Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 1 2022

Bí nǹkan ṣe ń burú sí i láyé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jìyà nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá tàbí àwọn àjálù táwọn èèyàn ń fọwọ́ ara wọn fà. Ka ìwé yìí kó o lè rí bó o ṣe lè máa fara dà á àtohun tó o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ àtàwọn ẹlòmíì.

 

Ayé Dojú Rú—Kí Lọ̀nà Àbáyọ?

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, tètè ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o lè dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ.

1 | Tọ́jú Ara Rẹ

Tó o bá ń tọ́jú ara ẹ dáadáa, ó máa rọrùn fún ẹ láti fara dà á tí ìṣòro bá dé.

2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ

To o ba mo beeyan se n sowo na, iyen o ni je ki nnkan nira ju fun e nigba isoro.

3 | Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Tẹbítọ̀rẹ́ Dáa Sí I

Tó o bá ka ìwé yìí, wàá mọ ohun tó o lè ṣe kí àjọṣe ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ lè dáa sí i, wàá tún rí ohun tó lè ṣe kí àárín ìwọ àti tẹbítọ̀rẹ́ má bàa dà rú.

4 | Gbà Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro wa, ó sì lè jẹ́ ká ní ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Ka ìwé yìí kó o lè rí ohun tí ìwọ àti ìdílé ẹ lè ṣe láti fara dà á bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń dojú rú sí i láyé yìí.