Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìgbéyàwó

Ìgbéyàwó

Ṣé àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ lásán ni ìgbéyàwó?

“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:6.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Lójú Ọlọ́run, ìgbéyàwó kì í kan ṣe àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ lásán. Àjọṣe mímọ́ láàárín ọkùnrin àti obìnrin ló jẹ́. Bíbélì sọ pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá ‘[Ọlọ́run] dá wọn ní akọ àti abo. Ní tìtorí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’ . . . Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” aMáàkù 10:6-9; Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

Gbólóhùn náà, “ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀,” kò túmọ̀ sí pé ọ̀run la ti ń so tọkọtaya pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bó ṣe tọ́ka sí Ẹlẹ́dàá wa pé òun ni Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú àjọṣe náà. Àwọn tọkọtaya tó bá gbà pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ yìí, máa ń wo ìgbéyàwó wọn gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ àti àjọṣe tó gbọ́dọ̀ wà pẹ́ títí, èyí sì máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ fẹ́ láti rí i pé ohunkóhun kò ba ìgbéyàwó àwọn jẹ́. Ó tún máa rọrùn fún wọn láti ṣàṣeyọrí tí ọkọ àti ìyàwó bá ń jẹ́ kí Bíbélì tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n lè bójú tó ojúṣe tí kálukú wọ́n ní.

Kí ni ojúṣe ọkùnrin?

“Ọkọ ni orí aya rẹ̀.”—Éfésù 5:23.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kí gbogbo nǹkan lè máa lọ dáadáa nínú ìdílé, ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà tá a máa pinnu bí nǹkan á ṣe máa lọ. Bíbélì sọ pé ọkọ ni Ọlọ́run gbé iṣẹ́ yẹn lé lọ́wọ́. Àmọ́, ìyẹn kò sọ ọ di apàṣẹwàá tàbí abúmọ́ni. Kò sì gbọ́dọ̀ yẹ ojúṣe rẹ̀ sílẹ̀ tí ìyàwó rẹ̀ kò fi ní lè bọ̀wọ̀ fún un, táá sì mú kí iṣẹ́ wọ aya rẹ̀ lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run retí pé kó ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó aya rẹ̀, kó máa fọ̀wọ̀ wọ̀ ọ́ torí òun ló sún mọ́ ọn jù lọ, kí wọ́n sì fọkàn tán ara wọn. (1 Tímótì 5:8; 1 Pétérù 3:7) Ìwé Éfésù 5:28 sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.”

Ọkọ tó bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ dénú máa ń mọyì àwọn nǹkan tí ìyàwó ẹ̀ mọ̀ ọ́n ṣe, á máa gba tiẹ̀ rò pàápàá lórí àwọn ọ̀ràn tó bá kan ìdílé wọn. Kò gbọ́dọ̀ sọ pé ohun tóun bá ṣáà ti sọ labẹ gé torí pé òun ni olórí ìdílé. Nígbà tí Ábúráhámù, tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò gba ìmọ̀ràn rere tí ìyàwó rẹ̀ fún un nípa ohun tó yẹ kó ṣe nínú ìdílé wọn, Jèhófà Ọlọ́run sọ fún un pé: “Fetí sí ohùn rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 21:9-12) Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni Ábúráhámù fi ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ, èyí sì mú kí ìdílé rẹ̀ ní àlááfíà kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan, Ọlọ́run sì bù kún wọn.

Kí ni ojúṣe obìnrin?

“Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín.” —1 Pétérù 3:1.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kí Ọlọ́run tó dá ìyàwó fún ọkùnrin àkọ́kọ́, ó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Àṣekún ni nǹkan tó bá ń mú kí nǹkan pé tàbí kó péye. Nítorí náà, Ọlọ́run kò dá obìnrin kó lè dà bí ọkùnrin tàbí kó máa bá a díje, àmọ́ ó dá a láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn méjèèjì á sì lè ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láti bí ọmọ bíi tiwọn, kí wọ́n sì fi wọ́n kún ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Kí obìnrin lè ṣe ojúṣe rẹ̀, Ọlọ́run fun un ní ara, ọpọlọ àti èrò tó yẹ. Tó bá fi ọgbọ́n àti ìfẹ́ lo àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún un yìí, ó máa jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ̀ lè wà pẹ́ títí, ó sì máa jẹ́ kí ọkàn ọkọ rẹ̀ balẹ̀, inú rẹ̀ á sì máa dùn. Ọlọ́run sọ pé ó yẹ ká yin irú obìnrin àtàtà bẹ́ẹ̀. bÒwe 31:28, 31.

a Bíbélì fàyè gba tọkọtaya láti kọ ara wọn sílẹ̀ tí ọ̀kan nínú wọn bá lọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì.—Mátíù 19:9.

b Àwọn tọkọtaya máa rí àwọn àbá tó gbéṣẹ́ nípa ìgbéyàwó àti ìdílé ní apá tá a pè ní “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé” tó máa ń jáde nínú ìwé ìròyìn Jí!