẹlẹ́sìn fúngun mọ́ àwọn aláṣẹ, wọ́n sì mú kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì ló fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀.
Láwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a ò mọ ohun tá a máa ṣe, gbogbo nǹkan sì tojú sú wa. A wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wa pé, kí ló máa ṣẹlẹ̀ báyìí? Kò pẹ́ ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí rán wa lọ sí orílẹ̀-èdè Papua New Guinea. Ní September 2001, a gúnlẹ̀ sí ìlú Port Moresby tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà.
Ilẹ̀ Papua New Guinea Ṣàrà Ọ̀tọ̀
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Papua New Guinea ló sún mọ́ Ọsirélíà jù, àṣà wọn àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan yàtọ̀ síra gan-an. Bó ṣe di pé iyán di àtúngún, ọbẹ̀ sì di àtúnsè fún wa nìyẹn. Ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) èdè ni wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè yìí. Àmọ́ a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Tok Pisin torí pé èdè yẹn lọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ jù.
Lẹ́yìn tá a lo ọdún mẹ́tà nílùú Popondetta, ètò Ọlọ́run ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. A ò tiẹ̀ rò ó rí pé Jèhófà lè mú ká nírú àǹfààní yìí. Tí mo bá rí àwọn alábòójútó àyíká, mo máa ń mọyì bí wọ́n ṣe ń kọ́ni, bí wọ́n ṣe ń gbani níyànjú àti bí òtítọ́ ṣe jinlẹ̀ nínú wọn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé irú mi kó ló ń ṣiṣẹ́ náà. Ó ṣì ń yà mí lẹ́nu pé, Jèhófà fún mi nírú àǹfààní yìí torí pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló ti wà lọ́kàn mi látilẹ̀. Mi ò sì rò ó rí pé mo lè di alábòójútó àyíká.

Mò ń kọ lẹ́tà tí mo fẹ́ fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ́yìn tí mo ṣèbẹ̀wò sí àwùjọ kan tó wà ní Papua New Guinea
Tá a bá lọ bẹ àwọn ìjọ tó wà nígboro wò, wọ́n máa ń fún wa ní yàrá tó ní bẹ́ẹ̀dì, a tún máa ń rí iná àti omi lò. Àmọ́ nǹkan kì í rí bẹ́ẹ̀ tá a bá lọ bẹ àwọn ìjọ tó wà ní abúlé wò. Inú àwọn ilé kéékèèké tí ò lómi tí ò sì níná la máa ń sùn. Ìta la ti máa ń dáná, àá sì lọ wẹ̀ lódò. Àmọ́ táwọn ọ̀nì bá wà nínú odò, ṣe la máa pọnmi lọlé, àá sì lọ wẹ̀ lẹ́yìn ilé wa.
Nínú gbogbo àwọn iṣẹ́ tá a ti ṣe, eléyìí ló ń tánni lókun jù. Àmọ́ ó dá wa lójú pé tá a bá ‘lọ pẹ̀lú agbára tá a ní’ Jèhófà máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí. (Àwọn Onídàájọ́ 6:14) Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í rọrùn láti dé àwọn ibi táwọn ìjọ tá a fẹ́ lọ bẹ̀ wò wà, torí ó lè gba pé ká gba inú igbó kìjikìji, inú ẹrẹ̀ tàbí àwọn ọ̀nà gbágungbàgun tí òkè pọ̀ níbẹ̀ kọjá. Nígbà míì, ọkọ̀ la máa wọ̀ tàbí ká wọkọ̀ ojú omi, ó sì lè jẹ́ pé ọkọ̀ òfúrufú la máa lò tàbí ká fẹsẹ̀ rìn. Ohun tó ṣáà jẹ wá lógún ni pé ká rí àwọn ará wa. b
Tá a bá fẹ́ lọ bẹ ìjọ kan tó wà nítòsí ibodè Indonesia wò, a máa ń rìnrìn àjò tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ààbọ̀ (350) kìlómítà lójú ọ̀nà tí ò dáa. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì (200) ìgbà tá a gbé ọkọ̀ wa sọdá odò, ọ̀pọ̀ àwọn odò yẹn ni ò sì ní afárá tí mọ́tò lè gbà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mọ́tò wa máa ta kú sínú ẹrẹ̀, a sì máa ń ṣe wàhálà fún ọ̀pọ̀ wákàtí ká tó lè tì í jáde. Á ti rẹ̀ wá tá a bá fi máa dé ọ̀dọ̀ àwọn ará, àmọ́ bí wọ́n ṣe máa ń wá pà dé wa pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ àti oúnjẹ aládùn tí wọ́n ti sè máa ń mú kára tù wá.
Tá a bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ sáwọn abúlé kan, àfi ká wọ ọkọ̀ òfúrufú kékeré. Tá a bá fẹ́ balẹ̀, ẹni tó ń wakọ̀ òfúrufú yìí á kọ́kọ́ wa ọkọ̀ náà wá sísàlẹ̀ kó lè mọ ibi tá a wà. Tó bá tún fẹ́ balẹ̀, á kọ́kọ́ wò ó bóyá kò sí àwọn ọmọdé tàbí àwọn ẹran lójú ọ̀nà, lẹ́yìn náà la máa wá balẹ̀ lórí ọ̀nà gbágungbàgun tó wà lórí òkè kan tó ga ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún (2,100) mítà lọ. Nígbà míì tá a bá fẹ́ kúrò láwọn abúlé náà, àfi kí ọkọ̀ òfúrufú náà gbéra lójú ọ̀nà tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. c
Láwọn ìgbà míì, a máa ń rìn gba àwọn ọ̀nà tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tàbí láwọn ibi tí irà wà nínú oòrùn tó mú ganrínganrín, àá wá kó àwọn ìwé àtàwọn nǹkan míì tá a nílò sínú báàgì àpọ̀nsẹ́yìn. A máa ń gbádùn ìrìn àjò yìí gan-an torí bá a ṣe ń kọ́wọ̀ rìn pẹ̀lú àwọn ara, bẹ́ẹ̀ la máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró, a sì máa ń para wa lẹ́rìn.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ nínú 1 Tẹsalóníkà 2:8 pé: ‘Bí a ṣe ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí yín, a ti pinnu pé a máa fún yín ní ara wa, torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.’ Irú ìfẹ́ yìí làwọn ará wa náà ní sí wa, kódà wọ́n ṣe tán láti kú kí wọ́n lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú tó fẹ́ ṣe wá ní jàǹbá. Mo rántí ọjọ́ kan tí ọkùnrin kan fẹ́ ṣá ìyàwó mi ládàá, mi ò sí níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn torí pé abúlé míì ni mo ti ń wàásù. Ọpẹ́lọpẹ́ arákùnrin kan tó bọ́ sáàárín ọkùnrin náà àti ìyàwó mi, òun ló fara gba àdá náà, ó sì ṣèṣe díẹ̀. Àwọn ará tó kù ya bo ọkùnrin tí inú ń bí yìí kí wọ́n lè gba àdá lọ́wọ́ ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìpá túbọ̀ ń burú sí i ní ìlú yẹn, ojoojúmọ́ là ń rọ́wọ́ Jèhófà láyé wa tó ń pa wá mọ́ káwọn ará wa lè máa rí àbójútó tẹ̀mí tí wọ́n nílò.
Torí pé Papua New Guinea ò fi bẹ́ẹ̀ láwọn ilé ìwòsàn tó pọ̀, kò rọrùn fún wa láti máa rí ìtọ́jú tá a nílò látìgbàdégbà. Lọ́dún 2010, ìyàwó mi kó àrùn burúkú kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀, ojú ẹsẹ̀ la wọkọ̀ òfúrufú lọ sí Ọsirélíà kó lè gbà tọ́jú ní kíákíá. Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo àkókò yìí. Nígbà tó yá àwọn dókítà rí oògùn tó wo àìsàn ẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn dókítà náà sọ fún wa pé: “Àwọn iṣẹ́ rere tẹ́ ẹ ti ṣe fún Ọlọ́run yín, èrè ẹ̀ lẹ̀ ń gbà báyìí.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, a pa dà sẹ́nu iṣẹ́ wa.
Iṣẹ́ Pọ̀ Láti Ṣe Ní Ọsirélíà
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀ ìgbà la lọ sí Ọsirélíà fún ìtọ́jú ìyàwó mi. Àmọ́ nígbà tó dọdún 2012, ètò Ọlọ́run sọ pé ká kúkú dúró sí Ọsirélíà ká lè máa gba ìtọ́jú tó yẹ. Lẹ́yìn tá a pa dà dé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìlera ìyàwó mi lohun tó ṣòro jù fún wa láti bá yí, àmọ́ ohun tó ṣòro jù ni pé gbogbo nǹkan ṣàjèjì sí wa, torí ó ti pẹ́ tá a ti kúrò ní Ọsirélíà. Ó dùn wá gan-an pé a fẹ́ fi iṣẹ́ wa tá a gbádùn àtàwọn ará wa tá a nífẹ̀ẹ́ sílẹ̀. Kódà ṣe ló ń ṣe wá bíi pé a ti já Jèhófà kulẹ̀, a ò sì lè wúlò fún un mọ́. Torí ó sì ti pẹ́ tá a ti kúrò, ara wa ò mọlé mọ́. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ará tó dúró tì wá, ìyẹn ló jẹ́ ká lè fara dà á.
Lẹ́yìn tí ara ìyàwó mi yá, ètò Ọlọ́run ní ká lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Wollongong, tó wà ní gúúsù Sydney, ní New South Wales. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, inú wá dùn gan-an nígbà tí ètò Ọlọ́run pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fáwọn Tọkọtaya (tá à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí). Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Australasia ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Láwọn ọdún tá a ti lò lẹ́nu iṣẹ́ yìí, onírúurú ìjọ àti àwọn àwùjọ la ti bẹ̀ wò. A ti lọ sáwọn ìjọ tó wà ní ìgboro àwọn ìjọ tó wà ní aṣálẹ̀, títí kan àwọn èyí tó wà ní abúlé tí wọ́n ti ń pẹja. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn ìjọ tó wà ní aṣálẹ̀ àríwá Ọsirélíà àti orílẹ̀-èdè Timor-Leste là ń bẹ̀ wò.
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìyàwó tó fún mi. Ìyàwó mi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì dúró tì mí nígbà dídùn àti nígbà kíkan. Ìyàwó mi kì í kọ iṣẹ́ èyíkéyìí tí ètò Ọlọ́run bá fún wa bó ti wù kó le tó. Tí wọ́n bá bi í pé ọgbọ́n wo ló ń dá sí i tó fi lè fara da àwọn ìṣòro tó ní, á sọ fún wọn pé, “Mo máa ń sọ gbogbo ìṣòro mi fún Jèhófà.” Lẹ́yìn náà, tó bá ka Bíbélì, ó máa ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà nípa bó ṣe yẹ kóun máa ronú àtohun tó yẹ kóun ṣe.
Mi ò kábàámọ̀ pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni mo fayé mi ṣe, dípò kí n máa lé bí mo ṣe máa di gbajúgbajà nídìí eré ìdárayá. Mo ti rí i pé tí Jèhófà bá fún wa ní iṣẹ́ èyíkéyìí téèyàn sì tẹ́wọ́ gbà á, ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣiṣẹ́ náà láṣeyọrí. Mo tún ti kọ́ pé ojoojúmọ́ ló yẹ kéèyàn máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún èèyàn ní ọgbọ́n àti ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ téèyàn bá níṣòro tàbí tó bá fẹ́ ṣèpinnu. A dúpẹ́ pé Jèhófà Baba wa ọ̀run ti mú káyé wa dùn kó lóyin, a sì ń fojú sọ́nà fáwọn nǹkan míì tó máa mú ká gbéṣe bó tiẹ̀ jẹ́ pé “ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe” ni wá.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
a Ìtàn ìgbésí ayé Max Lloyd wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2012, ojú ìwé 17-21.
b Tẹ́ ẹ bá fẹ́ kà nípa àwọn ìbẹ̀wò tá a ṣe nínú ọkọ̀ ojú omi, ó wà nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2011, ojú ìwé 129-134 lédè Gẹ̀ẹ́sì.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Òkè Ẹfun Gàgàrà Lójú Òfuurufú” nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 2010, ojú ìwé 16-17.