Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ipò Òṣì Túmọ̀ Sí Pé Inú Ọlọ́run Ò Dùn sí Wa?

Ṣé Ipò Òṣì Túmọ̀ Sí Pé Inú Ọlọ́run Ò Dùn sí Wa?

Ṣé Ipò Òṣì Túmọ̀ Sí Pé Inú Ọlọ́run Ò Dùn sí Wa?

ỌLỌ́RUN sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ́ òtòṣì láàárín [yín].” Ìdí ni pé nínú Òfin tó fún wọn, ètò wà fún bí wọ́n á ṣe máa tọ́jú àwọn òtòṣì, kódà ètò wà fún bí wọ́n á ṣe máa gbójú fo gbèsè tí wọ́n bá jẹ ara wọn. (Diutarónómì 15:1-4, 7-10) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kò yẹ kí òtòṣì kankan wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí Jèhófà ti ṣèlérí láti bù kún wọn. Ìgbà tí wọ́n bá pa Òfin Jèhófà mọ́ ni wọ́n tó máa rí ìbùkún yẹn gbà, àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ láti ṣègbọràn.

Èyí ò wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ṣojú rere sáwọn tí nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún ju àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló jẹ́ òtòṣì. Wòlíì Ámósì jẹ́ òtòṣì, ó máa ń sin ẹran, ó sì tún máa ń ṣe alágbàṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Ámósì 1:1; 7:14) Nígbà ayé wòlíì Èlíjà, ìyàn kan mú lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, Èlíjà sì ní láti gbára lé òtòṣì opó kan tó jẹ́ ọ̀làwọ́ kó tó lè jẹun, Ọlọ́rùn rí sí i pé ìwọ̀nba ìyẹ̀fun àti òróró díẹ̀ tí opó yẹn ní kò tán títí ìyàn náà fi kásẹ̀ nílẹ̀. Kò sí èyí tó dolówó nínú Èlíjà àti opó yẹn, àmọ́ Jèhófà pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún wọn.—1 Àwọn Ọba 17:8-16.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ téèyàn ò retí lè sọni di òtòṣì lọ́sàn kan òru kan. Jàǹbá àti àìsàn lè máà jẹ́ kéèyàn lè ṣiṣẹ́ fáwọn àkókò kan tàbí títí láé. Ikú sì lè sọ àwọn kan di ọmọ aláìlóbìí àti opó ọ̀sán gangan. Kódà, irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò bára dé yìí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti kẹ̀yìn sí ẹnì kan. Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Náómì àti Rúùtù wọni lọ́kàn gan-an, ó sì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn òtòṣì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Náómì àti Rúùtù di òtòṣì paraku torí ikú ọkọ wọn, Jèhófà Ọlọ́run bù kún wọn, ó sì ṣètò bí wọ́n á ṣe máa rí ohun tí wọ́n nílò.—Rúùtù 1:1-6; 2:2-12; 4:13-17.

Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ipò òṣì ò túmọ̀ sí pé inú Ọlọ́run ò dùn sí wa. Àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run lè nígbẹkẹ̀lé nínú ọ̀rọ̀ Dáfídì Ọba tó sọ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.”—Sáàmù 37:25.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Náómì àti Rúùtù jẹ́ òtòṣì, Ọlọ́run bù kún wọn ó sì fìfẹ́ bójú tó wọn