Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

AYÉ DOJÚ RÚ

2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ

2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kìràkìtà torí àtijẹ àtimu lójoojúmọ́, ṣe nìyẹn sì túbọ̀ ń nira torí bí nǹkan ṣe ń dojú rú láyé yìí. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?

  • Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ níbì kan tàbí tí nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí, àwọn nǹkan á gbówó lórí, irú bí owó ilé àti owó oúnjẹ.

  • Tí nǹkan bá dojú rú nílùú, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tàbí kí owó tó ń wọlé fún wọn dín kù.

  • Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó lè ba ohun ìní àwọn èèyàn jẹ́, kíyẹn sì sọ wọ́n di òtòṣì.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

  • Tó o bá mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, ìyẹn ò ní jẹ́ kí nǹkan nira jù fún ẹ nígbà ìṣòro.

  • Fi sọ́kàn pé nǹkan lè yí pa dà nígbàkigbà. Owó tàbí ohun ìní rẹ lè má níyì mọ́ tó bá dọ̀la.

  • Tẹ́nì kan bá lówó, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa láyọ̀ tàbí pé ìdílé ẹ̀ máa wà níṣọ̀kan.

Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí

Bíbélì sọ pé: “Tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.”​—1 Tímótì 6:8.

Tó o bá ní ìtẹ́lọ́rùn, o ò ní máa wá àwọn nǹkan tó kàn wù ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ á máa dùn ọkàn ẹ á sì balẹ̀ tó o bá ti rí àwọn ohun pàtàkì tó o nílò. Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an tí nǹkan bá yí pa dà fún ẹ.

Kó o lè ní ìtẹ́lọ́rùn, o máa ní láti ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì kan. Bí àpẹẹrẹ, á dáa kó o máa ṣọ́wó ná, kó o má sì ṣe ju agbára ẹ lọ. Torí tó o bá ń ná ju iye tó ń wọlé fún ẹ, ìyẹn lè mú kí nǹkan nira.