Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Ẹja Remora Ṣe Máa Ń Lẹ̀ Mọ́ Nǹkan

Bí Ẹja Remora Ṣe Máa Ń Lẹ̀ Mọ́ Nǹkan

 Ọ̀kan lára àwọn ẹja tó máa ń lẹ̀ mọ́ nǹkan nínú omi ni ẹja remora. Ó lágbára láti lẹ̀ mọ́ oríṣiríṣi ẹja tàbí àwọn nǹkan míì tó wà nínú omi, kó sì tún ṣí ara ẹ̀ kúrò láìṣèpalára fún ohun tó lẹ̀ mọ́ náà. Ohun ìyanu ló jẹ́ fáwọn tó ń ṣèwádìí nígbà tí wọ́n rí ọ̀nà àgbàyanu tí ẹja yìí ń gbà lẹ̀ mọ́ nǹkan.

 Rò ó wò ná: Ẹja remora máa ń lẹ̀ mọ́ oríṣiríṣi ẹja nínú omi, irú bí ẹja ray, àbùùbùtán, ìjàpá, àtàwọn míì láìka bí ara wọn bá ṣe rí. Tí remora bá lẹ̀ mọ́ ẹja kan nínú omi, ẹja náà láá máa gbé e kiri, táá sì máa dáàbò bò ó. Oúnjẹ tó bá bọ́ látẹnu ẹja tó ń gbé e kiri yẹn ló máa ń jẹ pẹ̀lú àwọn kòkòrò míì tó bá rí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣèwádìí lórí ohun tó ń mú kó ṣeé ṣe fún ẹja remora láti lẹ̀ mọ́ àwọn ẹja míì nínú omi, kí wọ́n lè mọ bí ẹja náà ṣe máa ń rọra lẹ̀ mọ́ nǹkan tí ò sì ní tètè já kúrò láìka bí ojú ibi tó lẹ̀ mọ́ ṣe rí.

 Àwọn ẹja remora lẹ̀ mọ́ ẹja àbùùbùtán, ẹja náà sì ń gbé wọn kiri

 Ẹ̀yìn orí ẹja remora ni ohun tó ń mú kó lẹ̀ mọ́ nǹkan lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yẹn wà. Ohun náà rí pẹrẹsẹ, ó sì dà bí awọ tí ò fi bẹ́ẹ̀ yi. Ó ní àwọn ilà tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ilà náà sì ní ohun tó dà bí ẹ̀gún kéékèèké tó le. Tí ohun tó dà bí ilà náà bá kan ẹja tí remora fẹ́ lẹ̀ mọ́, àwọn nǹkan tó dà bí ẹ̀gún lára ẹ̀ máa wọ ara ẹja náà, á sì dì í mú. Láìka bí ohun tí remora lẹ̀ mọ́ bá ṣe ń sáré, tó sì ń fara pitú nínú omi, ṣe ni remora máa dúró digbí. Ohun tó ń mú kíyẹn ṣeé ṣe ni bí ohun tó rí pẹrẹsẹ tó wà lórí ẹ̀ ṣe máa ń jẹ́ kó lẹ̀ mọ́ nǹkan, tóhun tó dà bí ẹ̀gún á sì di nǹkan tó lẹ̀ mọ́ náà mú dáadáa.

 Nígbà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàyẹ̀wò ohun tó ń mú kó ṣeé ṣe fún ẹja remora láti lẹ̀ mọ́ nǹkan, ó jọ wọ́n lójú gan-an, làwọn náà bá gbìyànjú láti ṣe ohun tó jọ ọ́. Ohun tí wọ́n ṣe náà lè lẹ̀ mọ́ oríṣiríṣi nǹkan. Nígbà tí wọ́n lẹ̀ ẹ́ mọ́ ohun kan tí wọ́n sì gbìyànjú láti já a kúrò, ṣe ló dì í mú ṣinṣin láìka bí wọ́n ṣe fi gbogbo agbára fà á!

 Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn onímọ̀ ẹ̀rọ lè gbà lo ọgbọ́n tí wọ́n kọ́ látinú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nípa bí ẹja remora ṣe ń lẹ̀ mọ́ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi ṣe ohun tí wọ́n máa ń so mọ́ ara ẹja láti lè fi ṣèwádìí nípa ẹ̀, wọ́n lè lò ó láti ṣèwádìí nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nísàlẹ̀ omi, wọ́n tún lè lò ó láti so iná tàbí àwọn nǹkan míì mọ́ ọkọ̀ ojú omi tàbí afárá.

 Kí lèrò ẹ? Ṣé ohun tó máa ń mú kí ẹja remora lẹ̀ mọ́ nǹkan ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣe iṣẹ́ àrà yìí?