ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 10-11

Mósè àti Áárónì Lo Ìgboyà

Mósè àti Áárónì Lo Ìgboyà

10:3-6, 24-26, 28; 11:4-8

Mósè àti Áárónì fi hàn pé àwọn nígboyà, wọn ò sì bẹ̀rù nígbà tí wọ́n kojú Fáráò, ìyẹn ẹni tó lágbára jù lọ láyé nígbà yẹn. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Bíbélì sọ nípa Mósè pé: “Ìgbàgbọ́ mú kó kúrò ní Íjíbítì, àmọ́ kò bẹ̀rù ìbínú ọba, torí ó dúró ṣinṣin bíi pé ó ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Heb 11:27) Mósè àti Áárónì nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e.

Àwọn ipò wo lo ti nílò ìgboyà láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fún ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ?