Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí nìdí tí kò fi sí àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé?

Ìjọba tó bá lè yí ìwà àwọn èèyàn pa dà ló lè mú kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé

Bíbélì sọ ìdí méjì pàtó tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni àwọn èèyàn ti gbé ṣe lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run kò dá wọn pé kí wọ́n máa darí ara wọn. Ìdí kejì sì ni pé, gbogbo ọgbọ́n tí àwọn èèyàn ń dá ló ń já sí pàbó torí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. Abájọ tó fi jẹ́ pé, pẹ̀lú gbogbo bí ẹ̀dá èèyàn ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe tó, wọn kò lè mú kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Jeremáyà 10:23; 1 Jòhánù 5:19.

Bákan náà, bí àwọn èèyàn kò ṣe mọ̀ ju tara wọn nìkan, tí wọ́n sì ń wá ipò ńlá lójú méjèèjì ò jẹ́ kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé. Ìjọba tó bá lè kọ́ àwọn èèyàn láti máa ṣe ohun tí ó tọ́, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn ló lè mú kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Aísáyà 32:17; 48:18, 22.

Ta ló máa mú kí àlàáfíà jọba lórí ilẹ̀ ayé?

Ọlọ́run Olódùmarè ti ṣèlérí pé òun máa mú kí ìjọba kan ṣoṣo ṣàkóso lórí gbogbo aráyé. Ìjọba yìí ló máa rọ́pò ìjọba èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44) Jésù, Ọmọkùnrin Ọlọ́run, ló máa ṣàkóso bí Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ó máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè máa gbé ní àlàáfíà.—Ka Aísáyà 9:6, 7; 11:4, 9.

Ní báyìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Jésù. Wọ́n ń fi Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn ní bí wọ́n ṣe máa wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn. Láìpẹ́, àlàáfíà máa jọba kárí ayé.—Ka Aísáyà 2:3, 4; 54:13.