Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣó yẹ kí Pọ́ńtù Pílátù bẹ̀rù Késárì?

Àwọn aṣáájú àwọn Júù dúnkookò mọ́ Pọ́ńtù Pílátù tó jẹ́ Gómìnà Róòmù kó bàa lè ní kí wọ́n lọ pa Jésù, wọ́n sọ fún un pé: “Bí ìwọ bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì.” (Jòhánù 19:12) Tìbéríù ni Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù tí ẹsẹ Bíbélì yìí pè ní “Késárì.” Ṣó yẹ kí Pílátù bẹ̀rù Késárì yìí?

Irú èèyàn wo ni Tìbéríù tó jẹ́ Késárì yìí? Ìwé The New Encyclopædia Britannica sọ pé ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó gbẹ́jọ́ Jésù ni Tìbéríù ti di “ẹni tó máa ń fẹ́ ṣe tinú ẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kì í sì í kọ ohun tó lè tìdí ẹ̀ yọ.” Torí pé ó máa ń fura sáwọn èèyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ìyà àjẹkúdórógbó ló máa fi ń jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ti fura sí pé ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀. Ìwé yẹn tún sọ síwájú sí i pé “tó bá jẹ́ òótọ́ lọ̀rọ̀ àwọn òpìtàn tó gbé ayé lákòókò tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sígbà ayé Tìbéríù, a jẹ́ pé àwọn eré ìdárayá tó ní ín ṣe pẹ̀lú ìwà òǹrorò àtàwọn nǹkan tó ń kóni nírìíra ni Tìbéríù fẹ́ràn jù lọ. Kò sí bí wọ́n ṣe lè ṣàlàyé ẹjọ́ tàbí kí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ fún un tó, ẹni tó bá wù ú kó pa ló máa ń kì mọ́lẹ̀ nígbàkigbà tó bá wù ú.”

Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú ẹni tí Tìbéríù jẹ́ yìí ló mú kí ẹ̀rù ba Pílátù nígbà táwọn aṣáájú àwọn Júù dúnkookò mọ́ ọn, tó fi pinnu pé kí wọ́n lọ pa Jésù.—Jòhánù 19:13-16.

Kí nìdí tí Jésù fi fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?

Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ ló ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹsẹ̀ lásán ni wọ́n máa fi ń rìn kiri. Sálúbàtà làwọn tó ń wọ bàtà sábà máa ń wọ̀ nígbà yẹn, ìyẹn ò sì ju pé kí wọ́n fi okùn so ìtẹ́lẹ̀ bàtà wọn mọ́ àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọrùn ẹsẹ̀ lọ. Ẹsẹ̀ àwọn èèyàn ò lè ṣe kó má dọ̀tí torí pé àwọn ọ̀nà eléruku àtàwọn pápá tó ní ẹrọ̀fọ̀ ló ṣeé ṣe kí wọ́n máa gbà kọjá.

Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àṣà wọn ni láti máa kọ́kọ́ bọ́ bàtà kí wọ́n tó wọlé. Wọ́n sì tún máa ń fọ ẹsẹ̀ àwọn àlejò wọn kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn láájò àlejò. Àwọn onílé tàbí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ló sábà máa ń fọ ẹsẹ̀ àwọn àlejò. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ló sọ̀rọ̀ nípa àṣà yìí. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù sọ fáwọn àlejò tó wá sínú àgọ́ rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí a bu omi díẹ̀, jọ̀wọ́, kí a sì wẹ ẹsẹ̀ yín. Lẹ́yìn náà kí ẹ rọ̀gbọ̀kú lábẹ́ àwọn igi. Ẹ sì jẹ́ kí n wá búrẹ́dì díẹ̀, kí n sì tu ọkàn-àyà yín lára.”—Jẹ́nẹ́sísì 18:4, 5; 24:32; 1 Sámúẹ́lì 25:41; Lúùkù 7:37, 38, 44.

Gbogbo ìtàn yìí jẹ́ ká mọ ìdí tí Jésù fi wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà ayẹyẹ Ìrékọjá tó ṣe gbẹ̀yìn pẹ̀lú wọn. Lákòókò tá à ń wí yìí, kò sí onílé tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ tó máa wẹ ẹsẹ̀ wọn, ó sì ṣe kedere pé kò sẹ́ni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ àwọn yòókù nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Nípa fífọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Jésù tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.—Jòhánù 13:5-17.