Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

Báwo la ṣe lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù?

Ká ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ọkàn wa. Dípò tí a ó fi máa fura sí ẹnì kan, ńṣe ló yẹ ká ronú nípa ohun tó fà á tá a fi ní èrò tí kò tọ́ nípa rẹ̀. Ṣé kì í ṣe torí káwọn èèyàn lè túbọ̀ máa kíyè sí àṣeyọrí wa la ṣe ń ṣe àríwísí rẹ̀? Ká má ṣe gbàgbé pé tá a bá ń ṣe àríwísí ẹnì kan ńṣe ló máa mú kí nǹkan túbọ̀ burú sí i.—8/15, ojú ìwé 21.

Báwo ni òfin Mósè ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin?

Láyé àtijọ́, àwọn obìnrin Ísírẹ́lì lómìnira gan-an ni, wọ́n sì láǹfààní láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n máa ń bọlá fún wọn, wọ́n sì máa ń fọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n. Wọn ò sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n.—9/1, ojú ìwé 5 sí 7.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo là ń retí bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé?

Ìkéde “Àlááfíà àti ààbò!” Àwọn orílẹ̀-èdè á kọ lu Bábílónì Ńlá, wọ́n á sì pa á run. Wọ́n á kọ lu àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Lẹ́yìn náà, a ó ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.—9/15, ojú ìwé 4.

Àǹfààní wo ló wà nínú bí a kò ṣe mọ ìgbà tí òpin máa dé?

Bí a kò ṣe mọ ìgbà tí òpin máa dé ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Ó fún wa ní àǹfààní láti mú inú Ọlọ́run dùn. Ó ń jẹ́ ká lè máa gbé ìgbé ayé onífara-ẹni-rúbọ. Ó ń jẹ́ ká gbára lé Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pátápátá. Bákan náà, ó ń jẹ́ kí àwọn àdánwò tí à ń dojú kọ nísinsìnyí yọ́ wa mọ́.—9/15, ojú ìwé 24 sí 25.

Báwo la ṣe lè fi ohun tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:19 ran ẹnì kan tó gbà gbọ́ nínú ọ̀rún àpáàdì lọ́wọ́?

Ẹsẹ yẹn sọ pé nígbà tí Ádámù bá kú, ó máa pa dà sínú ilẹ̀, kò sọ pé ọ̀run àpáàdì ló máa lọ.—10/1, ojú ìwé 13.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Ìṣípayá 1:16, 20, àwọn wo ni “ìràwọ̀ méje” tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jésù dúró fún?

Àwọn ìràwọ̀ méje náà dúró fún àwọn alábòójútó tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró nínú ìjọ. Ní àfikún sí ìyẹn wọ́n tún dúró fún gbogbo àwọn alábòójútó nínú ìjọ.—10/15, ojú ìwé 14.

Kí ni tọkọtaya kan lè ṣe tí wọ́n bá jẹ gbèsè?

Ó yẹ kí àwọn méjèèjì wá àsìkò kan tí wọ́n máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ nípa gbèsè wọn. Kí wọ́n sọ̀rọ̀ lórí ètò ìnáwó ìdílé wọn. Ṣé wọ́n lè wá bí owó tó ń wọlé fún wọn ṣe máa pọ̀ sí i tàbí kí wọ́n dín ìnáwó wọn kù? Wọ́n gbọ́dọ̀ pinnu bí wọ́n ṣe máa yanjú gbèsè tí wọ́n jẹ, bóyá kí wọ́n lọ bá àwọn tí wọ́n jẹ ní gbèsè, kí wọ́n sì jọ tún àdéhùn ṣe nípa bí wọ́n ṣe máa san gbèsè náà. Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí níní owó lọ́wọ́ tàbí àìní owó lọ́wọ́ gbà wọ́n lọ́kàn. (1 Tím. 6:8)—11/1, ojú ìwé 19 sí 21.

Báwo ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn látàrí ohun tó wà nínú Aísáyà 50:4, 5?

Àwọn ẹsẹ yẹn sọ pé àwọn tó ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́” kò ní “yí padà sí òdì kejì.” Jésù fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn, ó sì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí Baba rẹ̀ kọ́ ọ. Ó máa ń wù ú nígbà gbogbo láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, ó fara balẹ̀ kíyè sí bí Jèhófà ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àánú hàn sí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀.—11/15, ojú ìwé 11.

Báwo ni sítáǹbù ìrántí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Estonia ṣe fẹ̀rí hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa ìwà títọ́ wọn mọ́?

Lọdún 2007 ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ti ilẹ̀ Estonia ṣe sítáǹbù kan ní ìrántí àwọn tó fara gbá ìpẹ̀yàrun tó wáyé lábẹ́ ìjọba Stalin ní ilẹ̀ Estonia. Lára àwọn nọ́ńbà tó wà lára sítáǹbù náà ni 382, èyí sì ni iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ọmọ wọn tí wọ́n fipá kó lọ sí àgọ́ ìfìyàjẹni lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, lọ́dún 1951.—12/1, ojú ìwé 27 sí 28.