Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Àwọn Aláìní

Àwọn Aláìní

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn aláìní tiẹ̀ jẹ Ọlọ́run lógún?

“Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó . . . Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’”—Hébérù 13:5.

BÍ ỌLỌ́RUN ṢE FI HÀN PÉ Ọ̀RỌ̀ WỌN JẸ ÒUN LÓGÚN

Nígbà tí nǹkan bá le koko fún ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, oríṣiríṣi ọ̀nà ni Ọlọ́run máa ń gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ òun lógún. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni bó ṣe máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. * Ìwé Jákọ́bù 1:27 sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.”

Àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni máa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìyàn ńlá máa mú ní ilẹ̀ Jùdíà, àwọn Kristẹni tó wà ní ilẹ̀ Síríà ti Áńtíókù pinnu “láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:28-30) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní rí àwọn nǹkan tí wọ́n nílò gbà. Ìwà ọ̀làwọ́ táwọn Kristẹni yìí ní fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn.—1 Jòhánù 3:18.

Téèyàn bá jẹ́ aláìní, kí ló lè ṣe láti ran ara rẹ̀ lọ́wọ́?

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—Aísáyà 48:17, 18.

ỌLỌ́RUN Ń RÀN WÁ LỌ́WỌ́ KÍ AYÉ WA LÈ DÁA

Àìmọye èèyàn ló ti rí i pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì wúlò fún wa gan-an, kò sì láfiwé. Òwe 2:6, 7 sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá. Òun yóò sì to ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣánṣán.” Àwọn tó bá wá ọgbọ́n yìí rí, tí wọ́n sì fi sílò máa ń ṣe ara wọn láǹfààní gan-an.

Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í ná ìnákúnàá, wọn kì í sì í dá àṣàkaṣà, irú bíi lílo oògùn olóró tàbí mímu ọtí àmujù. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Wọ́n tún jẹ́ olóòótọ́, ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó sì ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa. Ìyẹn ń jẹ́ kí wọ́n lè ríṣẹ́, kí àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ sì lè máa fojú iyì wò wọ́n. Ìwé Éfésù 4:28 sọ pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, . . . kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.”

Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè ran àwọn aláìní lọ́wọ́?

“A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”—Mátíù 11:19.

ÀWỌN Ẹ̀RÍ TÍ KÒ ṢEÉ JÁ NÍ KORO

Wọ́n gba ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Wilson sí iṣẹ́ fúngbà díẹ̀ lórílẹ̀-èdè Gánà. Iṣẹ́ náà kò sì ní pẹ́ parí. Ní ọjọ́ tí Wilson máa lò kẹ́yìn níbi iṣẹ́ náà, ó rí owó lẹ́yìn ọkọ̀ ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ náà nígbà tó ń fọ ọkọ̀ náà. Ọ̀gá rẹ̀ kékeré sọ fún un pé kó lọ gbé owó tó rí yẹn pa mọ́. Àmọ́ Wilson kọ̀ láti jí owó náà torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Ó dá owó náà pa dà fún ọ̀gá rẹ̀ àgbà. Dípò kí wọ́n dá Wilson dúró níbi iṣẹ́ náà, ṣe ni wọ́n sọ fún un pé kó máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ, wọ́n sì wá sọ ọ́ di ọ̀gá nídìí iṣẹ́ rẹ̀.

Ní ilẹ̀ Yúróòpù, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Géraldine torí pé ẹni tó gbà á síṣẹ́ kò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ìyá ọ̀gá Géraldine sọ fún ọmọ rẹ̀ pé àṣìṣe ló ṣe bó ṣe dá Géraldine dúró lẹ́nu iṣẹ́. Ó ní: “Tó o bá ń wá òṣìṣẹ́ tó máa fi òótọ́ inú ṣiṣẹ́ fún ẹ, tí kò ní fi iṣẹ́ rẹ̀ ṣeré, kò sí ẹlòmíì tó o lè gbà síṣẹ́ tó máa dà bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ọ̀gá Géraldine wá lọ ṣèwádìí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì gba Géraldine pa dà síṣẹ́.

Ní orílẹ̀-èdè South Africa, obìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah nìkan ló ń dá tọ́mọ. Nígbà tó ní ìṣòro, Sarah rí bí àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó nígbà tí àwọn ará ìjọ rẹ̀ fún òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ ní oúnjẹ, tí wọ́n sì tún fi ọkọ̀ gbé wọn. Àwọn ọmọ rẹ̀ sọ pé: “Àwọn òbí tá a ní nínú ìjọ pọ̀.”

Àwọn àpẹẹrẹ bí èyí tá a mẹ́nu kàn yìí pọ̀ gan-an. Ó rán wa létí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 1:33, tó sọ pé: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò.” Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí!

^ ìpínrọ̀ 5 Láwọn ìlú kan, ìjọba máa ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Àmọ́ níbi tí kò bá ti sí irú ètò yìí, ojúṣe àwọn mọ̀lẹ́bí ẹni tó jẹ́ aláìní yẹn ni pé kí wọ́n ràn án lọ́wọ́.—1 Tímótì 5:3, 4, 16.