Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsọ̀rí 2

“Olùfẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”

“Olùfẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”

Àìṣèdájọ́ òdodo wọ́pọ̀ gan-an láyé òde òní, àwọn èèyàn a sì máa fi àìmọ̀kan sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni. Síbẹ̀, Bíbélì kọ́ wa ní òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tó dùn mọ́ni. Òótọ́ ọ̀rọ̀ náà ni pé “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Sáàmù 37:28) Ní ìsọ̀rí yìí a óò kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, tí ó sì tipa báyìí mú kí ọmọ aráyé nírètí.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 11

“Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀ Jẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”

Báwo ni ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣe ń mú ká sún mọ́ ọn?

ORÍ 12

“Àìṣèdájọ́ Òdodo Ha Wà Pẹ̀lú Ọlọ́run Bí?”

Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Jèhófà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ, kí ló dé tí ìwà ìrẹ́jẹ fi kúnnú ayé?

ORÍ 13

“Òfin Jèhófà Pé”

Báwo ni òfin ṣe lè mú kéèyàn máa nífẹ̀ẹ́?

ORÍ 14

Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”

Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí kò ṣòroó lóye tó máa mú wa sún mọ́ Ọlọ́run

ORÍ 15

Jésù “Gbé Ìdájọ́ Òdodo Kalẹ̀ ní Ilẹ̀ Ayé”

Báwo ni Jésù ṣe gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ láyé àtijọ́? Báwo lo ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí? Báwo ló sì ṣe máa fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

ORÍ 16

Máa “Ṣe Ìdájọ́ Òdodo” Bó O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rìn

Kí ló dé tí Jésù fi kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́”?