Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
Kí Ni Kò Tọ̀nà Nínú Àwòrán Yìí?
Tọ́ka sí ohun mẹ́ta nínú àwòrán yìí tó yàtọ̀ sí ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 7:1-9, 13-16, 23; 8:15-19.
1. ․․․․․
2. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Wo Léfítíkù 11:3 àti Diutarónómì 14:4.
3. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Wo Diutarónómì 14: 7-19.
FÚN ÌJÍRÒRÒ: Báwo làwọn ọmọ Nóà àtàwọn ìyàwó wọn ṣe ràn án lọ́wọ́? Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Nóà?
Nínú Ìtẹ̀jáde Yìí
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
OJÚ ÌWÉ 6 Kí lẹni tó fẹ́ràn owó ò ní ní? Oníwàásù 5:․․․
OJÚ ÌWÉ 9 Àwọn wo ló máa láyọ̀? Mátíù 5:․․․
OJÚ ÌWÉ 18 Kí ni kò yẹ kéèyàn ṣe bó bá ń gbàdúrà? Mátíù 6:․․․
OJÚ ÌWÉ 28 Kí ló yẹ ká ṣe nípa àwọn àníyàn wa? 1 Pétérù 5:․․․
Àwọn Wo Ló Wà Lára Ìdílé Jésù?
Kọ́kọ́ wo ohun tá a kọ sínú amọ̀nà. Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí. Lẹ́yìn náà, kọ orúkọ tó tọ̀nà sínú àlàfo.
4. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpẹẹrẹ burúkú ni bàbá mi fi lélẹ̀, síbẹ̀ mo jẹ́ ọba tó ń “bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà.”
5. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Mo ṣi agbára mi lò nípa títa ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀ ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi.
Ka 2 Àwọn Ọba 21:16.
6. ․․․․․
AMỌ̀NÀ: Mo tẹ̀ lé àpẹẹrẹ burúkú tí bàbá mi fi lélẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ mi sì pa mí.
ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ
1. Ọkọ̀ áàkì ò ní irú iwájú àti ẹ̀yìn tí ọkọ̀ ojú omi máa ń ní.
2. Nóà mú méje nínú àwọn ẹranko tí ó “mọ́,” irú bí àgùntàn, sínú áàkì.
3. Nóà mú onírúurú ẹranko tí “kò mọ́” ní méjì-méjì sínú ọkọ̀ áàkì.
4. Hesekáyà.—Mátíù 1:9.
5. Mánásè.—Mátíù 1:10.
6. Ámọ́nì.—Mátíù 1:10.