Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Mọ Àwọn Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe

Gbogbo wa la kì í ráyè tó pọ̀ tó láti dá kẹ́kọ̀ọ́. Báwo la ṣe lè lo àkókò tá a ní lọ́nà tó dáa jù lọ? Ohun àkọ́kọ́ ni pé, má ṣe kánjú. Wàá jàǹfààní gan-an tó bá jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ lo kà, tó o sì ṣàṣàrò nípa ẹ̀ dípò kó o kàn sáré ka ibi tó pọ̀ láì jàǹfààní.

Lẹ́yìn náà, ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó o máa ṣe lẹ́sẹẹsẹ. (Éfé. 5:15, 16) Wo àwọn àbá yìí:

  • Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Sm. 1:2) Á dáa kó o bẹ̀rẹ̀ látorí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tá a máa ń kà nípàdé àárín ọ̀sẹ̀.

  • Múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ sílẹ̀. Múra sílẹ̀ dáadáa kó o lè dáhùn nípàdé.​—Sm. 22:22.

  • Jọ̀wọ́, tún sapá láti máa ka àwọn ìwé ìròyìn wa tó wà fún gbogbo èèyàn àtàwọn ìwé míì tó ń jáde lórí ìkànnì jw.org, kó o sì tún máa wo àwọn fídíò wa.

  • Ṣèwádìí nípa ẹ̀kọ́ kan tó wù ẹ́. O lè ṣèwádìí nípa ìṣòro kan tó o ní, ìbéèrè kan tó ò ń wá ìdáhùn ẹ̀ tàbí ẹ̀kọ́ kan nínú Bíbélì tó o fẹ́ kó túbọ̀ yé ẹ. Kó o lè mọ ohun tó o tún lè ṣe, lọ sí abala “Eré Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” lórí ìkànnì jw.org.