Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ọtí

Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ọtí

 “Ọmọ ọdún mẹ́fà ni ọmọbìnrin wa nígbà tá a kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa ọtí. Ó yà wá lẹ́nu pé ọ̀rọ̀ ọtí ò ṣàjèjì sí i rárá tó bá a ṣe rò.”​—Alexander.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Ó ṣe pàtàkì kó o kọ́ àwọn ọmọ ẹ nípa ọtí. Má dúró dìgbà tí ọmọ ẹ bá tó wọ ọdún kẹtàlá. Khamit láti Rọ́ṣíà sọ pé, “Ó dùn mí pé a ò tètè bá ọmọ wa ọkùnrin sọ̀rọ̀ láti kékeré nípa ojú tó yẹ kéèyàn fi máa wo ọtí mímu. Ìgbà tọ́rọ̀ bẹ́yìn yọ tán ni mo tó rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó. Àṣé ọmọ wa ò ju ọdún mẹ́tàlá lọ tó ti ń mu ọtí léraléra.”

 Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o fojú kéré ọ̀rọ̀ yìí?

  •   Àwọn ọmọ kíláàsì ọmọ rẹ, àwọn tó ń polówó ọjà àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n lè nípa lórí ojú tí ọmọ rẹ fi ń wo ọtí.

  •   Àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí bí wọ́n ṣe ń kápá àìsàn, tí wọ́n sì ń dènà ẹ̀ ní Amẹ́ríkà ṣèwádìí tó jẹ́ ká rí i pé tá a bá pín gbogbo ọtí táwọn èèyàn ń mu lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ́nà ọgọ́rùn-ún (100), mọ́kànlá (11) nínú ẹ̀ ló jẹ́ pé àwọn tọ́jọ́ orí wọn ò tó tẹni tó lè mutí ló mu ún.

 Abájọ táwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ìlera fi dábàá ẹ̀ fáwọn òbí pé àtikékeré ni kí wọ́n ti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ewu tó wà nínú ọtí mímu. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

 Ohun tó o lè ṣe

 Ronú àwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kí ọmọ ẹ bi ẹ́. Báwọn ọmọ bá ṣe ń dàgbà sí ni wọ́n ṣe máa ń túbọ̀ fẹ́ mọ nǹkan sí. Torí náà, á dáa kó o ti múra bó o ṣe máa dá ọmọ ẹ lóhùn tó bá bi ẹ́ níbèérè. Bí àpẹẹrẹ:

  •   Ká sọ pé ọmọ ẹ fẹ́ mọ bí ọtí ṣe máa ń rí lẹ́nu, o lè sọ fún un pé bí omi ọsàn tó kan ni wáìnì ṣe máa ń rí, àmọ́ ọtí bíà lè korò lẹ́nu.

  •   Ká sọ pé ọmọ ní òun fẹ́ tọ́ ọtí wò, o lè sọ fún un pé ọtí lágbára jù fún ara àwọn ọmọdé. Ṣàlàyé fún un pé èèyàn lè fi ọtí tura, àmọ́ tó bá ti pọ̀ jù, ojú onítọ̀hún lè bẹ̀rẹ̀ sí í pòòyì, kó máa ṣe rádaràda tàbí kó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìsọkúsọ, tó máa pa dà kábàámọ̀ tó bá yá.​—Òwe 23:​29-​35.

 Dá ara ẹ lẹ́kọ̀ọ́. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà.” (Òwe 13:16) Kí ìwọ fúnra ẹ mọ àǹfààní àti ewu tó wà nínú ọtí mímu, kó o sì mọ òfin tó de ọ̀rọ̀ ọtí mímu ní orílẹ̀-èdè yín. Ìgbà yẹn lo máa tó lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ dáadáa.

 Ìwọ ni kó o dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Mark, tó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, “Ọ̀rọ̀ ọtí kì í sábà yé àwọn ọmọdé. Mo bi ọmọkùnrin mi ọlọ́dún mẹ́jọ bóyá ó dáa kéèyàn mu ọtí àbí kò dáa. Mo rí i pé mo fi í lára balẹ̀, mi ò sì mú ọ̀rọ̀ náà le, èyí jẹ́ kó lè sọ bó ṣe rí lára ẹ̀ láìbẹ̀rù.”

 Tó o bá ń dá ọ̀rọ̀ nípa ọtí sílẹ̀ léraléra, ohun tó o bá sọ á túbọ̀ wọ àwọn ọmọ ẹ lọ́kàn. Bí ọmọ ẹ bá ṣe dàgbà tó, ó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ míì mọ́ ọn tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọtí, irú bí ọ̀rọ̀ sísọdá títì àti ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.

 Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Bíi tìmùtìmù làwọn ọmọdé rí, ohun tí wọ́n ń rí láyìíká wọn máa ń tètè ràn wọ́n, bí ìgbà tí tìmùtìmù bá fa omi. Ìwádìí sì fi hàn pé àwọn òbí ló máa ń nípa tó pọ̀ jù lórí àwọn ọmọ wọn. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé, tó bá jẹ́ pé ọtí lo fi máa ń tura ṣáá tó bá ti rẹ̀ ẹ́, ohun tó ò ń dọ́gbọ́n sọ fún ọmọ ẹ ni pé ọtí lèèyàn fi ń yanjú ìṣòro láyé yìí. Torí náà, àpẹẹrẹ rere ni kó o jẹ́. Rí i pé ò ń hùwà ọmọlúàbí tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu.

Àpẹẹrẹ bí ìwọ òbí ṣe ń mu ọtí ni àwọn ọmọ á máa tẹ̀ lé