Jẹ́nẹ́sísì 7:1-24

  • Wọ́n ń wọ inú áàkì (1-10)

  • Ìkún Omi tó bo ayé (11-24)

7  Jèhófà wá sọ fún Nóà pé: “Wọ inú áàkì, ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, torí ìwọ ni mo rí pé ó jẹ́ olódodo níwájú mi nínú ìran yìí.+  Kí o mú gbogbo onírúurú ẹran tó mọ́ ní méje-méje,*+ ní akọ àti abo; mú méjì-méjì péré nínú gbogbo ẹran tí kò mọ́, ní akọ àti abo;  kí o sì mú àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run ní méje-méje,* ní akọ àti abo, kí ọmọ wọn má bàa pa run ní gbogbo ayé.+  Torí ní ọjọ́ méje òní, èmi yóò rọ òjò+ sórí ayé fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru,+ màá sì run gbogbo ohun alààyè tí mo dá kúrò lórí ilẹ̀.”+  Nóà sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kó ṣe.  Ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún ni Nóà nígbà tí ìkún omi bo ayé.+  Nóà, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ sì wọnú áàkì kí ìkún omi+ náà tó bẹ̀rẹ̀.  Àwọn kan lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti gbogbo ẹran tí kò mọ́, lára àwọn ẹ̀dá tó ń fò àti gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀,+  wọ́n wọnú áàkì lọ bá Nóà ní méjì-méjì, ní akọ àti abo, bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún Nóà. 10  Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ìkún omi bo ayé. 11  Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, ní ọdún tí Nóà pé ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún, ọjọ́ yẹn ni gbogbo orísun omi ya, àwọn ibodè omi ọ̀run sì ṣí.+ 12  Òjò rọ̀ sórí ayé fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. 13  Ní ọjọ́ yẹn gan-an, Nóà wọ inú áàkì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì,+ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.+ 14  Wọ́n wọlé, pẹ̀lú gbogbo ẹran inú igbó ní irú tiwọn, gbogbo ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn, gbogbo ẹran tó ń rákò ní ayé ní irú tiwọn, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, títí kan gbogbo ẹyẹ àti gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́. 15  Wọ́n ń wọlé lọ bá Nóà nínú áàkì, ní méjì-méjì, lára onírúurú ẹran tó ní ẹ̀mí.* 16  Wọ́n wá wọlé, akọ àti abo nínú onírúurú ẹran, bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún un. Lẹ́yìn náà, Jèhófà ti ilẹ̀kùn pa. 17  Ìkún omi náà ò dáwọ́ dúró* lórí ayé fún ogójì (40) ọjọ́, omi náà sì ń pọ̀ sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé áàkì náà, ó sì léfòó lórí omi tó bo ayé. 18  Omi náà bolẹ̀, ó sì ń pọ̀ gan-an ní ayé, àmọ́ áàkì náà léfòó lórí omi. 19  Omi náà bo ayé débi pé gbogbo òkè tó ga tó wà lábẹ́ ọ̀run ni omi bò mọ́lẹ̀.+ 20  Omi náà fi ìgbọ̀nwọ́* mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ga ju àwọn òkè lọ. 21  Torí náà, gbogbo ohun alààyè* tó wà ní ayé pa run,+ ìyẹn, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, àwọn ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹran inú igbó, àwọn ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn àti gbogbo aráyé.+ 22  Gbogbo ohun tó wà lórí ilẹ̀ tó ní èémí ìyè* ní ihò imú rẹ̀ ló kú.+ 23  Ó run gbogbo ohun alààyè tó wà ní ayé, títí kan èèyàn àti ẹran, ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run. Gbogbo wọn pátá ló pa run ní ayé;+ Nóà àti àwọn tí wọ́n jọ wà nínú áàkì nìkan ló yè é.+ 24  Omi náà sì bo ayé fún àádọ́jọ (150) ọjọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “méjì-méjì lọ́nà méje lára gbogbo ẹran tó mọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “méjì-méjì lọ́nà méje lára gbogbo ẹran tó mọ́.”
Tàbí “èémí ìyè.”
Tàbí “ń bá a lọ.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”
Tàbí “ẹ̀mí.”