Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìdáhùn

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìdáhùn

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìdáhùn

“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ní èrò tiẹ̀ nípa irú ẹni tí [Jésù] jẹ́. Yálà ìgbàgbọ́ wa pọ̀ tàbí ó kéré tàbí a tiẹ̀ jẹ́ oníyèmejì paraku, gbogbo wa la máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni ọkùnrin yìí?’”—AUTHOR STAN GUTHRIE.

ÀWỌN èèyàn máa ń fẹ́ mọ ẹni tí Jésù jẹ́. Ọ̀pọ̀ ìwé táwọn èèyàn kọ nípa rẹ̀ ti di ọ̀kan lára ìwé tó tà jù láyé. Àwọn fíìmù tí wọ́n ṣe nípa rẹ̀ di èyí tó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ta. Síbẹ̀ àwọn èèyàn ò yéé béèrè ìbéèrè nípa Jésù. Ìdí ni pé oríṣiríṣi èrò tó yàtọ̀ síra ni àwọn èèyàn ní nípa ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an.

Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, àwọn akọ̀ròyìn méjì kan bi àwọn aráàlú pé, “Ta ni Jésù?” Wọ́n wá sọ pé kí àwọn èèyàn fi èsì wọn ránṣẹ́ sórí ìkànnì àwọn. Ara àwọn ìdáhùn tí wọ́n rí gbà nìwọ̀nyí:

● “Rábì (ìyẹn olùkọ́) tó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nínú kéèyàn jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ni Jésù.”

● “Èèyàn bíi tiwa ni, àmọ́ ó gbé ìgbé ayé àrà ọ̀tọ̀.”

● “Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé Jésù tiẹ̀ wà.”

● “Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n bí, tó kú, tó sì jíǹde láti gbà wá là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó ń bẹ láàyè títí dòní, Ó sì tún máa pa dà wá sí ayé.”

● “Mo gbà gbọ́ pé Jésù Kristi ni ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run. Ènìyàn ni, ọlọ́run sì tún ni, méjèèjì ló jẹ́ pa pọ̀ lẹ́sẹ̀ kan náà.”

● “Jésù jẹ́ ẹ̀dá inú àlọ́ lásán, ṣe ló dà bí ìgbà tí èèyàn ń pa ìtàn ìjàpá fún aròbó.”

Dájúdájú, kò lè jẹ́ pé gbogbo èrò tó yàtọ̀ síra wọ̀nyẹn ló tọ̀nà. Ǹjẹ́ ibì kan wà tí a ti lè rí ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé, tó sì jóòótọ́, tó máa dáhùn àwọn ìbéèrè wa nípa Jésù? Àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn tó o ń kà yìí gbà gbọ́ pé Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé Bíbélì nìkan ṣoṣo ló lè sọ òtítọ́ délẹ̀délẹ̀ fún wa nípa Jésù. *2 Tímótì 3:16.

Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a máa wo bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa Jésù. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́” nínú òun yóò rí ìgbàlà. (Jòhánù 3:16) A rọ̀ ọ́ pé kó o wo àwọn ìdáhùn náà, kí o sì wá pinnu fúnra rẹ bóyá wàá fẹ́ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù àti bó o ṣe lè dẹni tó ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 2 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àkòrí rẹ̀ ni “Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.