Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsọtẹ́lẹ̀ 2. Ìyàn

Àsọtẹ́lẹ̀ 2. Ìyàn

Àsọtẹ́lẹ̀ 2. Ìyàn

“Àìtó oúnjẹ yóò wà.”—MÁÀKÙ 13:8.

● Ní orílẹ̀-èdè Niger, ọkùnrin kan kúrò ní abúlé rẹ̀ lọ sí abúlé kan tó ń jẹ́ Quaratadji, kó bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ìyàn. Àwọn àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin lóbìnrin àtàwọn ẹbí rẹ̀ náà ti ṣí kúrò ní abúlé tó jìnnà réré káwọn náà lè bọ́ lọ́wọ́ ìyàn. Síbẹ̀, ọkùnrin náà sùn sórí ẹní lóun nìkan. Kí nìdí tó fi wà níbẹ̀ lóun nìkan? Ọ̀gbẹ́ni Sidi tó jẹ́ baálẹ̀ abúlé náà sọ pé, “Ìdí ni pé, kò lè bọ́ ìdílé rẹ̀, kò sì fẹ́ máa wò wọ́n lójú ló ṣe kúrò lọ́dọ̀ wọn.”

KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Kárí ayé, èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹyọ kan nínú méje ni kì í rí oúnjẹ tí ó tó jẹ lójoojúmọ́. Iye yìí tún wá pabanbarì ní gúúsù aṣálẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà, níbi tí wọ́n ti sọ pé èèyàn kan nínú mẹ́ta kò ní oúnjẹ tí wọ́n lè jẹ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Kí ohun tí à ń sọ lè túbọ̀ yé wa, ẹ fojú inú wo ìdílé kan tó ni bàbá, ìyá àti ọmọ kan. Tó bá jẹ́ pé oúnjẹ ẹni méjì ni wọ́n ní, ta ni kò ní jẹun? Ṣé bàbá ni tàbí ìyá àbí ọmọ? Ojoojúmọ́ làwọn ìdílé tó wà nírú ipò yẹn ní láti ṣe irú ìpinnu yìí.

ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Oúnjẹ tí ilẹ̀ ayé ń mú jáde pọ̀ ju èyí tí gbogbo èèyàn ayé lè jẹ lọ. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé, kí àwọn tó ń bójú tó ohun tí ilẹ̀ ayé ń mú jáde bójú tó o dáadáa.

ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Òótọ́ ni pé, àwọn àgbẹ̀ lè pèsè oúnjẹ tó pọ̀ kí wọ́n sì gbé wọn wá sínú ìlú lákòókò yìí ju tí ìgbàkígbà rí lọ. Kò sì sí àní-àní pé, ó yẹ kí ìjọba fi oúnjẹ tí ilẹ̀ ayé ń mú jáde yanjú ìṣòro ebi. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ìsapá tí wọ́n ti ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún láti yanjú ìṣòro náà, pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.

KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ohun tó wà nínú ìwé Máàkù 13:8 ló ń ṣẹ? Pẹ̀lú bí ìtẹ̀síwájú ṣe bá ìmọ̀ ẹ̀rọ, ṣé ebi kì í pa àwọn èèyàn kárí ayé?

Àwọn ìṣòro kan máa ń wáyé lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ àti ìyàn, ó sì jẹ́ apá mìíràn lára àwọn àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“Iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára àwọn ọmọdé tí òtútù àyà, ìgbẹ́ ọ̀rìn àtàwọn àìsàn míì ń pa ni kò bá máà kú ká ní wọ́n jẹunre kánú.”​—ANN M. VENEMAN, TÓ FÌGBÀ KAN RÍ JẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ OWÓ TÍ ÀJỌ ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ YÀ SỌ́TỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌMỌDÉ.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]

© Paul Lowe/Panos Pictures