ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Táwọn Míì Bá Ń Yìn Ẹ́

Yorùbá
Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Táwọn Míì Bá Ń Yìn Ẹ́
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020247/univ/art/202020247_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 July ojú ìwé 8

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Táwọn Míì Bá Ń Yìn Ẹ́

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Táwọn Míì Bá Ń Yìn Ẹ́

Nígbà míì, àwọn èèyàn lè gbóríyìn fún wa torí ohun tá a ṣe. Tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè fún wa níṣìírí. (Owe 15:23; 31:10, 28) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyẹn kó sí wa lórí débi tá a fi máa ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ.

WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN BÍI JÉSÙ​—NÍGBÀ TÍ WỌ́N BÁ Ń YÌN Ọ́, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí làwọn nǹkan tó lè mú káwọn èèyàn máa gbóríyìn fún wa?

  • Báwo ni àwọn ará ṣe gbóríyìn fún Arákùnrin Ṣẹ́gun?

  • Báwo ni wọ́n ṣe yin Arákùnrin Ṣẹ́gun ju bó ṣe yẹ lọ?

  • Kí lo rí kọ́ nínú bí Arákùnrin Ṣẹ́gun ṣe fèsì?