Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 Orí 26

Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

1-3. (a) Ẹrù wíwúwo wo ló wọ Dáfídì onísáàmù náà lọ́rùn, kí ló sì tù ú lọ́kàn? (b) Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ẹrù wíwọni lọ́rùn wo ni èyí lè dì rù wá, àmọ́ ìdánilójú wo ni Jèhófà fún wa?

DÁFÍDÌ onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Àwọn ìṣìnà mi ti gba orí mi kọjá; bí ẹrù wíwúwo, wọ́n wúwo jù fún mi. Ara mi ti kú tipiri, mo sì ti di ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó.” (Sáàmù 38:4, 8) Dáfídì mọ bí ẹrù ìdààmú ti ẹ̀rí ọkàn tí ń dáni lẹ́bi ṣe wúwo tó. Ṣùgbọ́n nǹkan kan wà tó ń tù ú lọ́kàn. Ó mọ̀ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, kò kórìíra ẹlẹ́ṣẹ̀ náà, bí onítọ̀hún bá sáà ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tó sì yọwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún pé Jèhófà múra tán láti ṣojú àánú sí àwọn tó bá ronú pìwà dà, Dáfídì sọ pé: “Jèhófà, o . . . ṣe tán láti dárí jini.”—Sáàmù 86:5.

2 Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀rí ọkàn wa pẹ̀lú lè di ẹrù wíwúwo fún wa, kó máa nà wá ní pàṣán. Ẹ̀dùn ọkàn yìí ní iṣẹ́ tó ń ṣe. Ó lè sún wa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti lè ṣàtúnṣe. Àmọ́ o, èèyàn tún lè wá jẹ́ kí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ bo òun mọ́lẹ̀ pátápátá. Ọkàn wa lè máa yọ wá lẹ́nu ṣáá pé Jèhófà kò ní dárí jì wá bó ti wù ká ronú pìwà dà tó. Bí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ bá wá ‘gbé wa mì,’ Sátánì lè sapá láti mú wa juwọ́ sílẹ̀, ká wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé a ò wúlò mọ́ lójú Jèhófà, pé irú wa ò yẹ lẹ́ni tí ń sìn ín.—2 Kọ́ríńtì 2:5-11.

3 Ṣé irú ojú tí Jèhófà fi ń wò wá nìyẹn? Rárá o! Ìdáríjì jẹ́ apá kan lára ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà ní. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó mú un dá wa lójú pé tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, òun ṣe tán láti dárí jì wá. (Òwe 28:13) Kí a má bàa máa rò pé àlá tí kò  lè ṣẹ ni rírí ìdáríjì gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tí Jèhófà fi ń dárí jini àti bó ṣe ń dárí jini.

Ìdí Tí Jèhófà Fi “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

4. Kí ni Jèhófà ń rántí nípa ẹ̀dá wa, báwo sì ni èyí ṣe kan ọwọ́ tó fi ń mú wa?

4 Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ. Sáàmù 103:14 sọ pé: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” Kì í gbàgbé pé ẹ̀dá tó wá látinú ekuru ni wá, tó ní àìlera tàbí kùdìẹ̀-kudiẹ, nítorí jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé. Gbólóhùn náà pé ó mọ “ẹ̀dá wa” rán wa létí pé Bíbélì fi Jèhófà wé amọ̀kòkò, ó sì fi wá wé ìkòkò tí ó mọ. * (Jeremáyà 18:2-6) Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà ń wo ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ tá a jẹ́ mọ́ wa lára, ó sì tún wo ìhà tá a kọ sí ìtọ́sọ́nà rẹ̀, bóyá à ń tẹ̀ lé e tàbí a kò tẹ̀ lé e.

5. Báwo ni ìwé Róòmù ṣe ṣàpèjúwe agbára tí ẹ̀ṣẹ̀ ń sà lórí wa?

5 Jèhófà mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti lágbára tó. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣàpèjúwe ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipá lílágbára, tó mú aráyé mọ́lẹ̀ dan-in dan-in. Báwo tilẹ̀ ni agbára tí ẹ̀ṣẹ̀ ń sà lórí wa ṣe pọ̀ tó? Nínú ìwé Róòmù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: A wà “lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,” bí àwọn ọmọ ogun ṣe máa ń wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gágun wọn (Róòmù 3:9); pé ẹ̀ṣẹ̀ ń “ṣàkóso” aráyé bí ọba (Róòmù 5:21); ó “ń gbé” inú wa (Róòmù 7:17, 20); “òfin” rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nínú wa láìfi wá lọ́rùn sílẹ̀, ó fẹ́ máa darí wa bó ṣe wù ú. (Róòmù 7:23, 25) Agbára ńlá tí ẹ̀ṣẹ̀ ń sà lórí ẹran ara àìpé wa mà pọ̀ o!—Róòmù 7:21, 24.

6, 7. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń fi ọkàn ìròbìnújẹ́ wá ojú àánú rẹ̀? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fojú tín-ínrín àánú Ọlọ́run?

6 Nítorí náà, Jèhófà mọ̀ pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣègbọràn sí òun lọ́nà pípé, bó ti wù kí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ wá  lọ́kàn tó. Ó mú un dá wa lójú tìfẹ́tìfẹ́ pé bí a bá fi ọkàn ìrònúpìwàdà wá ojú àánú òun, òun á dárí jì wá. Sáàmù 51:17 sọ pé: “Àwọn ẹbọ sí Ọlọ́run ni ẹ̀mí tí ó ní ìròbìnújẹ́; ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” Láéláé, Jèhófà kò ní tẹ́ńbẹ́lú, tàbí kí ó kọ ọkàn “tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀” nítorí pé ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ bò ó mọ́lẹ̀.

7 Ṣùgbọ́n, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé a lè fojú tín-ínrín àánú Ọlọ́run, ká máa fi ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ tá a jẹ́ kẹ́wọ́ láti lè máa dẹ́ṣẹ̀? Rárá o! Kì í ṣe ìgbónára lásánlàsàn ló ń darí Jèhófà. Àánú rẹ̀ ní ààlà. Dájúdájú, kò ní dárí ji àwọn tí ń forí kunkun dá ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, tí wọ́n sì kọ̀ láti ronú pìwà dà. (Hébérù 10:26) Àmọ́, nígbà tó bá rí ọkàn tó ní ìròbìnújẹ́, ó ṣe tán láti dárí jì í. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn èdè tó fakíki tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe apá fífanimọ́ra yìí nínú ìfẹ́ Jèhófà.

Báwo Ni Ìdáríjini Jèhófà Ṣe Ń Rìn Jìnnà Tó?

8. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kí ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà tó bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ìgbọ́kànlé wo sì ni èyí fún wa?

8 Dáfídì tó ronú pìwà dà wí pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀. . . . Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” (Sáàmù 32:5) Gbólóhùn náà ‘dárí jì’ tú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ ní ṣáńgílítí sí “gbé” tàbí “rù.” Bá a ṣe lò ó níhìn-ín dúró fún mímú “ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀, ìrékọjá” kúrò. Nítorí náà, ohun tí ibí yìí ń sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ni pé Jèhófà gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì lọ. Kò sí iyèméjì pé èyí pẹ̀rọ̀ sí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tó bo Dáfídì mọ́lẹ̀. (Sáàmù 32:3) Àwa náà lè ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run tí ń kó ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ń wá ìdáríjì rẹ̀ lọ, lọ́lá ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹbọ ìràpadà Jésù.—Mátíù 20:28.

9. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa tó?

 9 Dáfídì lo gbólóhùn mìíràn tó fakíki láti fi ṣàlàyé ìdáríjì Jèhófà. Ó sọ pé: “Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa.” (Orin Dafidi 103:12, Bibeli Mimọ) Báwo ni ìlà oòrùn ṣe jìnnà tó sí ìwọ̀ oòrùn? Ìlà oòrùn ni ibi tá a gbà pé ó jìnnà jù lọ sí ìwọ̀ oòrùn; ìhà méjèèjì ò lè bára pàdé láé. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé gbólóhùn yìí túmọ̀ sí “jìnnà réré; ibi jíjìnnà jù lọ.” Ọ̀rọ̀ onímìísí tí Dáfídì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, ó máa ń kó ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ sí ibi tó jìnnà jù lọ sí wa.

‘A ó sọ ẹ̀ṣẹ̀ yín di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì’

10. Nígbà tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, èé ṣe tí kò fi yẹ ká rò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa?

10 Ǹjẹ́ o tíì gbìyànjú láti mú àbààwọ́n kúrò lára aṣọ aláwọ̀ títàn yòyò rí? Bóyá gbogbo bó o ṣe fọ̀ ọ́ tó, àbààwọ́n náà ṣì hàn. Ẹ wá jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ṣàpèjúwe bí ìdáríjini rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n  di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì; bí wọ́n tilẹ̀ pupa bí aṣọ pípọ́ndòdò, wọn yóò dà bí irun àgùntàn gẹ́lẹ́.” (Aísáyà 1:18) Ọ̀rọ̀ náà “rírẹ̀dòdò” jẹ́ àwọ̀ tó pupa yòò. * Àwọ̀ “pípọ́ndòdò” jẹ́ ọ̀kan lára àwọ̀ pupa tí wọ́n fi ń pa aṣọ láró. (Náhúmù 2:3) Bó ṣe wù ká sapá tó, a ò lè fúnra wa mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Ṣùgbọ́n Jèhófà lè mú ẹ̀ṣẹ̀ tó pupa bí aṣọ rírẹ̀dòdò, tàbí èyí tó pọ́n dòdò, kí ó sọ ọ́ di funfun gbòò bí ìrì dídì tàbí bí irun àgùntàn tí a kò tíì pa láró. Nígbà tí Jèhófà bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kò sídìí fún rírò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.

11. Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà ń ju ẹ̀ṣẹ̀ wa sẹ́yìn ara rẹ̀?

11 Nínú orin tó wúni lórí kan tí Hesekáyà fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lẹ́yìn tó mú kí ó ye àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan, ó sọ fún Jèhófà pé: “O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.” (Aísáyà 38:17) Ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé Jèhófà mú ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan tó ti ronú pìwà dà, ó sì jù ú sẹ́yìn Rẹ̀, níbi tí Òun ò ti ní rí i mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan ti wí, èrò tí ibí yìí gbé yọ ni pé: “O ti jẹ́ kí [ẹ̀ṣẹ̀ mi] dà bí èyí tí kò tilẹ̀ wáyé rí rárá.” Ǹjẹ́ èyí kò fini lọ́kàn balẹ̀?

12. Báwo ni wòlíì Míkà ṣe fi hàn pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, ńṣe ni Ó máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá?

12 Nínú ìlérí kan tó jẹ́ ìlérí ìmúbọ̀sípò, wòlíì Míkà sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó dá a lójú pé Jèhófà yóò dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀ tó ronú pìwà dà, ó ní: “Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ, . . . tí ó . . . ń ré ìṣìnà àṣẹ́kù ogún rẹ̀ kọjá? . . . Ìwọ yóò sì sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sínú ibú òkun.” (Míkà 7:18, 19) Sáà ronú ohun tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn máa túmọ̀ sí létí àwọn tó ń gbé ayé nígbà tá a kọ Bíbélì. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti rí ohun tá a sọ “sínú ibú òkun” yọ? Rárá o. Fún ìdí yìí, ọ̀rọ̀ Míkà fi hàn pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jì wá, ńṣe ló máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá.

13. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù náà “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá”?

 13 Jésù fi ohun tó wà láàárín ayánilówó àti ajigbèsè ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Jésù sọ pé ká máa gbàdúrà pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá.” (Mátíù 6:12) Jésù tipa báyìí fi ẹ̀ṣẹ̀ wé gbèsè. (Lúùkù 11:4) Nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀, “gbèsè” la jẹ Jèhófà yẹn. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe kan lédè Gíríìkì tá a tú sí “dárí jì” ni: “Láti yááfì gbèsè kan, láti gbójú fò ó, nípa ṣíṣàìbéèrè mọ́.” Tó túmọ̀ sí pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jini, ṣe ló fagi lé gbèsè tí ì bá kà sí wa lọ́rùn. Nítorí náà, kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ti ronú pìwà dà lọ fọkàn balẹ̀. Jèhófà kò ní sìn wá ní gbèsè tó ti fagi lé láé!—Sáàmù 32:1, 2.

14. Kí ni gbólóhùn náà “kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́” mú wá síni lọ́kàn?

14 Nínú Ìṣe 3:19, Bíbélì tún ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” Gbólóhùn náà ‘pa rẹ́’ tí a lò yìí tú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì kan tó lè túmọ̀ sí “láti nu nǹkan nù, . . . láti fagi lé nǹkan tàbí láti pa nǹkan run.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, èrò tó mú wá síni lọ́kàn ni pípa ohun téèyàn fọwọ́ kọ rẹ́. Báwo ni èyí ṣe lè ṣeé ṣe? Àpòpọ̀ èédú, oje igi àti omi ni wọ́n sábà fi ń ṣe yíǹkì láyé àtijọ́. Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi irú yíǹkì bẹ́ẹ̀ kọ̀wé tán, ó lè fi kànrìnkàn tí ó ti rẹ sínú omi pa ohun tí ó kọ rẹ́. Àpèjúwe alárinrin yìí bá àánú Jèhófà mu wẹ́kú. Nígbà tó bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ṣe ló dà bíi pé ó fi kànrìnkàn nù ún nù.

Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun “ṣe tán láti dárí jini”

15. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ nípa òun?

15 Nígbà tá a bá ronú lórí ọ̀kan-kò-jọ̀kan àpèjúwe wọ̀nyí, ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun ṣe tán lóòótọ́ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, bó bá rí i pé a ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Kò tún yẹ ká bẹ̀rù pé yóò ka irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí wa lọ́rùn lọ́jọ́ ọ̀la. A rí àrídájú èyí nínú ohun mìíràn tí Bíbélì fi hàn nípa àánú ńlá Jèhófà, ìyẹn: Nígbà tó bá dárí jini, ó gbàgbé ọ̀rọ̀ náà nìyẹn.

 ‘Èmi Kì Yóò Rántí Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn Mọ́’

16, 17. Nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ló túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

16 Jèhófà ṣèlérí fáwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun pé: “Èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” (Jeremáyà 31:34) Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí Jèhófà bá dárí jini, kò lè rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Jèhófà dárí jì, títí kan Dáfídì, sáà wà nínú Bíbélì. (2 Sámúẹ́lì 11:1-17; 12:13) Ó dájú pé Jèhófà ṣì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ìrònúpìwàdà wọn àti bí Ọlọ́run ṣe dárí jì wọ́n, wà ní àkọọ́lẹ̀ fún àǹfààní wa.  (Róòmù 15:4) Kí wá ni ọ̀rọ̀ Bíbélì túmọ̀ sí, pé Jèhófà kì í “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ó dárí jì?

17 Ọ̀rọ̀ ìṣe inú èdè Hébérù tí a tú sí ‘èmi yóò rántí’ kò mọ sórí wíwulẹ̀ rántí ohun àtẹ̀yìnwá. Ìwé Theological Wordbook of the Old Testament sọ pé “ó tún wé mọ́ gbígbé ìgbésẹ̀ lórí ohun náà téèyàn rántí.” Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nínú ọ̀ràn yìí, láti “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ wé mọ́ fífi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀. (Hóséà 9:9) Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run sọ pé “ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́,” ó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tí òun bá ti lè dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, òun ò tún ní bẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyẹn wò lára rẹ̀ mọ́ lẹ́yìnwá ọ̀la. (Ìsíkíẹ́lì 18:21, 22) Nípa báyìí, Jèhófà máa ń gbàgbé ní ti pé kì í gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kò wá lójú mọ́, tàbí kó máa wá fìyà rẹ̀ jẹ wá léraléra. Ǹjẹ́ kò tuni nínú pé Ọlọ́run wa ń dárí jì wá, ó sì ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wa?

Àbájáde Rẹ̀ Ńkọ́?

18. Kí nìdí tí ìdáríjì kò fi túmọ̀ sí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ìwà àìtọ́ rẹ̀?

18 Ǹjẹ́ torí pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jini túmọ̀ sí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ìwà àìtọ́ rẹ̀? Rárá o. Ẹlẹ́ṣẹ̀ ò lè lọ láìjìyà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Ẹ̀ṣẹ̀ wa lè ṣe àwọn àkóbá kan fún wa. Èyí kò túmọ̀ sí pé lẹ́yìn tí Jèhófà bá dárí jì wá ló tún ń mú ìyọnu bá wa. Nígbà tí wàhálà bá dé, kò yẹ kí Kristẹni kan máa rò ó pé, ‘Ó mà lè jẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi àtẹ̀yìnwá ni Jèhófà ń fìyà rẹ̀ jẹ mí yìí o.’ (Jákọ́bù 1:13) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà kì í ràdọ̀ bò wá kúrò lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ìwà àìtọ́ wa. Ìkọ̀sílẹ̀, oyún ẹ̀sín, kíkó àrùn látinú ìṣekúṣe, dídi ẹni tí a kò fọkàn tán mọ́ tàbí dídi ẹni ẹ̀tẹ́, àní gbogbo ìwọ̀nyí ló ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìyọnu tí ẹ̀ṣẹ̀ wa kó bá wa. Rántí pé, kódà lẹ́yìn tí Jèhófà  dárí ji Dáfídì nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó dá nínú ọ̀ràn Bátí-ṣébà àti Ùráyà, kò ràdọ̀ bo Dáfídì kúrò lọ́wọ́ àwọn àjálù tó tipa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ já lù ú.—2 Sámúẹ́lì 12:9-12.

19-21. (a) Báwo ni òfin tó wà nínú Léfítíkù 6:1-7 ṣe ṣàǹfààní fún ẹni tá a ṣẹ̀ àti ẹni tó ṣẹ̀? (b) Bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá pa ẹlòmíràn lára, ìgbésẹ̀ wo ni inú Jèhófà máa ń dùn pé ká gbé?

19 Ẹ̀ṣẹ̀ wa tún lè ní àwọn àbájáde mìíràn, pàápàá bí ohun tá a ṣe bá ṣèpalára fáwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, gbé àkọsílẹ̀ Léfítíkù orí kẹfà yẹ̀ wò. Níbẹ̀, Òfin Mósè sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo ní ti pé ó fi olè jíjà, ìlọ́nilọ́wọ́gbà tàbí jìbìtì gba nǹkan ìní ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà wá sẹ́ kanlẹ̀, tó tún lórí-láyà tó ń búra èké. Ó wá di pé èkíní ń sọ pé ó ṣe é, èkejì sì ń sẹ́ pé òun ò ṣe é. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí na ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní pàṣán, ó sì wá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kí Ọlọ́run tó lè dárí jì í, ó ní láti ṣe ohun mẹ́ta mìíràn, ìyẹn ni: kí ó dá ohun tí ó mú padà, kí ó san owó ìtanràn tí iye rẹ̀ jẹ́ ìdá márùn-ún ohun tí ó jí fún oní-ǹkan, kí ó sì fi àgbò kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi. Ẹ̀yìn náà ni òfin tó sọ pé: “Kí àlùfáà . . . ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì dárí rẹ̀ jì í.”—Léfítíkù 6:1-7.

20 Ojú àánú Ọlọ́run ló jẹ́ kó ṣe òfin yìí. Ó ṣàǹfààní fún oní-ǹkan tí wọ́n dá nǹkan rẹ̀ padà, ó sì dájú pé ara á tù ú nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, òfin náà ṣàǹfààní fún ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sún un nígbẹ̀yìngbẹ́yín láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì ṣàtúnṣe. Àmọ́, ká ní ó kọ̀ tí kò jẹ́wọ́, tí kò sì ṣàtúnṣe ni, kò ní rí ìdáríjì Ọlọ́run.

21 Bí a kò tilẹ̀ sí lábẹ́ Òfin Mósè, Òfin yẹn jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà, títí kan èrò rẹ̀ nípa ìdáríjì. (Kólósè 2:13, 14) Bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ti pa àwọn ẹlòmíràn lára, inú Ọlọ́run máa ń dùn bá a bá sa gbogbo ipá wa láti ṣàtúnṣe ọ̀ràn ọ̀hún. (Mátíù 5:23, 24) Èyí lè kan jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, gbígbà pé a jẹ̀bi, àní ká tún tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹni tí a ṣẹ̀. Lẹ́yìn náà, a lè wá bẹ Jèhófà,  lọ́lá ẹbọ Jésù, ká sì ní ìdánilójú pé Ọlọ́run ti dárí jì wá.—Hébérù 10:21, 22.

22. Kí ni ohun mìíràn tí ìdáríjì Jèhófà lè ní nínú?

22 Gẹ́gẹ́ bí òbí onífẹ̀ẹ́ ti ń ṣe, Jèhófà lè fi ìbáwí díẹ̀ kún ìdáríjì tó fún wa. (Òwe 3:11, 12) Àǹfààní sísìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tàbí ajíhìnrere alákòókò kíkún lè bọ́ lọ́wọ́ Kristẹni kan tó ronú pìwà dà. Ó lè dùn ún pé fún sáà kan òun á pàdánù àwọn àǹfààní tóun ń gbé gẹ̀gẹ̀. Ṣùgbọ́n, irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé Jèhófà kò dárí jì í. Ká má gbàgbé o, pé ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ ẹ̀rí pé ó fẹ́ràn wa. Títẹ́wọ́gba ìbáwí náà, ká sì tẹ̀ lé e jẹ́ fún ire wa.—Hébérù 12:5-11.

23. Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé a kò lè rí àánú Jèhófà láé, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe àfarawé rẹ̀ nínú bó ṣe ń dárí jini?

23 Ẹ wo bó ti ń tuni lára tó láti mọ̀ pé Ọlọ́run wa “ṣe tán láti dárí jini”! Àṣìṣe yòówù kí á ṣe, ká má ṣe parí èrò sí pé a ò lè rí àánú Jèhófà láé o. Bí a bá ronú pìwà dà látọkànwá, tá a gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe, tá a sì gbàdúrà tọkàntọkàn fún ìdáríjì, ẹ jẹ́ ká lọ fọkàn balẹ̀ pé lọ́lá ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀, Jèhófà á dárí jì wá. (1 Jòhánù 1:9) Ẹ jẹ́ ká máa dárí ji ara wa lẹ́nì kìíní kejì ní àfarawé Jèhófà. Ó ṣe tán, bí Jèhófà tí kì í dẹ́ṣẹ̀, bá ń fi tìfẹ́tìfẹ́ dárí jì wá, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ máa sa gbogbo ipá wa láti dárí ji ọmọnìkejì wa?

^ ìpínrọ̀ 4 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ẹ̀dá wa” tún tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún ìkòkò tí amọ̀kòkò mọ.—Aísáyà 29:16.

^ ìpínrọ̀ 10 Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé àwọ̀ rírẹ̀dòdò “jẹ́ àwọ̀ tí kì í ṣí tàbí kó bó. Ìrì tàbí òjò tàbí fífọ̀ tàbí lílò pàápàá kò lè mú un kúrò.”