Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Rẹ?

Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Rẹ?

Tó o bá ń gbàdúrà, ṣé o rò pé Ọlọ́run ń tẹ́tí sí ẹ lóòótọ́?

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

  • Ọlọ́run ń fetí sílẹ̀. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́. . . . Ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.”​—Sáàmù 145:18, 19.

  • Ọlọ́run fẹ́ kó o máa gbàdúrà sí òun. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.”​—Fílípì 4:6.

  • Ọlọ́run ń bójú tó ẹ lóòótọ́. Ọlọ́run mọ àwọn ìṣòro àti àníyàn rẹ, ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”​—1 Pétérù 5:7.