Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Ti Ṣẹlẹ̀ Àmọ Ẹ Fi Ṣàríkọ́gbọ́n”

“Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Ti Ṣẹlẹ̀ Àmọ Ẹ Fi Ṣàríkọ́gbọ́n”

Ní June 14, 2007, ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ti ilẹ̀ Estonia, ìyẹn Estonian National Post Office, ṣe sítáǹbù tí wọ́n ń lẹ̀ mọ́ àpò ìwé, tí àwòrán rẹ̀ wà ní apá ọ̀tún yìí. Nígbà tí wọ́n máa gbé e jáde wọ́n ṣe ìkéde kan pé: “A ṣe sítáǹbù yìí jáde ní ìrántí àwọn tí wọ́n hùwà ìkà sí nígbà ìpẹ̀yàrun tó wáyé lábẹ́ ìjọba Stalin ní ilẹ̀ Estonia.” Ó ṣẹlẹ̀ pé láàárín ọdún 1941 sí 1951, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ilẹ̀ Estonia ni ìjọba fipá kó lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ ibòmíì.

NÍ ILẸ̀ Estonia, wọ́n sábà máa ń lo àkànlò èdè kan pé “ìtàn kì í purọ́.” Wọ́n máa ń lò ó láti fi sọ pé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, àmọ́ kéèyàn fi ṣàríkọ́gbọ́n. Àwọn èèyàn ilẹ̀ ibòmíì náà sì ní àkànlò èdè tí wọ́n ń lò bẹ́ẹ̀. Òótọ́ sì ni o, pé kò sí ohun tá a lè ṣe nípa nǹkan tó bá ti ṣẹlẹ̀ kọjá, àmọ́ a lè kọ́ ẹ̀kọ́ látinú rẹ̀. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba ní Ísírẹ́lì àtijọ́ sọ pé: “Gbogbo nkan wọnyìí ni mo rí, mo si fiyè si iṣẹ́ gbogbo ti a nṣe labẹ òòrùn: ìgbà kan nbẹ, ninu èyí ti ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ìfarapa rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nílẹ̀ Estonia àti ní àwọn apá ibòmíì ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù, tó jẹ́rìí sí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ní ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí. Ìjọba èèyàn fìyà jẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nígbà tí wọ́n fipá kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ kan tó jìnnà réré kí wọ́n lọ máa gbé ibẹ̀, wọ́n sì kó àwọn míì lọ sìnrú nínú àwọn àgọ́ tí wọ́n ti ń fàwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó níbẹ̀.

Àwọn òpìtàn ní ilẹ̀ Estonia sọ pé àwọn ará ìlú tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn láti orílẹ̀-èdè kékeré yìí ju ọ̀kẹ́ méjì àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [46,000] lọ láàárín ọdún 1941 sí 1951. Èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló jẹ́ pé tìtorí ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n wà ni wọ́n ṣe kó wọn lọ, àwọn kan sì wà tó jẹ́ pé torí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá tàbí ipò wọn láwùjọ ni wọ́n ṣe kó wọn. Àmọ́ ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n kó lọ, tìtorí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe ni wọ́n ṣe kó wọn.

Wọ́n Gbógun Ti Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Aigi Rahi-Tamm sọ nínú ìwé kan tí ilé ìtẹ̀wé Tartu University Press tẹ̀ jáde ní ọdún 2004 pé: “Láàárín ọdún 1948 sí 1951, wọ́n mú méjìléláàádọ́rin [72] lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn tí wọ́n mọ̀ mọ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ṣètò bí wọ́n ṣe máa kó àwọn Ẹlẹ́rìí púpọ̀ sí i lọ sí ìgbèkùn. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ ní òru April 1, 1951. Kì í ṣe àwọn Ìpínlẹ̀ Baltic nìkan ni wọ́n ti wá kó àwọn èèyàn, wọ́n tún kó láti Moldova, apá ìwọ̀ oòrùn Ukraine àti Belorussia pàápàá.”

Ṣáájú ọdún 1951 ni wọ́n ti máa ń mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Estonia, tí wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ wọn, tí àwọn aláṣẹ máa ń wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu wọn, tí wọ́n sì máa ń ju àwọn míì sẹ́wọ̀n lára wọn. Àmọ́ ìdí tí wọ́n fi wá bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sí ìgbèkùn lọ́tẹ̀ yìí ni pé wọ́n kúkú fẹ́ pa ẹ̀sìn náà rẹ́ ráúráú ní ilẹ̀ Estonia.

Ẹ kíyè sí i pé wọ́n kọ April 1, 1951 sí ara sítáǹbù tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Ẹ ó tún rí i pé wọ́n kọ 382 sí ara rẹ̀. Nọ́ńbà yìí ń tọ́ka sí iye àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn ọmọ wọn tí ìjọba kó lọ sí ìgbèkùn láti orílẹ̀-èdè náà lọ́jọ́ yẹn. Àwọn mọ̀lẹ́bí àti aládùúgbò àwọn Ẹlẹ́rìí yìí wà lára àwọn wọ̀nyí. Lọ́jọ́ náà, ìjọba kọ́kọ́ mú gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ kó lọ sí ìgbèkùn ní orílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà tó di alẹ́, wọ́n wá rọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n mú, àtọmọdé àti àgbà, pọ̀ sínú ibi tí wọ́n máa ń kó àwọn ẹranko sí nínú ọkọ̀ rélùwéè, wọ́n sì wà wọ́n lọ sí ilẹ̀ Siberia.

Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ella Toom * jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà yẹn, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu rẹ̀, ó ní: “Ọ̀kan nínú àwọn sójà tó wà níbẹ̀ halẹ̀ mọ́ mi, ó ní kí n jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe. Ó tiẹ̀ bi mí pé: ‘Ṣé o fẹ́ràn ẹ̀mí ẹ? Àbí o fẹ́ kí àtìwọ àti Ọlọ́run rẹ jọ lọ kú pọ̀ sínú oko ní ilẹ̀ Siberia?’” Àmọ́ Ella ń fi ìgboyà wàásù ìhìn rere nìṣó. Torí náà, wọ́n mú un nígbèkùn lọ sí ilẹ̀ Siberia, ó sì tó ọdún mẹ́fà tí wọ́n fi ń gbé e láti àgọ́ kan sí òmíràn níbi tí wọ́n ti ń fàwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó.

Obìnrin Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Hiisi Lember wà lára ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn tí wọ́n ṣàdédé kó lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ Estonia láìtiẹ̀ dúró gbẹ́jọ́. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní April 1, 1951, ó ní: “Ṣe ni wọ́n kàn wá lóru, tí wọ́n ń sọ pé: ‘Àfira! Ẹ palẹ̀ ẹrù yín mọ́ láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú!’” Òru yẹn ni wọ́n mú Hiisi àti ọmọ rẹ̀ obìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà lọ sí ibùdókọ̀ rélùwéè. Inú ọkọ̀ rélùwéè tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ ni wọ́n kó wọn sí, ọkọ̀ náà wá ń lọ láti ibùdókọ̀ kan sí òmíràn, ó ń kó àwọn Ẹlẹ́rìí míì. Hiisi sọ pé: “Ibi tí wọ́n máa ń kó ẹranko sí nínú ọkọ̀ rélùwéè ni wọ́n kó wa sí. Ọpẹ́lọpẹ́ pé àwọn ìgbẹ́ ẹran tó wà nínú ibẹ̀ ti dì gbagidi torí yìnyín; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ì bá ṣòro gan-an fún wa láti dúró sórí wọn. Ṣe ni wọ́n kàn rọ́ wa pọ̀ sínú ibẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n kó ẹranko.”

Ìrìn àjò burúkú náà gba ọ̀sẹ̀ méjì, ojú wọn sì rí màbo. Èrò ti pọ̀ jù làwọn ibi tí wọ́n kó wọn sí nínú ọkọ̀ rélùwéè náà, ó tún wá lẹ́gbin. Gbogbo ọ̀nà ni wọ́n gbà fi ayé sú àti ọmọdé àti àgbàlagbà wọn, wọ́n sì wọ́ wọn nílẹ̀. Àwọn kan lára wọn sunkún títí, wọn kò sì jẹun. Àmọ́ ṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ń kọrin ìyìn sí Ọlọ́run láti fi gba ara wọn níyànjú, wọ́n sì fi ń gbé ara wọn ró, wọ́n tún jọ ń pín oúnjẹ tí wọ́n bá ní. Ní kúkúrú, wọ́n kó wọn lọ sí ibì kan tí wọ́n máa “tẹ̀ dó sí,” wọ́n wá sọ fún wọn pé “àrèmábọ̀” ni ibẹ̀ fún wọn.

Hiisi rántí ìtìlẹyìn tó dùn mọ́ni tó rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ará lásìkò làásìgbò náà. Ó ní: “Ìgbà kan wà tí ọkọ̀ wa dúró ní ibùdókọ̀ kan, a sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ rélùwéè kan tó ń bọ̀ láti ilẹ̀ Moldova. Látinú ibi tí a wà, a gbọ́ tí ọkùnrin kan ní ìta béèrè bá a ṣe jẹ́ àti ibi tí à ń lọ. A sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, ilẹ̀ Estonia ni a ti ń bọ̀, àmọ́ a kò mọ ibi tí wọ́n ń kó wa lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí míì tí wọ́n wà nínú ọkọ̀ rélùwéè tó ń bọ̀ láti Moldova fetí kọ́ ohun tí a sọ. Wọ́n sì ju búrẹ́dì ńlá kan àti àwọn èso gbígbẹ gba ojú àyè kan tó wà lára ọkọ̀ rélùwéè sí wa. Ìgbà yẹn la rí i pé kì í ṣe ọ̀dọ̀ wa nìkan ni wọ́n ti kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé gbogbo ilẹ̀ Soviet Union ni ọ̀rọ̀ náà dé!”

Ó ju ọdún mẹ́fà tí àwọn ọmọbìnrin méjì kan tí wọn kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, ìyẹn Corinna àti àbúrò rẹ̀ Ene, kò fi rí ìyá wọn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni màmá wọn, ṣáájú àkókò náà ni wọ́n ti mú un, tí wọ́n sì gbé e lọ sí àgọ́ tí wọ́n ti ń fàwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n wá ń kó àwọn èèyàn lóṣù April yẹn, wọ́n fipá kó ọmọbìnrin méjèèjì yìí ní ilé wọn, wọ́n sì taari wọn sínú ọkọ̀ rélùwéè. Arábìnrin Corinna sọ pé àwọn dúpẹ́ pé, “nínú ọkọ̀ náà, obìnrin Ẹlẹ́rìí kan tó ní ọmọ méjì fà wá mọ́ra, pé ká fọkàn balẹ̀, pé a ó máa gbé pẹ̀lú òun àti àwọn ọmọ òun.”

Ilẹ̀ oníyìnyín tí òtútù ibẹ̀ yọyẹ́ ni Siberia. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n dé aginjù olótùútù tí wọ́n kó wọn lọ yìí? Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n dé bẹ̀ wọ́n dà wọ́n síta bí ẹrú, kí àwọn tó dáko sí àgbègbè ibẹ̀ wá máa ṣà wọ́n bí wọ́n ṣe fẹ́, kí wọ́n sì kó wọn lọ máa ṣiṣẹ́ oko. Arábìnrin Corinna rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà, ó ní: “A ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn jiyàn lórí wa pé: ‘Ṣebí o ti rí ẹni táá máa bá ẹ wa katakata. Èmi ni máa mú eléyìí.’ Àwọn míì sì ń sọ pé: ‘Arúgbó méjì ló ti wà nínú àwọn témi mú o. Ìwọ náà gbọ́dọ̀ mú àwọn arúgbó kan.’”

Ọmọbìnrin méjèèjì yìí, Corinna àti Ene àbúrò rẹ̀, nígboyà gan-an. Nígbà tó yá wọ́n sọ pé: “Àárò màmá wa sọ wá gan-an ni, ṣe ló máa ń ṣe wá bíi pé ká rí i, kó tún gbà wa mọ́ra bó ṣe máa ń ṣe!” Síbẹ̀ náà, ṣe ni ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà dúró sán-ún, wọn kò sì jẹ́ kí ipò tí wọ́n wà ba ayọ̀ wọn jẹ́. Corinna sọ pé: “Lọ́nà kan ṣá, mo lè sọ pé ó tiẹ̀ dáa bí màmá wa kò ṣe sí lọ́dọ̀ wa, torí pé ìgbà míì wà tó jẹ́ pé inú òtútù ilẹ̀ oníyìnyín tó burú jáì la ti máa ń ṣiṣẹ́ ní ìta gbangba, láìrí aṣọ tó nípọn wọ̀ láti fi gba òtútù.”

Ní tòdodo, aráyé ti fojú àwọn ẹni ẹlẹ́ni tí kò ṣẹ̀ rárá gbolẹ̀ gan-an ní ilẹ̀ Estonia àti ní àwọn ibòmíì. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì wà lára irú àwọn aláìṣẹ̀ bẹ́ẹ̀. (Wo àpótí náà “Ìwà Ìkà Tó Kọjá Àfẹnusọ.”) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà kan rí, wọ́n hu irú ìwà ìkà yìí sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ Estonia, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣì ń fi ìtara bá ìjọsìn wọn nìṣó, wọ́n sì jẹ́ aláyọ̀.

Ọjọ́ Ọ̀la Aláyọ̀ Dé Tán!

Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra àìṣèdájọ́ òdodo. Ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, gbogbo aláìṣèdájọ́ òdodo, jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 25:16) Lóòótọ́, ìwà ibi tó ti ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí pọ̀, Ọlọ́run sì ń rí i, àmọ́ ó máa tó fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ibi pátápátá. Ìwé Sáàmù sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

Ó dájú pé ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ dé tán! Bí a kò tiẹ̀ lè yí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá pa dà, a lè ṣe ohun tó máa mú kí a lè rí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. Nítorí náà, sún mọ́ Ọlọ́run kí o lè wà lára àwọn tó máa gbádùn ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ níbi tí òdodo ti máa gbilẹ̀.—Aísáyà 11:9.

^ Ìtàn ìgbésí ayé Ella Toom wà nínú ìwé ìròyìn Jí! April 2006, ojú ìwé 20 sí 24 [Gẹ̀ẹ́sì].