Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àpẹẹrẹ Lẹ́tà Tá A Lè Fi Wàásù

Àpẹẹrẹ Lẹ́tà Tá A Lè Fi Wàásù
  • Kọ àdírẹ́sì rẹ sẹ́yìn lẹ́tà náà kí ẹni tó o kọ ọ́ sí lè fèsì. Tó o bá ronú pé kò ní bọ́gbọ́n mu pé kó o kọ àdírẹ́sì rẹ gangan síbẹ̀, bi àwọn alàgbà bóyá o lè lo àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba yín. Àmọ́, MÁ ṢE lo àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì RÁRÁ.

  • Tó o bá mọ orúkọ ẹni yẹn, kọ ọ́ sínú lẹ́tà náà, ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe ọjà lo fẹ́ polówó fún wọn.

  • Ríi dájú pé o ò ṣi ọ̀rọ̀ kankan kọ, kọ ọ́ lọ́nà tó máa fi yé ẹni náà, kó o sì fi àwọn àmì tó bá yẹ sí i. Jẹ́ kó bójú mu, kó má lọ rí rúdurùdu. Tó bá jẹ́ pé ọwọ́ lo fi kọ ọ́, jẹ́ kó rọrùn ún kà. Kọ ọ́ bíi pé ọ̀rẹ́ rẹ lò ń kọ ọ́ sí, àmọ́ kó o jẹ́ kó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó.

Àpẹẹrẹ lẹ́tà tá a lè fi wàásù ló wà níbí. Nígbàkigbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ kọ lẹ́tà sí ẹnì kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kì í ṣe pé kẹ́ ẹ kọ ọ̀rọ̀ tó wà níbí sílẹ̀ gẹ́lẹ́. Kọ lẹ́tà náà lọ́nà tó máa fi wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan ládùúgbò yín.