Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Barnacle Ṣe Ń Lẹ̀ Mọ́ Nǹkan

Bí Barnacle Ṣe Ń Lẹ̀ Mọ́ Nǹkan

 Ọjọ́ pẹ́ táwọn onímọ̀ nípa ẹranko ti ń kíyè sí ẹran omi òkun kékeré kan tí wọ́n ń pè ní barnacle, ó ní agbára láti lẹ̀ mọ́ àpáta àti afárá, kódà ó lè lẹ̀ mọ́ abẹ́ ọkọ̀ òkun pẹ́kípẹ́kí jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Agbára tí barnacle fi ń lẹ̀ mọ́ nǹkan ju ti gọ́ọ̀mù èyíkéyìí téèyàn ṣe lọ. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni àwọn tó ń ṣèwádìí ṣẹ̀ṣẹ̀ rí àdììtú tó wà nínú bí barnacle ṣe ń lẹ̀ mọ́ nǹkan, kódà tí omi bá wà lára nǹkan náà.

 Rò ó wò ná: Ìwádìí fi hàn pé kí barnacle kan tó yan ibi tó ti máa lo ìyókù ìgbésí ayé ẹ̀, ó máa lúwẹ̀ẹ́ kiri nígbà tó ṣì kéré, kó lè wo ibi tó dáa jù tó máa lẹ̀ mọ́. Tó bá ti rí ibi tó tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó máa tú èròjà méjì sórí ibẹ̀. Àkọ́kọ́ nínú àwọn èròjà yìí dà bí òróró, èròjà yìí ló máa nu omi kúrò lójú ibi tó fẹ́ lẹ̀ mọ́. Èyí á jẹ́ kí èròjà kejì lè ríbi dúró sí, àwọn èròjà purotéènì tí wọ́n ń pè ní phosphoproteins ló sì para pọ̀ di èròjà kejì.

 Àwọn èròjà méjèèjì yìí ló para pọ̀ di gọ́ọ̀mù alágbára tí omi tàbí kòkòrò bakitéríà èyíkéyìí ò lè bà jẹ́. Ó ṣe pàtàkì kí gọ́ọ̀mù náà lágbára gan-an torí pé ibi tí barnacle bá lẹ̀ mọ́ ló ti máa lo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀.

Ìṣùpọ̀ barnacle ló wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn. Àkámọ́ roboto iwájú yìí ń fi àwọn fọ́nrán gọ́ọ̀mù rẹ̀ kọ̀ọ̀kan hàn

 Ọ̀nà tí barnacle gbà ń ṣe gọ́ọ̀mù alágbára yìí díjú kọjá ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rò tẹ́lẹ̀. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ohun àgbàyanu ló jẹ́ láti rí gọ́ọ̀mù tó lágbára bí èyí, ó ti jẹ́ ká rí ojútùú sí ìṣòro tá a máa ń ní tá a bá fẹ́ lẹ nǹkan tí omi wà lára ẹ̀.” Ohun táwọn tó ń ṣèwádìí rí yìí máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe gọ́ọ̀mù tí á lè máa lẹ nǹkan dáadáa kódà lábẹ́ omi, wọ́n á tún lè lò ó tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àti lẹ́nu iṣẹ́ ìṣègùn.

 Kí lèrò ẹ? Ṣé agbára tí gọ́ọ̀mù barnacle ní láti lẹ̀ mọ́ nǹkan pẹ́kípẹ́kí yìí kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?