Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsọtẹ́lẹ̀ 5. Pípa Ilẹ̀ Ayé Run

Àsọtẹ́lẹ̀ 5. Pípa Ilẹ̀ Ayé Run

Àsọtẹ́lẹ̀ 5. Pípa Ilẹ̀ Ayé Run

“[Ọlọ́run yóò] run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—ÌṢÍPAYÁ 11:18.

● Ẹmu ni ọ̀gbẹ́ni Pirri máa ń dá, abúlé kan tó ń jẹ́ Kpor ló ń gbé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Iṣẹ́ tó ń ṣe bà jẹ́ nígbà tí epo rẹpẹtẹ dà sórí ilẹ̀ ní agbègbè Niger Delta. Ọ̀gbẹ́ni yìí sọ pé, “Ó pa àwọn ẹja wa, ó ba awọ ara wa jẹ́, ó sì ba àwọn odò wa jẹ́. Mi ò ní iṣẹ́ tí mo lè fi gbọ́ bùkátà ara mi mọ́.”

KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé, òbítíbitì pàǹtí tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ tọ́ọ̀nù ló ń wọnú àwọn òkun ayé yìí lọ́dọọdún. Wọ́n sọ pé ìdajì àwọn pàǹtí náà ló jẹ́ ike, tí omi á máa gbé kiri fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí wọ́n tó pòórá. Yàtọ̀ sí bíba ayé jẹ́, àwọn èèyàn tún ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ayé ní ìlòkulò lọ́nà tó bani lẹ́rù. Ìwádìí fi hàn pé, ilẹ̀ ayé nílò ọdún kan àtoṣù márùn-ún láti ṣe ìmúbọ̀sípò ohun àmúṣọrọ̀ tí aráyé lò lọ́dún kan ṣoṣo. Ìwé ìròyìn Sydney Morning Herald, láti ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Bí iye èèyàn bá ń pọ̀ sí i bó ṣe ń pọ̀ sí i yìí, tí àwọn èèyàn sì ń lo ohun àmúṣọrọ̀ ayé bí wọ́n ṣe ń lò ó yìí, a máa nílò ayé méjì míì tó bá máa fi di ọdún 2035.”

ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Ẹ̀dá tó ní làákàyè ni èèyàn. A lè wá ojútùú sí àwọn ìṣòro yìí, kí á sì gba ayé lọ́wọ́ ewu.

ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Ọ̀pọ̀ èèyàn, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti ní ẹgbẹẹgbẹ́ ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa tún àyíká ṣe. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ṣì ń ba ayé jẹ́ lọ́nà tó bùáyà.

KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ ìdí kankan wà tó fi yẹ kí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà, kó sì gba ayé wa lọ́wọ́ àwọn tó ń pa á run, gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí?

Yàtọ̀ sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì márùn-ún tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, Bíbélì tún sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó ń mọ́kàn yọ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò nínú àsọtẹ́lẹ̀ kẹfà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

“Ńṣe ló dà bíi pé mo kúrò nínú Párádísè tí mo sì wá ń gbénú ìdọ̀tí olóró.”​—ERIN TAMBER, TÓ Ń GBÉ NÍ ÈTÍKUN GULF, LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ, NÍPA ÀBÁJÁDE EPO TÓ DÀ SÓRÍ ILẸ̀ LỌ́DÚN 2010 NÍ GULF OF MEXICO.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Ṣé Ọlọ́run Ló Fà Á?

Nígbà tó jẹ́ pé Bíbélì ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan búburú tí à ń rí lónìí, ṣé ìyẹn wá fi hàn pé Ọlọ́run ló fà á? Ṣé Ọlọ́run ló fà á tí a fi ń jìyà? Wàá rí ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè yìí ní orí 11 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

U.S. Coast Guard photo