Yorùbá
Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
/assets/ct/fa815d8e9f/images/syn_placeholder_sqr.png
w08 3/1 ojú ìwé 17
Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó pé o wà níbi tí ohun tó ò ń kà náà ti ṣẹlẹ̀, kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Kó o sì máa fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tó kópa pàtàkì nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 19:1-14.

Bó o ṣe ń finú yàwòrán àwọn àlejò Lọ́ọ̀tì, sọ bí wọ́n ṣe rí.

․․․․․

Àwọn wo ló wà nínú àwọn ewèlè èèyàn yẹn?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 13:7-13.

Báwo ni Lọ́ọ̀tì ṣe dẹni tó ń gbé ní ìlú Sódómù?

․․․․․

Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé òun yóò pa àwọn tó ń gbé ìlú náà run?

․․․․․

KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 19:15-26.

Báwo ni Jèhófà ṣe gba ti Lọ́ọ̀tì rò?

․․․․․

Kí ló mú kí aya Lọ́ọ̀tì bojú wẹ̀yìn?

․․․․․

Kí ló ṣekú pa aya Lọ́ọ̀tì?

․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà ibi.

․․․․․

Bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú.

․․․․․

Bí Jèhófà ṣe kọ́kọ́ máa ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ kó tó ṣèdájọ́ wọn.

․․․․․

Apá wo ló gbàfiyèsí rẹ jù lọ nínú ìtàn yìí, kí sì nìdí?

․․․․․

․․․․․