Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yóò Ní Láti Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”

“Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yóò Ní Láti Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”

BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ tí ẹnì kan bá fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí o kò mọ̀ nípa rẹ̀ rárá kàn ọ́? Tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń jìyà gan-an nítorí ìwà ọ̀daràn ọ̀hún ńkọ́, àní títí kan àwọn ẹni ẹlẹ́ni tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀? Ó dájú pé wàá fẹ́ wẹ orúkọ ara rẹ mọ́! Ǹjẹ́ o mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ sí Jèhófà? Lónìí, ọ̀pọ̀ máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi ohun tí kò ṣe, wọ́n á ní Ọlọ́run ló fa ìwà ìrẹ́jẹ àti ìyà tó ń jẹ aráyé. Ǹjẹ́ o rò pé Jèhófà máa wá nǹkan ṣe sí i kí ó lè wẹ orúkọ rẹ̀ mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o! Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí ó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì.—Ka Ìsíkíẹ́lì 39:7.

Jèhófà sọ pé: “Èmi kì yóò sì jẹ́ kí a sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ mọ́.” Nígbà tí àwọn èèyàn bá ń sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ìdájọ́ òdodo, ṣe ni wọ́n ń sọ orúkọ rẹ̀ di aláìmọ́. Lọ́nà wo? Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “orúkọ” sábà máa ń tọ́ka sí irú ẹni tí èèyàn jẹ́. Ìwé ìwádìí kan sọ pé orúkọ Ọlọ́run dúró fún “ohun tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ohun tó ṣí payá nípa ara rẹ̀; ó sì tún dúró fún ògo rẹ̀, àti iyì rẹ̀.” Orúkọ Jèhófà wé mọ́ irú ẹni tó jẹ́. Wàyí o, irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìwà àìṣe ìdájọ́ òdodo? Ó kórìíra rẹ̀ gan-an ni! Àánú àwọn tí wọ́n bá hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí sì máa ń ṣe é gan-an. * (Ẹ́kísódù 22:22-24) Torí náà tí àwọn èèyàn bá ń fi ẹ̀sùn àwọn ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kórìíra kan Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ “hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ” rẹ̀.—Sáàmù 74:10.

Ṣàkíyèsí pé ẹ̀ẹ̀mejì ni Jèhófà lo ọ̀rọ̀ náà “orúkọ mímọ́ mi.” (Ẹsẹ 7) Nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń lo orúkọ Jèhófà pa pọ̀ mọ́ “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́.” Ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” máa ń fi hàn pé ohun tí à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ èyí tí a yà sọ́tọ̀; pé ó mọ́ nigín-nigín, kò sì ní àbàwọ́n kankan. Orúkọ Jèhófà jẹ́ mímọ́ torí pé òun fúnra rẹ̀ tó ń jẹ́ orúkọ náà jẹ́ mímọ́, ìyẹn ni pé ó jìnnà pátápátá sí ohunkóhun tí ó bá jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí àìmọ́. Ǹjẹ́ o ti wá rí ìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀gàn ńláǹlà ni àwọn èèyàn ń mú bá orúkọ Jèhófà tí ó jẹ́ “orúkọ mímọ́,” nígbà tí wọ́n bá ń sọ pé Jèhófà ń ṣe nǹkan búburú?

Ète Jèhófà láti fọ orúkọ rẹ̀ mọ́ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ni lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì. Ìwé Ìsíkíẹ́lì tẹnu mọ́ ọn lemọ́lemọ́ pé “àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsíkíẹ́lì 36:23; 37:28; 38:23; 39:7) Kíyè sí i pé, àwọn orílẹ̀-èdè kò ní fúnra wọn yàn láti mọ̀ pé òun ni Jèhófà tàbí pé òun kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n fẹ́ bí wọ́n kọ̀, ó ní wọn ‘yóò ní láti mọ̀.’ Èyí fi hàn pé Jèhófà máa ṣe nǹkan tí ó máa mú kó di dandan fún àwọn orílẹ̀-èdè ayé láti gbà pé òun jẹ́ ẹni tí òun sọ pé òun jẹ́, ìyẹn Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ tí orúkọ rẹ̀ dúró fún gbogbo ohun tó jẹ́ mímọ́, tó mọ́ nigín-nigín tí kò sì ní àbàwọ́n kankan.

Ìlérí tí Jèhófà ṣe lemọ́lemọ́ pé “àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,” jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n ń retí pé kí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìjìyà dópin. Jèhófà yóò mú ìlérí yẹn ṣẹ láìpẹ́, yóò sì mú gbogbo ẹ̀gàn tí àwọn èèyàn ti mú bá orúkọ rẹ̀ kúrò. Yóò mú ìwà ibi àti gbogbo àwọn tí ó ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀ kúrò. Àmọ́ gbogbo àwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú orúkọ rẹ̀, tí wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ yẹn àti gbogbo ohun tí ó dúró fún ni yóò pa mọ́. (Òwe 18:10) Ǹjẹ́ èyí kò mú kí ó wù ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí o ṣe lè sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́ tí ó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo”?—Sáàmù 37:9-11, 28.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún September:

Ìsíkíẹ́lì 39-48Dáníẹ́lì 1-3

^ Wo àpilẹ̀kọ náà ““Sún Mọ́ Ọlọ́run—Ó Fẹ́ràn Ìdájọ́ Òdodo,” èyí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2008.