Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Bá A Ṣe Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù Lọ́dún 2022—A Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ará

Bá A Ṣe Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù Lọ́dún 2022—A Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ará

JANUARY 1, 2023

 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àti “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù” máa wà lákòókò wa yìí. (Lúùkù 21:10, 11) Gbogbo àwọn ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ yìí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2022. a Bí àpẹẹrẹ, ogun tó ń jà ní Ukraine kò tíì dáwọ́ dúró, ó sì ti ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn. Ọ̀pọ̀ ibi láyé ni ràbọ̀ràbọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà ò tíì tán lára wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ni àjálù ti ṣẹlẹ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Haiti, ìjì tó lagbára jà ní Central America, ní Philippines àti ní apá gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà. Báwo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí yìí lọ́wọ́?

 Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2022, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará níbi gbogbo tí àjálù ti ṣẹlẹ̀. Àwọn àjálù tó ṣẹlẹ̀ náà sì tó ọgọ́rùn-ún méjì (200). Lápapọ̀, a ná ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjìlá owó dọ́là láti pèsè ìrànwọ́. b Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àjálù méjì àti bá a ṣe ná owó tẹ́ ẹ fi ṣètọrẹ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí.

Àwọn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Ṣẹlẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Haiti

 Ní August 14, 2021, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára gan-an tó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ ṣẹlẹ̀ ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Haiti. Ó bani nínú jẹ́ pé arábìnrin méjì àti arákùnrin kan bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Àwọn ará tó kù pàdánù àwọn ohun ìní wọn, nǹkan sì tojú sún wọn. Arákùnrin Stephane sọ pé: “Ìlú ò fara rọ rárá torí ọ̀pọ̀ èèyàn ló kú débi pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ní wọ́n ń ṣètò ìsìnkú fún ohun tó ju oṣù méjì lọ.” Arákùnrin míì tó ń jẹ́ Éliézer sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn Ará ni ò ní àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, irú bí ilé, aṣọ, bàtà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí burú débi pé ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ẹ̀rù ṣì ń ba àwọn èèyàn.”

 Ojú ẹsẹ̀ ni ètò Ọlọ́run dìde ìrànwọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Haiti gbé oúnjẹ tọ́ọ̀nù mẹ́tàléláàádọ́ta (53) lọ fún wọn. Bákan náà, wọ́n fún wọn láwọn àtíbàbà, tapólì, bẹ́ẹ̀dì, àti ẹ̀rọ solar tí wọ́n lè fi gba iná sórí fóònù wọn. Láfikún síyẹn, lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2022 àwọn ilé tó ju ọgọ́rùn-ún (100) lọ ni wọ́n tún kọ́ tàbí tún ṣe. Ohun tá a ná láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́ ju mílíọ̀nù kan dọ́là lọ.

Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè Haiti

 Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin mọyì ètò ìrànwọ́ tí wọ́n rí gbà yìí gan-an. Arábìnrin Lorette sọ pé: “Ìmìtìtì ilẹ̀ náà ba ilé wa jẹ́ pátápátá, ó sì ṣàkóbá fún iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. A ò tiẹ̀ ni nǹkan kan tá a lè jẹ. Àmọ́ ètò Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ rárá, wọ́n pèsè gbogbo ohun tá a nílò.” Arábìnrin Micheline sọ pé: “Ìmìtìtì ilẹ̀ náà ba ilé wa jẹ́, ibẹ̀ sì lèmi àtàwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì ń gbé. Mi ò mọ ohun tí mo lè ṣe, ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, Jèhófà sì lo ètò rẹ̀ láti dáhùn àdúrà mi. Wọ́n bá wa kọ́ ilé tuntun tó dúró dáadáa. Mo ti pinnu pé máa ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti fi hàn pé mo mọyì oore ńlá tí Jèhófà ṣe fún mi yìí.”

 Àwọn aláṣẹ kíyè sí àwọn ètò ìrànwọ́ tá à ń ṣe. Olùdarí gbọ̀ngàn ìlú L’Asile sọ pé: “Inú mi dùn gan-an láti rí bẹ́ẹ ṣe tètè wá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Mo sì tún gbóríyìn fún yín torí pé ẹ bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Ó wú mi lórí bí mo ṣe rí i pé kì í ṣe torí owó lẹ ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ torí ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn.”

Ìjì Líle Kan Tó Ń Jẹ́ Ana Jà Lórílẹ̀-Èdè Màláwì àti Mòsáńbíìkì

 Ní January 24, 2022, ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Ana jà ní orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì àti Màláwì. Ìjì líle náà fa òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá àti atẹ́gùn tó lágbára gan-an. Ìjì yìí fa omíyalé, ó sì tún ba iná mànàmáná àti afárá jẹ́.

 Ó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) àwọn ará tí ìjì náà ṣèpalára fún ní orílẹ̀-èdè Màláwì àti Mòsáńbíìkì. Arákùnrin Charles tó ń bá àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù ṣiṣẹ́, sọ pé: “Nígbà tí mo rí bí ìyà ṣe ń jẹ́ àwọn ará wa àti ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n pàdánù, ọkàn mi gbọgbẹ́, ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá mi.” Èyí tó burú jù ni pé oúnjẹ wọn àti ohun tí wọ́n fi lè gbọ́ bùkátà ti bá omi lọ. Ọ̀pọ̀ ni kò nílé lórí mọ́. Ó ṣeni láàánú pé ìyàwó arákùnrin kan àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì ló kú nígbà tí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ dojú dé.

Ilé tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó bà jẹ́ lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì

Lẹ́yìn tí wọ́n tún ilé náà kọ́

 Ìjì náà le gan-an. Ní aago kan òru nílùú Nchalo ní Màláwì, ìdílé Sengeredo gbọ́ ìró omi tó ń ya bọ̀. Àwọn odò méjì ti kún àkúnya! Arákùnrin Sengeredo ní kí wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu gan-an torí kò pẹ́ sígbà yẹn ni àkúnya omi yẹn wó ilé wọn. Gbogbo nǹkan ìní wọn ló ṣeé ṣe kó ti bà jẹ́ tàbí kó ti bómi lọ. Torí náà, wọ́n pinnu láti lọ sí Ilé Ìpàdé wa, èyí ò sì ju ìrìn ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú lọ. Àmọ́ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, wákàtí méjì ni wọ́n fi rìn dé Ilé Ìpàdé náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo aṣọ wọn ti tutù, tó sì ti rẹ̀ wọ́n, a dúpẹ́ pé wọ́n débẹ̀ ní àlàáfíà.

 Láìfi àkókò falẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Màláwì àti Mòsáńbíìkì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ìrànwọ́. Torí náà, wọ́n ní kí àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan táwọn ará nílò kí wọ́n sì fún wọ́n níṣìírí nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn náà, wọ́n yan àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù bíi mélòó kan láti bójú tó ètò ìrànwọ́ náà. Ojú ẹsẹ̀ làwọn ìgbìmọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ra oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì táwọn ará wa nílò. Ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ($33,000) owó dọ́la tá a ná láti fi ra oúnjẹ àtàwọn nǹkan kòṣeémáàní míì, kódà ó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ($300,000) owó dọ́là tá a ná láti fi ṣàtúnṣe àti àtúnkọ́ àwọn ilé tó bà jẹ́.

 Àwọn ìgbìmọ̀ yìí fọgbọ́n ná owó tá a ṣètò fún ìrànwọ́ náà, èyí sì ṣe pàtàkì torí bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń wọ́n sí i. Bí àpẹẹrẹ, lóṣù méje àkọ́kọ́ tá a bẹ̀rẹ̀ ètò ìrànwọ́ náà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì ni iye tí wọ́n ń ta àgbàdo lílọ̀ fi wọ́n sí i, oúnjẹ yìí sì làwọn ara Màláwì fẹ́ràn jù. Owó epo tún lọ sókè sí i. Ká lè ṣọ́wó ná, wọ́n ra àwọn oúnjẹ àtàwọn ohun èlò ìkọ́lé lọ́pọ̀ lórílẹ̀-èdè Màláwì, èyí sì jẹ́ kí owó tá a ná lórí àwọn ohun tá a rà títí kan iye tá a fi kó àwọn ẹrù náà dín kù.

 Inú àwọn ará wa dùn gan-an fún ètò ìrànwọ́ yìí. Arákùnrin Felisberto tó wà ní Mòsáńbíìkì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ètò Ọlọ́run pèsè fún wa nígbà àjálù yìí, bí àwọn ohun èlò ìkọ́lé, nǹkan ìrìnsẹ̀ tá a fi kó ẹrù títí kan àwọn tó wá bá wa tún ilé ṣe. Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n pèsè oúnjẹ àti àwọn ìtọ́ni tó jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ lóye ohun tí Jésù sọ nípa ìfẹ́ ara ní Jòhánù 13:34, 35. Mi ò rí irú èyí rí láyé mi.” Arábìnrin Ester tó jẹ́ opó tí ilé ẹ̀ bà jẹ́ ní Màláwì sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an torí kò síbi tí màá ti rí owó tí màá fi kọ́ ilé míì. Torí náà, nígbà táwọn arákùnrin yìí wá bá mi kọ́ ilé míì, ṣe ló dà bíi pé mo ti wà nínú ayé tuntun.”

 Bí òpin ayé ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, a mọ̀ pé àjálù á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. (Mátíù 24:7, 8) Àmọ́ ó dá wa lójú pé àwọn èèyàn Jèhófà máa rí àwọn nǹkan tí wọ́n nílò torí bẹ́ ẹ ṣe máa ń ṣètìlẹyìn tinútinú. Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà ṣètìlẹyìn, lọ sí donate.jw.org. A mọyì yín gan-an fún bẹ́ ẹ ṣe máa ń ṣètìlẹyìn.

a Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2022 bẹ̀rẹ̀ ní September 1, 2021, ó sì parí ní August 31, 2022.

b Gbogbo owó tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ owó dọ́la ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.