Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì

Ìwé ìròyìn kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé àwọn ọmọ “tí wọ́n ní àwọn àìsàn tó yẹ kí àwọn oníṣègùn ti rí nínú oyún” kò ní lè máa pe àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn lẹ́jọ́ mọ́. Àmọ́ àwọn òbí wọn lè pe àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn lẹ́jọ́ kí wọ́n lè gba owó ìtanràn torí “owó gọbọí tí wọ́n ń ná láti tọ́jú àwọn ọmọ náà jálẹ̀ ayé wọn.”

Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà

Ní Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, tọkọtaya mẹ́jọ nínú mẹ́wàá ló ti máa ń gbé pa pọ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó.

Orílẹ̀-èdè Gíríìsì

Ìwádìí tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìlera Ilẹ̀ Gíríìsì ṣe fi hàn pé láàárín oṣù márùn-ún àkọ́kọ́ lọ́dún 2011, iye àwọn tó fọwọ́ ara wọn pa ara wọn pọ̀ ju ti oṣù márùn-ún àkọ́kọ́ lọ́dún 2010 lọ. Èyí bọ́ sí ìgbà tí ètò ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà.

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Àjọ tó ń bójú tó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé nǹkan bí ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá oúnjẹ ni wọ́n fi ń ṣòfò lórílẹ̀-èdè náà. Wọ́n fojú bù ú pé ìdá méje nínú ọgọ́rùn-ún [100] ọ̀gbìn oko ló ń bàjẹ́ sóko torí pé wọn kì í kórè rẹ̀. Ìdá mẹ́tàdínlógún [17] nínú ọgọ́rùn-ún oúnjẹ tí wọ́n ń sè nílé oúnjẹ ló ń ṣòfò. Àti pé ìdá kan nínú mẹ́rin oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ ìdílé bá rà ni wọ́n ń kó dànù.

Orílẹ̀-èdè Madagásíkà

A gbọ́ pé wọ́n ti ṣàwárí ọ̀gà tó kéré jù lágbàáyé ní ilẹ̀ Madagásíkà. Ẹranko yìí kéré jọjọ. Kódà, kò tiẹ̀ gùn tó ọmọ ìka wa tó kéré jù. Àwọn kan lára irú ọ̀gà yìí kéré débi pé wọ́n lè dúró sórí èékánná orí ìka èèyàn. Àmọ́ torí pé àwọn èèyàn ti ń ba ibi tí wọ́n ń gbé jẹ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹranko yìí di àwátì.