Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Ayọ̀ àti Ọjọ́ Ìrètí Ohun Rere

Ọjọ́ Ayọ̀ àti Ọjọ́ Ìrètí Ohun Rere

Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Àádóje Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Ọjọ́ Ayọ̀ àti Ọjọ́ Ìrètí Ohun Rere

LÁÌSÍ àní-àní, ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì àádóje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì yìí ń mú kí inú àwọn tó wà níbẹ̀ máa dùn, wọ́n sì ń retí ohun rere. Ní Sátidé, March 12, ọdún 2011, èèyàn tí ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [8,500] ló pé jọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà, títí kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́, pẹ̀lú ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Yàtọ̀ sí pé inú àwọn èèyàn tó wá síbi ayẹyẹ yìí ń dùn nítorí ọjọ́ náà, inú wọn tún ń dùn nítorí àwọn míṣọ́nárì tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa náà tí wọ́n máa tó rán lọ káàkiri ayé láti kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì.

“Aláyọ̀ Ni Gbogbo Àwọn Tí Ń Bá A Nìṣó Ní Fífojúsọ́nà fún” Jèhófà

Ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú yìí, tó wà nínú ìwé Aísáyà 30:18, ni àkòrí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Geoffrey Jackson sọ. Ó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun sì ni alága ayẹyẹ náà. Pẹ̀lú ọ̀yàyà àti àwàdà ráńpẹ́, ó gbóríyìn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe ní sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àwọn nǹkan wo làwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà lè máa retí lọ́jọ́ iwájú? Ó sọ àwọn kókó pàtàkì mẹ́ta látinú ìwé Aísáyà 30:18-21.

Àkọ́kọ́, Arákùnrin Jackson sọ pé, “Ẹ lè retí pé Jèhófà yóò gbọ́ àdúrà yín.” Ó tọ́ka sí ọ̀rọ̀ ìdánilójú tó wà ní ẹsẹ 19, ó ní: “[Ọlọ́run] yóò fi ojú rere hàn sí ọ ní gbígbọ́ ìró igbe ẹkún rẹ.” Arákùnrin Jackson ṣàlàyé pé, ọ̀rọ̀ Hébérù náà, “ọ” tí wọ́n lò fún ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ nínú ẹsẹ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún ẹnì kan ṣoṣo kì í ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn, nítorí náà, ó sọ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. “Bíi Bàbá onífẹ̀ẹ́, Jèhófà kì í sọ pé, ‘Kí ló dé tí ìwọ kò ní ìgbàgbọ́ bíi ti lágbájá?’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń tẹ́tí gbọ́ àdúrà ẹnì kọ̀ọ̀kan, ó sì máa ń dáhùn.”

Ìkejì, olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé, a lè máa retí àwọn ìṣòro. “Jèhófà kò ṣèlérí pé gbogbo nǹkan á máa rọrùn, àmọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́.” Ní ẹsẹ 20, Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé, tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wàhálà yóò wá dà bí oúnjẹ àti ìnilára bí omi fún wọn. Àmọ́, ìgbà gbogbo ni Jèhófà múra tán láti dá àwọn èèyàn náà nídè. Bákan náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì máa ní ìṣòro àti ìpèníjà, ó sì lè jẹ́ irú èyí tí wọn kò ronú kàn! Arákùnrin Jackson fi kún un pé, “Àmọ́, ẹ retí pé Jèhófà máa ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè bójú tó ìṣòro kọ̀ọ̀kan.”

Ìkẹta, Arákùnrin Jackson rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí ohun tó wà nínú ẹsẹ 20 àti 21 pé, “ẹ lè retí ìtọ́sọ́nà, nítorí náà, ẹ wá ìtọ́sọ́nà!” Ó sọ pé, lónìí, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ní láti fetí sílẹ̀ dáadáa bí Jèhófà ṣe ń tipasẹ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì bá wọn sọ̀rọ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ náà fi ọ̀yàyà rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, nítorí ìyẹn ló máa mú kí wọ́n ní ìyè.

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rùbojo Jèhófà . . . Wà Lára Yín”

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé ìtumọ̀ gbólóhùn náà “ìbẹ̀rùbojo Jèhófà,” gbólóhùn yìí wá látinú Ìwé Mímọ́. (2 Kíróníkà 19:7) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí kò túmọ̀ sí ìbẹ̀rù tó ń mú kéèyàn ní ìpayà, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìfẹ́ àtọkànwá láti ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn ọ̀wọ̀ tó ń mú kéèyàn ní ìbẹ̀rù tó jinlẹ̀. Arákùnrin Morris gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé, “Irú ìbẹ̀rù yìí ni kẹ́ ẹ máa ní lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì yín.” Báwo ni wọ́n ṣe lè máa ní irú ìbẹ̀rù yìí fún Jèhófà? Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ ọ̀nà méjì tí wọ́n lè gbà ṣe é.

Ọ̀nà àkọ́kọ́, Arákùnrin Morris rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Jákọ́bù 1:19 sílò, ó ní: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” Ó sọ pé, òótọ́ ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ní oṣù márùn-ún tí wọ́n fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ wọ́n ní láti kíyè sára kó máa lọ di pé wọ́n á máa fi ohun tí wọ́n kọ́ ṣe fọ́rífọ́rí lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Ó sọ pé, “Ẹ ní láti kọ́kọ́ fetí sílẹ̀. Ẹ fetí sí àwọn èèyàn tó wà nínú ìjọ tí wọ́n bá yàn yín sí àtàwọn tó ń mú ipò iwájú ní ilẹ̀ náà, ẹ fetí sí ohun tí wọ́n bá sọ nípa orílẹ̀-èdè náà àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀. Ẹ má ṣe lọ́ra láti sọ pé, ‘Ohun kan kò yé yín.’ Tó bá jẹ́ pé ẹ rí ẹ̀kọ́ kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí lóòótọ́, ẹ óò wá rí i pé bí ẹ ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ ṣì ní láti mọ̀.”

Ọ̀nà kejì, Arákùnrin Morris ka ìwé Òwe 27:21 pé: “Ìkòkò ìyọ́hunmọ́ wà fún fàdákà, ìléru sì wà fún wúrà; ẹnì kọ̀ọ̀kan sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyìn rẹ̀.” Ó ṣàlàyé pé, bí ó ṣe di dandan pé ká yọ́ ìdọ̀tí tó wà lára wúrà àti fàdákà kúrò kí wọ́n lè dára gan-an, bákan náà, ìgbóríyìn lè túbọ̀ mú kéèyàn ṣe dáadáa. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìgbóríyìn lè dán irú ẹni téèyàn jẹ́ wò. Ó lè mú kéèyàn gbéra ga tí èèyàn á sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ojú rere Jèhófà, tàbí kẹ̀, ó lè mú kéèyàn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àṣeyọrí téèyàn ṣe, kéèyàn sì pinnu láti túbọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Arákùnrin Morris tipa báyìí rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, bí àwọn èèyàn bá gbóríyìn fún wọn, kí wọ́n fojú tó tọ́ wò ó, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn ní ‘ìbẹ̀rù tó tọ́ fún Jèhófà.’

“Ẹ Fọwọ́ Pàtàkì Mú Iṣẹ́ Yín”

Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sọ lájorí ọ̀rọ̀ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkòrí tó wà lókè yìí, ó sọ pé ọ̀rọ̀ náà, “míṣọ́nnárì” túmọ̀ sí “ẹni tí a rán níṣẹ́.” Ó ní, abájọ tó fi jẹ́ pé onírúurú míṣọ́nnárì ló wà, tí wọ́n máa ń lọ ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló jẹ́ pé, ọ̀ràn ìlera ló jẹ wọ́n lógún, ọ̀pọ̀ àwọn míì sì rèé, bí wọ́n ṣe máa fi ọ̀ràn ìṣèlú yanjú ìṣòro ayé ni wọ́n gbájú mọ́. Ó sọ pé, “Àmọ́ ọ̀ràn tiyín yàtọ̀.” Lọ́nà wo?

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nínú Bíbélì nípa ìwòsàn ara. Nígbà tí Jésù jí ọmọbìnrin kan dìde, àwọn òbí rẹ̀ “kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” (Máàkù 5:42) Bákan náà, nígbà tí Jésù wo àwọn afọ́jú sàn lọ́nà ìyanu, ayọ̀ wọn pọ̀ jọjọ. Ọ̀kan lára ìdí fún àwọn ìṣẹ́ ìyanu yẹn ni pé, kí àwa èèyàn òde òní lè mọ ohun tí Kristi máa ṣe nínu ayé tuntun tó ń bọ̀, ìyẹn ìgbà tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn olódodo tí wọ́n máa la òpin ayé burúkú ìsinsìnyí já máa rí ìwòsàn kúrò lọ́wọ́ gbogbo àìlera. (Ìṣípayá 7:9, 14) Bákan náà, wọ́n máa kí àwọn èèyàn wọn tó jíǹde káàbọ̀, kò sì ní sí àìlera kankan lára àwọn tó jíǹde náà. Wo bí ayọ̀ náà yóò ti pọ̀ tó!

Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Arákùnrin Pierce ti ṣàlàyé, ìwòsàn ti ara kọ́ ló ṣe pàtàkì jù lọ. Àwọn aláìsàn tí Jésù wò sàn tún ṣàìsàn nígbà tó yá. Àwọn òkú tí Jésù jí dìde tún pa dà kú. Ojú àwọn afọ́jú tí Jésù là pàápàá tún pa dà fọ́, ìyẹn nígbà tí wọ́n kú. Àmọ́ ìwòsàn tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ìwòsàn tẹ̀mí tí Jésù ṣe, ìyẹn bó ṣe kọ́ àwọn èèyàn láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bákan náà, iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ni pé kí wọ́n ṣe ìwòsàn tẹ̀mí fún àwọn èèyàn. Wọ́n á sọ àwọn èèyàn di ọ̀rẹ́ Bàbá wa ọ̀run kì wọ́n lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn tó rí ìwòsàn tẹ̀mí gbà nìkan ló máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Arákùnrin Pierce sọ pé, “Ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ìwòsàn tẹ̀mí jẹ́ ohun tó ń fi ìyìn fún Ọlọ́run. Ìyẹn ló máa túmọ̀ sí pé ẹ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù yín.”

Kókó Pàtàkì Mẹ́ta Míì Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Náà

“Ǹjẹ́ Ọjọ́ Òní Máa Dára?” Arákùnrin Robert Rains tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló dáhùn ìbéèrè tó bá àkókò mu yìí. Ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kí wọ́n rí i dájú pé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn jẹ́ ọjọ́ tó dára nípa lílo àkókò wọn lọ́nà rere, kí wọ́n jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí wọn nígbà tí wọ́n bá ní ìṣòro, kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà, kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e.

“Ṣé Wàá Fi Tuntun Rọ́pò ti Láéláé?” Arákùnrin Mark Noumair tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló béèrè ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ tó sọ. Ó jíròrò ohun tó wa ní 1 Jòhánù 2:7, 8, níbi tí àpọ́sítélì Jòhánù ti mẹ́nu kan “àṣẹ ti láéláé” tó tún jẹ́ “àṣẹ tuntun.” Àwọn àṣẹ méjèèjì kò yàtọ̀ sí ara wọn, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn láìsí ìmọtara ẹni nìkan, pé kí wọ́n ṣe tán láti kú nítorí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Jòhánù 13:34, 35) Ìdí tí àṣẹ yìí fi jẹ́ àṣẹ láéláé ni pé, ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Kristi fúnra rẹ̀ ti pàṣẹ náà fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ìdí tí àṣẹ yìí tún fi jẹ́ àṣẹ tuntun ní pé, àwọn Kristẹni ń ní àwọn ìṣòro tuntun, nítorí náà, wọ́n ní láti túbọ̀ fi ìfẹ́ hàn lọ́nà tuntun, ìyẹn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bákan náà, àwọn míṣọ́nnárì máa ní ìṣòro tuntun, wọ́n sì ní láti fi ìfẹ́ hàn láwọn ọ̀nà tuntun. Kí ló lè mú kí èyí ṣeé ṣe?

Arákùnrin Noumair gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé, “Má ṣe ṣe ohun tíwọ fúnra rẹ kórìíra.” Ó sọ pé, táwọn èèyàn bá ń ṣe ohun tí a kò fẹ́, àmọ́ tí àwa náà bá wá ń ṣe nǹkan náà, á jẹ́ pé a ṣe ohun tí àwa fúnra wa kórìíra nìyẹn. Ńṣe ló máa dà bí ìgbà téèyàn ń gbẹ́ sàréè ara rẹ̀. Àmọ́, tá a bá wá àwọn ọ̀nà tuntun láti fi bójú tó irú àwọn ìṣòro yìí, a ó máa tan “ìmọ́lẹ̀ tòótọ́,” a ó sì lé òkùnkùn tẹ̀mí lọ.

“Fi Òṣùká ru ẹrù náà.” Arákùnrin Michael Burnett tóun náà jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló sọ̀rọ̀ lórí àkòrí yìí. Ó sọ nípa àwọn èèyàn ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n máa ń fi orí ru ẹrù tó wúwo. Wọ́n máa ń lo òṣùká, tó máa jẹ́ kó rọrùn láti ru ẹrù náà, kò sì ní jẹ́ kí ẹrù náà yẹ̀ dà nù, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n lè máa rìn láìsí ìyọnu. Bákan náà, àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì máa ní ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ tí wọ́n máa rù níbi tí wọ́n yàn wọ́n sí nílẹ̀ òkèèrè, àmọ́ a ti fún wọn ní ohun kan tó dà bí òṣùká, ìyẹn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó kún rẹ́rẹ́ látinú Bíbélì. Bí wọ́n ṣe ń fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò, iṣẹ́ wọn á rọrùn láti ṣe, wọ́n á sì lè ṣàṣeyọrí.

Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń jáde lọ wàásù pẹ̀lú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí wọn, nítorí pé ara ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn lèyí jẹ́. Arákùnrin William Samuelson, tó jẹ́ alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run, sọ díẹ̀ lára ìrírí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní, ó lo àkòrí náà, “Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Sinmi.” (Oníwàásù 11:6) Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣefihàn tó gbádùn mọ́ni nípa iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n wá àkókò láti wàásù ìhìn rere nínú ọkọ̀ òfúrufú, ilé oúnjẹ àti ní ilé epo. Wọ́n wàásù láti ilé dé ilé, lákòókò tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ àti nípasẹ̀ lẹ́tà. Ó dájú pé wọn kò jẹ́ kí ọwọ́ wọn sinmi, àbájáde rẹ̀ sì dára gan-an ni.

Arákùnrin Kenneth Stovall tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń bójú tó ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ti ní ìrírí tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àwọn ni, Arákùnrin Barry Hill, tó sìn ní orílẹ̀-èdè Ecuador àti Dominican Republic, Arákùnrin Eddie Mobley tó wà lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire àti Arákùnrin Tab Honsberger tó sìn ní orílẹ̀-èdè Senegal, Benin àti Haiti. Gbogbo wọn ló sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà, “Dán Jèhófà Wò Kí O sì Rí Ìbùkún Gbà.” (Málákì 3:10) Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Hill sọ nípa bí òun àti ìyàwó òun ṣe dojú kọ ìṣòro ojú ọjọ́ orílẹ̀-èdè Ecuador tó máa ń yí pa dà láti gbígbóná àti eléruku sí èyí tó gbóná tí ó sì ṣú. Ó sọ pé ọdún méjì ààbọ̀ gbáko ni àwọn fi fi korobá pọn omi wẹ̀. Àmọ́, wọn kò sọ pé àwọn máa kúrò níbi tí wọ́n yàn wọ́n sí. Wọ́n gbà pé ìbùkún Jèhófà ni ibi tí wọ́n yan àwọn sí yìí. Ó sọ pé, “Iṣẹ́ yìí la fẹ́ fi ìgbésí ayé wa ṣe.”

Ní ìparí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ka lẹ́tà ìdúpẹ́ tó wọni lọ́kàn tí kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà kọ, nítorí ilé ẹ̀kọ́ náà. Wọ́n sọ nínú lẹ́tà náà pé, “Ìgbàgbọ́ wa ti lágbára gan-an, àmọ́ a ṣì ní láti máa tẹ̀síwájú.” Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn, wọ́n sì yàn wọ́n sí oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè. Arákùnrin Jackson parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nípa fífi dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú pé kí wọ́n máa retí àtìlẹ́yìn Jèhófà lọ́jọ́ iwájú, pàápàá nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àwọn ìṣòrò. Gbogbo àwọn tó wá lọ́jọ́ náà ló pa dà lọ pẹ̀lú ìdùnnú tí wọ́n sì ń retí ohun rere lọ́jọ́ iwájú. Láìsí àní-àní, Jèhófà yóò lo àwọn míṣọ́nnárì tuntun yìí láti gbé iṣẹ́ rere ṣe.

[Àtẹ ìsọfúnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 31]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

9 iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá

34.0 ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn

18.6 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti ṣèrìbọmi

13.1 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú ìṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

A rán kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nísàlẹ̀ yìí

IBI TÍ A RÁN ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ LỌ

AJẸNTÍNÀ

ÀMÉNÍÀ

BURKINA FASO

BÙRÚŃDÌ

KÓŃGÒ (KINSHASA)

CZECH REPUBLIC

HAITI

HONG KONG

INDONESIA

KẸ́ŃYÀ

LITHUANIA

MALAYSIA

MÒSÁŃBÍÌKÌ

NEPAL

PAPUA NEW GUINEA

ROMANIA

SENEGAL

TANZANIA

UGANDA

SÌǸBÁBÚWÈ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíláàsì Àádóje Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

A to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì lọ sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Molina, Z.; Bassolino, S.; Alatsis, C.; Arroyo, A.; Niño, L.; Merkling, S.; Clark, M.

(2) Little, C.; Tibaudo, S.; Jakobsson, S.; Moreno, J.; Rodriguez, A.; Lee, K.; Cárdenas, H.; Aguilar, L.

(3) Clairbush, A.; Polley, A.; Caldwell, S.; Adame, J.; Hildebrandt, S.; Shoemaker, I.; Grohman, N.; Galvez, G.

(4) Clark, J.; Bassolino, A.; Packham, K.; Adame, J.; Knaus, M.; Niño, M.; Moreno, R.; Galvez, J.

(5) Rodriguez, D.; Geynes, M.; Molina, J.; Aguilar, A.; Alatsis, I.; Manno, A.; Grohman, R.; Packham, J.

(6) Geynes, S.; Cárdenas, M.; Arroyo, C.; Manno, C.; Merkling, J.; Lee, H.; Clairbush, X.; Jakobsson, P.

(7) Little, J.; Hildebrandt, B.; Shoemaker, M.; Knaus, K.; Caldwell, J.; Tibaudo, F.; Polley, C.