Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Mu?

Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Mu?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, síbẹ̀ tó bá mẹ́nu kan àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, òótọ́ ló máa ń sọ. Jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò tó fi hàn pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ohun tí Bíbélì sọ mu. Nínú Bíbélì, a rí àlàyé tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu tí Bíbélì ṣe tó sì yàtọ̀ gédégbé sí ohun tàwọn èèyàn tó ń gbé lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì gbà gbọ́.

  •   Àgbáálá ayé wa yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn ìtàn àròsọ ayé ọjọ́un kan sọ pé àgbáálá ayé wa yìí kàn ṣàdédé wà ni, pé kò sí ẹni tó ṣẹ̀dá rẹ̀. Àwọn ará Bábílónì gbà gbọ́ pé láti inú omi òkun méjì ni àwọn ọlọ́run tó bí àgbáálá ayé wa yìí ti wá. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu míì sọ pé inú ẹyin ńlá kan ni àgbáálá ayé ti ṣẹ̀ wá.

  •   Àwọn ìlànà tó bọ́gbọ́n mu tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ ló ń darí àgbáálá ayé lójoojúmọ́, kì í ṣe èrò àwọn ọlọ́run àjúbàfún. (Jóòbù 38:33; Jeremáyà 33:25) Àwọn ìtàn àròsọ kan tó kárí ayé sọ pé kò sẹ́ni tó lè gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí àwọn ọlọ́run tí kò láàánú ń fà.

  •   Kò sí nǹkan kan tó gbé ayé dúró. (Jóòbù 26:7) Ọ̀pọ̀ àwọn tó gbé láyé nígbà àtijọ́ gbà pé ayé rí pẹrẹsẹ, ó sì dúró lórí òmìrán kan tàbí ẹranko kan bí ẹfọ̀n tàbí ìjàpá.

  •   Omi tí oòrùn bá fà sókè láti inú agbami òkun àtàwọn orísun míì ló máa di òjò, ìrì àti yìnyín tó máa ń rọ̀ padà sí ayé, lẹ́yìn náà, omi yìí á wá ṣàn lọ sínú odò tàbí kó di ìsun omi. (Jóòbù 36:27, 28; Oníwàásù 1:7; Aísáyà 55:10; Ámósì 9:6) Àwọn ará Gíríìkì ìgbàanì rò pé láti inú omi òkun abẹ́ ilẹ̀ ni omi tí ń ṣàn lọ sínú odò, èrò yìí ṣì ni wọ́n ní títí di ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún.

  •   A máa ń rí òkè ńlá tí omi òkun tó bò o mọ́lẹ̀ bá fà, òkè ńlá tí à ń rí lóde òní ti fìgbà kan wà lábẹ́ òkun. (Sáàmù 104:6, 8) Àmọ́, onírúurú ìtàn àròsọ sọ pé àwọn ọlọ́run ló dá àwọn òkè síbi tí wọ́n wà.

  •   Ìmọ́tótó borí àrùn. Ọlọ́run sọ ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe nínú Òfin tó fún wọn. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n máa fọ ọwọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ọwọ́ kan òkú, kí wọ́n sé àwọn tí wọ́n ní àrùn mọ́, kí wọ́n sì máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. (Léfítíkù 11:28; 13:1-5; Diutarónómì 23:13) Àmọ́, nígbà tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin yìí, àwọn ará Íjíbítì máa ń fi ìgbọ̀nsẹ̀ wọn ṣe oògùn tí wọ́n máa ń fi sí ojú egbò.

Ṣé àwọn ohun tí kì í ṣe òótọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì wà nínú Bíbélì?

 Tó o bá fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò Bíbélì, wàá rí i pé rárá ni ìdáhùn ìbéèrè yìí. Àwọn kan sọ pé Bíbélì ò bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, díẹ̀ lára àwọn ohun tí kì í ṣe òótọ́ tí wọ́n sọ nípa Bíbélì nìyí:

 Ohun tí kì í ṣe òótọ́: Bíbélì sọ pé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún mẹ́fà ni Ọlọ́run fi dá àgbáálá ayé.

 Òótọ́: Bíbélì ò sọ pé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni Ọlọ́run fi dá àgbáálá ayé, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé tipẹ́tipẹ́ ló ti dá a. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Àwọn ọjọ́ tí Jẹ́nẹ́sísì orí 1 sọ pé Ọlọ́run dá ayé jẹ́ àkókò tí Bíbélì ò sọ bó ṣe gùn tó. Kódà, “ọjọ́” ni Bíbélì pe gbogbo àkókò tí Ọlọ́run fi dá ọ̀run àti ayé.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:4.

 Ohun tí kì í ṣe òótọ́: Bíbélì sọ pé ewéko ti wà kí Ọlọ́run tó dá oòrùn tó máa mú kí ewéko mú irúgbìn jáde.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 16.

 Òótọ́: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti dá oòrùn tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ tó wà ní “ọ̀run” kí ó tó dá ewéko. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ìmọ́lẹ̀ tó wá láti ara oòrùn tàn sórí ayé ní “ọjọ́” àkọ́kọ́ tàbí àkókò ìṣẹ̀dá tí Bíbélì kò sọ bó ṣe gùn tó. Nígbà tó máa fi di “ọjọ́” kẹta, kò sí nǹkan kan mọ́ lójú òfuurufú, ìmọ́lẹ̀ tó sì wà níbẹ̀ tó láti mú kí àwọn ewéko dàgbà kí wọ́n sì méso jáde. (Jẹ́nẹ́sísì 1:3-5, 12, 13) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni oòrùn ṣẹ̀ wá fara hàn kedere sí ilẹ̀ ayé.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:16.

 Ohun tí kì í ṣe òótọ́: Bíbélì sọ pé oòrùn ń yí ayé po.

 Òótọ́: Oníwàásù 1:5 sọ pé: “Oòrùn pẹ̀lú ti yọ, oòrùn sì wọ̀, ó ń mí hẹlẹhẹlẹ sáré bọ̀ ní ipò rẹ̀ níbi tí yóò ti yọ.” Àmọ́ ńṣe ni ẹsẹ yìí ń sọ bí a ṣe máa ń rí oòrùn tó ń yọ, tó ń sì ń wọ̀ láti orí ilẹ̀ ayé. A lè gbọ́ kí ẹnì kan sọ pé “oòrùn yọ” tàbí “oòrùn wọ̀,” ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ohun tí onítọ̀hún ń sọ ni pé oòrùn ń yí ayé po.

 Ohun tí kì í ṣe òótọ́: Bíbélì sọ pé ayé rí pẹrẹsẹ.

 Òótọ́: Bíbélì lo gbólóhùn náà “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé” tó túmọ̀ sí òpin ilẹ̀ ayé. Èyí ò túmọ̀ sí pé ayé rí pẹrẹsẹ tàbí pé ó ní igun. (Ìṣe 1:8) Bákan náà, ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò, ìyẹn “ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé,” jẹ́ àkànlò èdè tó túmọ̀ sí gbogbo ayé. Ó dà bí ìgbà tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀ nípa igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìyẹn àríwá, gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn.​—Aísáyà 11:12; Lúùkù 13:29.

 Ohun tí kì í ṣe òótọ́: Bíbélì sọ pé tá a bá fi okùn wọn nǹkan tó rí róbótó yíká, ìwọ̀n tó máa fún wa máa jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta téèyàn bá wọ̀n ọ́n láti igun kan sí ìkejì. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, torí ó máa ń jù bẹ́ẹ̀ lọ.

 Òótọ́: Ohun tí Bíbélì sọ nínú 1 Àwọn Ọba 7:23 àti 2 Kíróníkà 4:2 fi hàn pé ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni ìwọ̀n “òkun dídà” tàbí “agbada ńlá dídà” tó rí róbótó náà téèyàn bá fi okùn wọ̀n ọ́n láti igun kan sí ìkejì. ‘Ó sì gba okùn tí ó jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti na àyíká rẹ̀ já.’ Ìyẹn ni pé tá a bá fi okùn wọn agbada tó rí róbótó náà yíká, ìwọ̀n tó máa fún wa máa jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta tá a bá wọ̀n ọ́n láti igun kan sí ìkejì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdiwọ̀n tó ṣe pàtó ni Bíbélì lò nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé téèyàn bá wọn agbada tó rí róbótó náà tinú tòde, ìwọ̀n tó máa fún wa ni Bíbélì sọ yẹn.