Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Làwọn Èèyàn Ṣe Lè Máa Fi Ọ̀wọ̀ Tèmi Wọ̀ Mí?

Báwo Làwọn Èèyàn Ṣe Lè Máa Fi Ọ̀wọ̀ Tèmi Wọ̀ Mí?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Làwọn Èèyàn Ṣe Lè Máa Fi Ọ̀wọ̀ Tèmi Wọ̀ Mí?

“Alàgbà tó gbajúmọ̀ dáadáa ni bàbá mi nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mò ń bọ̀wọ̀ fún un gan-an, ṣùgbọ́n nígbà míì, kì í dùn mọ́ mi bí wọ́n ṣe máa ń pè mí ní ọmọ Arákùnrin Lágbájá níbikíbi tí mo bá lọ.”—Larry. a

“Nítorí pé bàbá mi jẹ́ alàgbà táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, ńṣe ló dà bí ẹni pé ohun tó dára gan-an làwọn èèyàn máa ń retí pé kí n máa ṣe nígbà gbogbo, èyí wá jẹ́ kó ṣòro fún mi láti ṣe nǹkan lọ́nà tí Ọlọ́run gbà dá mi.”—Alexander.

BÍ O ti ń dàgbà, ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kó o fẹ́ láti ní òmìnira púpọ̀ sí i, ìyẹn ni pé káwọn èèyàn mọ̀ ọ́ bí ẹnì kan, kí wọ́n sì máa fọ̀wọ̀ tìẹ wọ̀ ẹ́. Nígbà tí àwọn òbí rẹ bí ọ, àwọn ni wọ́n yan orúkọ tó wù wọ́n fún ọ. Nígbà tó o sì ti wá ń bàlágà báyìí, ó wù ọ́ pé kí ìwọ náà yan “orúkọ” tí wàá máa jẹ́, ìyẹn ni pé, káwọn èèyàn mọ̀ ọ́ bí ẹnì kan.

Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Orúkọ [rere] ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀; ojú rere sàn ju fàdákà àti wúrà pàápàá.” (Òwe 22:1) Kódà, nígbà tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ yìí, ó lè wù ọ́ pé káwọn èèyàn mọ̀ ọ́ yàtọ̀.

Jíjọlá Àwọn Òbí Rẹ

Bíi ti Larry àti Alexander, àwọn èwe kan lérò pé ọlá orúkọ tàbí ọlá àṣeyọrí àwọn òbí àwọn làwọ́n ń jẹ. Bóyá gbajúmọ̀ láwùjọ làwọn òbí wọn nítorí irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tàbí nítorí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní. Ó sì lè jẹ́ pé ẹni tí wọ́n mọ̀ dáadáa nínú ìjọ Kristẹni ni wọ́n. Bí ọ̀ràn bá rí báyìí nípa àwọn òbí rẹ, nígbà míì ó lè máa ṣe ọ́ bí ẹni pé àwọn èèyàn á máa fi ojú ìyẹn wò ẹ́, á sì dà bí ẹni pé wọ́n ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Inú lè máa bí ọ bí o bá ní láti máa hùwà ní irú ọ̀nà kan pàtó nítorí irú ẹni tí àwọn òbí rẹ jẹ́.

Bí àpẹẹrẹ, Bàbá Ivan ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò wọn. Ivan sọ pé: “Nítorí pé bàbá mi gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta, táwọn èèyàn sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un, nígbà gbogbo ni mo máa ń ronú pé mo gbọ́dọ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe ni ilé ẹ̀kọ́ àti nínú ilé. Mo máa ń ronú pé èmi làwọn òbí mìíràn ń wò láti pinnu bí wọ́n ṣe fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn máa hùwà. Ó lè dà bí àpọ́nlé o, àmọ́ ìrònú yìí máa ń mú kó di dandan fún mi láti ṣe dáadáa lójú àwọn ẹlòmíràn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé n kì í hùwà ìrẹ̀lẹ̀ nígbà míì, n kì í sì í rí àwọn àléébù tèmi alára.” Alexander sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bí ẹni pé ìgbà gbogbo làwọn èèyàn ń ṣọ́ mi, bí mo bá sì ṣe àṣìṣe, àwọn tó máa nàka àbùkù sí mi ti wà ní sẹpẹ́.”

Nítorí kí àwọn èèyàn má bàa máa ṣọ́ Larry tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, ńṣe ló máa ń fi orúkọ bàbá rẹ̀ pa mọ́. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bá bá àwọn ojú tuntun pàdé níbi àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, màá kàn sọ pé, ‘Báwo ni? Larry lorúkọ mi,’ ó tán—mi ò sì jẹ́ dárúkọ bàbá mi. Tó bá ṣeé ṣe nígbà míì, orúkọ mi nìkan ni mo máa ń lò láti fọwọ́ síwèé. Ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn èèyàn á bá mi lò lọ́nà tó yàtọ̀ bí wọ́n bá mọ ọmọ ẹni tí mo jẹ́. Mi ò fẹ́ káwọn ẹlẹgbẹ́ mi máa bá mi lò lọ́nà yíyàtọ̀.”

Àmọ́ ṣá o, kò sí ohun tó burú níbẹ̀ bí àwọn ẹlòmíì bá ń retí pé kó o máa ṣe ohun tó dára nígbà gbogbo bí bàbá rẹ bá jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó ṣe tán, àwọn ọkùnrin tá a bá gbé irú ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lé lọ́wọ́ ní láti máa “ṣe àbójútó àwọn ọmọ àti agbo ilé tiwọn lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” (1 Tímótì 3:5, 12) Abájọ nígbà náà tí àwọn èèyàn fi ń retí pé kí o jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ! Àmọ́, ṣé ohun tí etí ò gbọ́dọ̀ gbọ́ nìyẹn ni? Wàá rí i pé kì í ṣe ohun tó burú nígbà tó o bá rántí pé Pọ́ọ̀lù yan Kristẹni ọ̀dọ́ náà Tímótì, bóyá nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́langba, pé kó máa bá òun rìnrìn àjò kó sì máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ṣe pàtàkì gan-an. (1 Tẹsalóníkà 3:1-3) Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ sakun láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere, yálà bàbá rẹ jẹ́ alàgbà tàbí kì í ṣe alàgbà.

Ìwà Ọ̀tẹ̀ Ò Pé O

Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń hùwà ọ̀tẹ̀ láti fi hàn pé àwọn ò fẹ́ sí lábẹ́ ìdarí àwọn òbí wọn. Ivan sọ pé: “Àwọn ìgbà míì wà tí jíjẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn ẹlòmíràn máa ń bí mi nínú. Mo máa ń fárígá nígbà mìíràn nípa fífi irun orí mi sílẹ̀ tí màá sí máa wo ibi tó máa kún dé kí n tó rẹ́ni sọ fún mi.”

Ábúsálómù, ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Dáfídì Ọba, sọ ara rẹ̀ di ọlọ̀tẹ̀. Bàbá rẹ̀ gbajúmọ̀ nítorí ìfọkànsìn rẹ̀ sí Jèhófà, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló sì fẹ́ràn rẹ̀. Níwọ̀n bí Ábúsálómù sì ti jẹ́ ọmọ Dáfídì, ohun púpọ̀ làwọn èèyàn ń retí látọ̀dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kàkà kí Ábúsálómù hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun yíyẹ táwọn èèyàn ń fojú sọ́nà fún, ó ṣe orúkọ fún ara rẹ̀ nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ sí bàbá rẹ̀. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé aṣojú Jèhófà tí a fòróró yàn ni Dáfídì, Jèhófà gan-an ni Ábúsálómù ń ṣọ̀tẹ̀ sí. Ìwà rẹ̀ kó ẹ̀gàn bá ìdílé rẹ̀ ó sì kó òun fúnra rẹ̀ sí yọ́ọ́yọ́.—2 Sámúẹ́lì 15:1-15; 16:20-22; 18:9-15.

Ìwà ọ̀tẹ̀ lè yọrí sí ìpalára ńláǹlà fún ìwọ náà pẹ̀lú. Ìwọ ronú wò lórí ohun tí Bíbélì sọ fún wa nípa Nehemáyà. Àwọn kan lára àwọn ọ̀tá rẹ̀ gbìyànjú láti tàn án hùwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí. Nítorí kí ni? Nehemáyà dáhùn pé: “Kí wọ́n bàa lè ba orúkọ mi jẹ́ kí wọ́n sì tẹ́ mi lógo.” (Nehemáyà 6:13, Bíbélì Today’s English Version) Ìwà ọ̀tẹ̀ lè sọ ọ́ ní orúkọ burúkú tí àwọn èèyàn ò ní tètè gbà gbé.

Kò sì yẹ kó o gbójú fo ipa tí ìwà ọ̀tẹ̀ lè ní lórí àwọn ẹlòmíràn dá. Ó kéré pin, wàá kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn òbí rẹ láìnídìí. (Òwe 10:1) Ìwà rẹ tún lè nípa búburú lórí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn. Ivan jẹ́wọ́ pé: “Ìwà mi nípa búburú lórí àbúrò mi. Láwọn àkókò kan, ó fi ìjọ Kristẹni sílẹ̀ pátápátá, ó sì ń hu àwọn ìwà tó mọ̀ pé kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Àmọ́, a dúpẹ́ pé ó pe orí ara rẹ̀ wálé, ó ti ń padà sin Jèhófà báyìí ó sì láyọ̀.”

Ohun Tó Sàn Jù

Sólómọ́nì tó jẹ́ ọbàkan Ábúsálómù ò ṣe bíi tiẹ̀. Ó ṣe tán láti fi ìrẹ̀lẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀, Dáfídì. (1 Àwọn Ọba 2:1-4) Dípò kó máa wá ọ̀nà tí yóò fi gbé ara rẹ̀ ga, ńṣe ni Sólómọ́nì ń wá ọ̀nà tí yóò fi ṣe orúkọ rere pẹ̀lú Ọlọ́run. Ní gbogbo ìgbà tó sì fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó buyì kún ìdílé rẹ̀ ó sì di ẹni tí a mọ̀ sí ọ̀kan lára àwọn ọba gíga jù lọ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.—1 Àwọn Ọba 3:4-14.

Àpẹẹrẹ rere Sólómọ́nì fi kókó pàtàkì méjì hàn kedere: Èkíní, kò dìgbà tó o bá ya ara rẹ sọ́tọ̀ kúrò lára ìdílé rẹ káwọn èèyàn tó mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, kìkì nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ rere tí ìdílé rẹ fi lélẹ̀ lo fi lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé àtìgbàdégbà náà Adolescence sọ pé: “Kò sí ìdí kankan tí ìgbà ìbàlágà fi gbọ́dọ̀ jẹ́ ìgbà tí àwọn ọ̀dọ́ á máa dẹ́yẹ sí àwọn òbí wọn nítorí àtilè fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn.” Ìwé ìròyìn náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìtìlẹ́yìn tí àwọn òbí rẹ ń fún ọ ò lè dí ọ lọ́wọ́” láti fi irú ẹni tó o jẹ́ hàn, “kàkà bẹ́ẹ̀ [ó máa] mú [kó] rọrùn ni.”

Ó dùn mọ́ni pé Sólómọ́nì alára gbani níyànjú pé: “Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.” (Òwe 23:22) Ó ṣe kedere pé kì í ṣe àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ni Sólómọ́nì ń kọ̀wé sí, nítorí pé bí àwọn òbí bá ti “darúgbó,” àwọn ọmọ wọn náà ti ní láti dàgbà. Kí wá ni kókó tó ń fà yọ? Kókó náà ni pé lẹ́yìn tó o bá ti dàgbà tó o sì ti ní ìdílé tìrẹ pàápàá, o ṣì lè jàǹfààní látinú ọgbọ́n àwọn òbí rẹ. Bó ṣe wá yé Ivan sí gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Bí mo ti ń dàgbà sí i, mò ń gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àpẹẹrẹ rere àwọn òbí mi, mo sì ń sapá láti yẹra fún àwọn àṣìṣe wọn.”

Kókó kejì tó yẹ láti gbé yẹ̀ wò ni pé mímú inú Jèhófà dùn ni Sólómọ́nì fi sí ipò àkọ́kọ́, kì í ṣe ‘fífẹ́ káwọn èèyàn mọ òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan.’ Lóòótọ́, ohun púpọ̀ ni àwọn èèyàn ń retí látọ̀dọ̀ rẹ̀ g̣ẹ́gẹ́ bí ọmọ Dáfídì. Ṣùgbọ́n, nítorí pé Sólómọ́nì gbára lé Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún un láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀. Ojú tí Alexander náà fi wò ó nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo ti wá gbà báyìí pé àwọn èèyàn sábà máa ń retí ohun tó pọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ alàgbà. Mo sì pinnu láti lo òye yìí lọ́nà tó gbéṣẹ́, ó sì ti dáàbò bò mí gan-an. Mo ti wá mọ̀ pé ojú tí Jèhófà fi ń wò mí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ó mọ̀ mí gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, kì í wulẹ̀ ṣe nítorí ọmọ ẹni tí mo jẹ́.”

Daryn, tí bàbá rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, b níbi tí a ti ń fún àwọn míṣọ́nnárì ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, ni òun pẹ̀lú ti mọ bó ṣe lè kojú ìpèníjà gbígbé pẹ̀lú àwọn òbí tó gbajúmọ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣèrìbọmi, Jèhófà ni mo ya ara mi sí mímọ́ fún kì í ṣe ẹlòmíràn. Nípa ṣíṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ mi, mo ní ìbàlẹ̀ ọkàn nítorí pé mo mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí mi, bí mi ò tiẹ̀ lè ṣe gbogbo ohun tí àwọn òbí mi ti ṣe.”

Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” (Òwe 20:11) Ní àbárèbábọ̀ gbogbo ẹ̀, ohun tó o sọ àti ohun tó o ṣe làwọn èèyàn á máa fi rántí rẹ. Jẹ́ àpẹẹrẹ rere “nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.” Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á fẹ́ràn rẹ wọ́n á sì bọ̀wọ̀ fún ọ nítorí irú ẹni tó o jẹ́!—1 Tímótì 4:12.

Àmọ́ ṣá o, ní ti àwọn èwe mìíràn, ìpèníjà tó dojú kọ wọ́n ni bí àṣeyọrí àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wọn tó ń rọ́wọ́ mú ò ṣe ní bo tiwọn mọ́lẹ̀. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á jíròrò bó o ṣe lè kojú ìpèníjà yìí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì àwọn náà ló sì ń bójú tó o.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Híhùwà ọ̀tẹ̀ á wulẹ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn òbí rẹ ni, á sì ba ìwọ fúnra rẹ lórúkọ jẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àpẹẹrẹ rere rẹ lè ṣàǹfààní fún àwọn ẹlòmíràn