Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ní Ilẹ̀ Mẹ́síkò Ń Ran Àwọn Ará Ṣáínà Lọ́wọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ní Ilẹ̀ Mẹ́síkò Ń Ran Àwọn Ará Ṣáínà Lọ́wọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ní Ilẹ̀ Mẹ́síkò Ń Ran Àwọn Ará Ṣáínà Lọ́wọ́

“ỌKÙNRIN mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) Lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì yìí ń ṣẹ níbi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” di aṣọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí mú kí wọ́n lè máa sin Jèhófà Ọlọ́run. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀nà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí gbà ń ṣẹ. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ lára wọn fi ń kọ́ èdè mìíràn kí wọ́n lè túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tó ń lọ lọ́wọ́ jákèjádò ayé.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò náà ń sapá gidigidi láti kọ́ èdè míì. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] èèyàn tó ń sọ èdè Ṣáínà ló ń gbé nílẹ̀ Mẹ́síkò. Lọ́dún 2003, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára wọn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe nílùú Mexico City. Èyí jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Mẹ́síkò rí i pé ó ṣeé ṣe ká rí lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà tó máa di Ẹlẹ́rìí lọ́jọ́ iwájú. Kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí láti wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Ṣáínà, wọ́n ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù mẹ́ta láti kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ará Mẹ́síkò ní bí wọ́n á ṣe máa fi èdè Mandarin tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Ṣáínà gbọ́rọ̀ kalẹ̀ ní ṣókí. Àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni wọ́n kọ́ ní èdè náà. Èèyàn pàtàkì kan láwùjọ àwọn tó ń sọ èdè Mandarin nílùú Mexico City wá síbi ayẹyẹ tí wọ́n ṣe nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà parí. Èyí fi hàn pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ti ṣe ìrànlọ́wọ́ gan-an fáwọn tó ń sọ èdè Ṣáínà. Ilé ẹ̀kọ́ àwọn ará Ṣáínà kan nílẹ̀ Mẹ́síkò fún mẹ́ta lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, wọ́n ní kí wọ́n lọ kẹ́kọ̀ọ́ sí i lókè òkun kí èdè Ṣáínà tí wọ́n kọ́ lè túbọ̀ dán mọ́rán.

Lára ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ni pé kí wọ́n lọ máa fi ohun tí wọ́n kọ́ dánra wò. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kọ́ bí wọ́n á ṣe sọ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan lédè Ṣáínà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí fi wàásù láwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ nílùú Mexico City. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́kànlélógún làwọn akẹ́kọ̀ọ́ onítara náà bẹ̀rẹ̀. Ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? lédè Ṣáínà tí wọ́n fi lẹ́tà tó jọ ABD, èyí tí wọ́n ń pè ní Pinyin, kọ wúlò fún wọn gan-an.

Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ èdè Ṣáínà ṣe ń báwọn èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè náà wàásù, gbogbo ohun tí wọ́n lè sọ ò ju, “Qing Du [Jọ̀wọ́ ka ibí yìí]” wọ́n á tọ́ka sí ìpínrọ̀ kan, lẹ́yìn náà wọ́n á tọ́ka sí ìbéèrè tó wà níbẹ̀. Bí onítọ̀hún bá ti kà á tán tó sì ti fi èdè Ṣáínà dáhùn ìbéèrè, wọ́n á sọ pé, “Shei shei [O ṣeun]” tàbí “Hen Hao [O ṣé gan-an].”

Obìnrin Ẹlẹ́rìí kan bẹ̀rẹ̀ irú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú obìnrin kan tó ní Kristẹni lòun. Nígbà tó ti di ẹ̀ẹ̀kẹta tó ti ń kọ́ obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́, ó wò ó pé bóyá lohun tí òun ń kọ́ obìnrin náà yé e. Ìyẹn ló mú kí Ẹlẹ́rìí náà mú arákùnrin ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí arákùnrin ọ̀hún béèrè bóyá obìnrin náà ní ìbéèrè èyíkéyìí, ìbéèrè tí obìnrin náà bi í ni pé: “Ṣé ó pọn dandan kí n jẹ́ òmùwẹ̀ kí n tó lè ṣèrìbọmi?”

Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n dá Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan sílẹ̀. Àwọn mẹ́sàn-án tí wọ́n ń sọ èdè Ṣáínà àtàwọn Ẹlẹ́rìí ọmọ ilẹ̀ Mẹ́síkò mẹ́tàlélógún ló ń wá síbẹ̀ déédéé. Dókítà kan tó jẹ́ ará Ṣáínà wà lára àwọn tó ń wá. Ó ti gba àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kan lédè Spanish lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìtọ́jú. Àmọ́ torí pé kò lè ka èdè Spanish, ó ní kí ẹnì kan bá òun túmọ̀ ìlà mélòó kan nínú rẹ̀. Nígbà tó wá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa Bíbélì làwọn ìwé náà ń sọ, ó ní kí ẹni tó fún òun níwèé ìròyìn náà bá òun wá ti èdè Ṣáínà, ìyẹn sì ṣe bẹ́ẹ̀. Síwájú sí i, nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Mẹ́síkò gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n ṣètò pé kí Ẹlẹ́rìí kan tó ń sọ èdè Ṣáínà lọ sọ́dọ̀ dókítà náà. Ìyá dókítà yìí tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ṣáínà ní Bíbélì, dókítà náà sì máa ń kà á dáadáa nígbà tó wà nílé. Nígbà tó sọ pé òun fẹ́ lọ sí Mẹ́síkò, ìyá rẹ̀ rọ̀ ọ́ pé kó má ṣe dáwọ́ Bíbélì kíkà dúró. Àṣé ó tiẹ̀ ti ń gbàdúrà pé kí ẹnì kan wá ran òun lọ́wọ́ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tayọ̀tayọ̀ ni dókítà náà fi sọ pé: “Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà mi!”

Àwọn mìíràn tó tún ń wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ náà ni ìdílé kan tí gbogbo wọn jẹ́ ará Ṣáínà. Ilé obìnrin ọmọ Mẹ́síkò kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n ń gbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé táátààtá làwọn ará Ṣáínà yìí gbọ́ nínú èdè Spanish, síbẹ̀ wọ́n máa ń wà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀hún. Nígbà tó yá, ìdílé náà bi Ẹlẹ́rìí tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bóyá ó ní ìwé èyíkéyìí lédè àwọn. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè Ṣáínà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ìdílé yìí sọ pé àwọn á fẹ́ máa wàásù fáwọn ọmọ ìlú àwọn, àwọn sì fẹ́ ya ìgbésí ayé àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà.

Ká sòótọ́, èdè Ṣáínà kò rọrùn láti kọ́. Àmọ́, àwọn ìrírí wọ̀nyí jẹ́ ká rí i pé ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti láwọn ibòmíràn lágbàáyé, Jèhófà ń ran àwọn èèyàn látinú onírúurú èdè, títí kan èdè Ṣáínà, lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó fẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn tó ń kọ́ èdè Ṣáínà nílùú Mexico City

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ẹlẹ́rìí ará Mẹ́síkò kan ń fi èdè Ṣáínà kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi èdè Ṣáínà wàásù láti ilé dé ilé nílùú Mexico City