Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ LÓYE BÍBÉLÌ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Lóye Bíbélì?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Lóye Bíbélì?

“Bíbélì gbayì gan-an nínú àwọn ìwé ìsìn. Àmọ́ ìwé àjèjì ni, kò sì wúlò fún àwa ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà.”—LIN, ṢÁÍNÀ.

“Mi ò lóye ohun tó wà nínú ìwé ìsìn Híńdù tí mò ń ṣe. Báwo ni màá ṣe wá lóye Bíbélì?”—AMIT, INDIA.

“Mo gbà pé ọba ìwé ni Bíbélì, torí ó lọ́jọ́ lórí, ó sì ń tà gan-an. Àmọ́, mi ò ríkan rí.”—YUMIKO, JAPAN.

Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló gbà pé ọba ìwé ni Bíbélì. Síbẹ̀, wọn ò mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ tàbí kó jẹ́ díẹ̀ ni ohun tí wọ́n mọ̀ níbẹ̀. Ìṣòro yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà, ó sì tún wà láwọn àgbègbè tí Bíbélì pọ̀ sí pàápàá.

O lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tó fi yẹ kí n lóye Bíbélì?’ Tó o bá lóye ohun tó wà nínú Bíbélì:

  • Wàá ní ìtẹ́lọ́rùn, wàá sì láyọ̀

  • Wàá lè kojú àwọn ìṣòro ìdílé

  • Wàá lè gbé àwọn àníyàn ìgbésí ayé kúrò lọ́kàn

  • Àárín ìwọ àtàwọn èèyàn máa túbọ̀ gún

  • Wàá mọ bí èèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná

Wo àpẹẹrẹ Yoshiko tó ń gbé ní Japan. Ó ti máa ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó wà nínú Bíbélì, ló bá pinnu láti kà á. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó sọ pé: “Bíbélì ti jẹ́ káyé mi nítumọ̀, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.” Ó wá fí kún un pé: “Ní báyìí, ọkàn mi balẹ̀.” Amit tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá sọ pé: “Ohun tí mo bá nínú rẹ̀ yà mí lẹ́nu. Mo rí i pé àwọn nǹkan tó máa ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní ló wà nínú Bíbélì.”

Bíbélì ti tún ayé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ṣe kárí ayé. Ìwọ náà lè yẹ̀ ẹ́ wò, kó o sì rí bó ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní.