Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Wo Làwọn Ohun Tí Ọlọ́run Dá Kọ́ Wa Nípa Ìgboyà?

Ẹ̀kọ́ Wo Làwọn Ohun Tí Ọlọ́run Dá Kọ́ Wa Nípa Ìgboyà?

Jèhófà ti lo àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin olóòótọ́ inú Bíbélì láti kọ́ wa láwọn ànímọ́ pàtàkì. Àmọ́, a tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. (Jóòbù 12:7, 8) Kí la rí kọ́ nínú bí kìnnìún, ẹṣin, asín igbó, ẹyẹ akùnyùnmù àti erin ṣe nígboyà?

WO FÍDÍÒ NÁÀ KỌ́ ÌGBOYÀ LÁRA ÀWỌN OHUN TÍ ỌLỌ́RUN DÁ, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo làwọn abo kìnnìún ṣe máa ń lo ìgboyà tí wọ́n bá fẹ́ dáàbò bo àwọn ọmọ wọn?

  • Báwo ni wọ́n ṣe máa ń dá àwọn ẹṣin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè nígboyà lójú ogun?

  • Kí nìdí tí asín igbó kì í fi í bẹ̀rù ejò olóró?

  • Báwo làwọn ẹyẹ akùnyùnmù kéékèèké ṣe ń lo ìgboyà?

  • Báwo làwọn erin ṣe ń lo ìgboyà nígbà tí wọ́n bá ń dáàbò bo àwọn erin míì nínú agbo?

  • Ẹ̀kọ́ wo làwọn ẹranko yìí kọ́ ẹ nípa ìgboyà?