Ẹ́kísódù 11:1-10

  • Ó kéde ìyọnu kẹwàá (1-10)

    • Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè ẹ̀bùn (2)

11  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ó ku ìyọnu kan tí màá mú wá sórí Fáráò àti Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ó máa jẹ́ kí ẹ kúrò níbí.+ Ṣe ló máa lé yín kúrò níbí nígbà tó bá gbà pé kí ẹ máa lọ.+  Torí náà, sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin béèrè àwọn nǹkan tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe lọ́wọ́ ọmọnìkejì wọn.”+  Jèhófà sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà rí ojúure àwọn ará Íjíbítì. Mósè fúnra rẹ̀ ti wá di ẹni ńlá nílẹ̀ Íjíbítì lójú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àti àwọn èèyàn náà.  Mósè wá sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Tó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ọ̀gànjọ́ òru, màá lọ sí àárín Íjíbítì,+  gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì yóò sì kú,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹrúbìnrin tó ń lọ nǹkan lórí ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn.+  Igbe ẹkún máa pọ̀ gan-an ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, irú ẹ̀ ò sì ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+  Àmọ́, ajá ò tiẹ̀ ní gbó* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àti ẹran ọ̀sìn wọn, kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà lè fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’+  Ó dájú pé gbogbo ìránṣẹ́ rẹ yóò wá bá mi, wọ́n á wólẹ̀ fún mi, wọ́n á sì sọ pé, ‘Máa lọ, ìwọ àti gbogbo èèyàn tó ń tẹ̀ lé ọ.’+ Lẹ́yìn náà, èmi yóò lọ.” Ló bá fi ìbínú kúrò níwájú Fáráò.  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Fáráò ò ní fetí sí yín,+ kí iṣẹ́ ìyanu mi lè pọ̀ sí i nílẹ̀ Íjíbítì.”+ 10  Mósè àti Áárónì ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu yìí níwájú Fáráò,+ àmọ́ Jèhófà jẹ́ kí ọkàn Fáráò le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “yọ ahọ́n sí.”